Wahala de o, wọn ni Dapọ Abiọdun naa ko ṣe agunbanirọ

Spread the love

Lasiko to jọ pe nnkan ṣẹṣẹ fẹẹ maa ri bo ṣe yẹ ko ri, ti ko si alatako fun un mọ ninu ẹgbẹ APC to ti fẹẹ dije dupo gomina ipinlẹ Ogun, ni wahala rugbo de fun Ọmọọba Dapọ Abiọdun.

Ẹsun ai ṣe agunbanirọ lasiko to yẹ ko ṣe e ni wọn fi kan an, wọn ni aiṣododo wa nidii iwe-ẹri girama lasan to fẹẹ  fi dupo gomina, wọn lo kawe jade fasiti daadaa.

 

Ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Adeṣina Baruwa lo pe ẹjọ tako Dapọ Abiọdun nile-ẹjọ giga kan l’Abuja, nibi to ti sọ fun wọn pe niṣe lo yẹ ki ile-ẹjọ fofin de ondije dupo naa lati ma ṣe dije dupo gomina Ogun mọ.

 

Ki wọn si tun fi ọwọ ofin mu un fun bo ṣe loun ko ni iwe-ẹri yunifasiti, to jẹ iwe-ẹri girama lasan lo mu kalẹ fun ajọ INEC lati dupo gomina, nigba to jẹ o lọ si yunifasiti nilẹ yii, o tun lọ loke okun.

 

Ohun to mu ọrọ yii jade gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ ni pe nigba ti ondije dupo yii fẹẹ dupo ile igbimọ aṣofin lọdun 2015, ninu ẹgbẹ oṣelu APC kan naa, wọn lo ko iwe-ẹri yunifasiti rẹ kalẹ nigba yẹn, eyi to ni Yunifasiti Ọbafemi Awolọwọ, to wa ni Ile-Ifẹ loun lọ.

 

Iwe-ẹri naa fidi ẹ mulẹ pe o kẹkọọ gboye ninu imọ iṣiro owo, o si ṣetan lọdun 1986. Iwe-ẹri keji ti wọn ni ọga elepo naa tun mu silẹ nigba yẹn ni ti Yunifasiti Kennesaw to wa ni Atlanata, Georgia, l’Amẹrika, nibi to ni oun ti pari ẹkọ lọdun 1989.

 

Gbogbo awọn sabukeeti yii lo fidi ẹ mulẹ pe ondije dupo lati Ipẹru-Rẹmọ yii kawe ni yunifasiti, ko si ti i dagba kọja kikopa ninu isinru ilu to jẹ dandan lorilẹ-ede yii fun ẹni ti ko ba ti i pe ọgbọn ọdun.

 

Lọdun 1986 to kẹkọọ gboye akọkọ yii, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ṣi ni Ọmọọba Dapọ Abiọdun, nitori ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun1960, ni wọn bi i.

 

Ṣugbọn nitori ai sinru ilu naa, ti ko si ni iwe-ẹri rẹ, ni ko ṣe lo iwe-ẹri fasiti rẹ lati dupo gomina, wọn ni iyẹn lo ṣe dọgbọn yẹ abala agunbanirọ to yẹ ko fi iwe-ẹri tiẹ naa silẹ sẹgbẹẹ

 

Adeṣina to pe Abiọdun lẹjọ yii sọ pe gedegbe lo foju han pe ofin meji ni baba olowo to fẹẹ ṣe gomina yii tẹ loju mọlẹ. Akọkọ ni ti ofin idibo ilẹ wa, ati ti ajọ agunbanirọ ti wọn n pe ni NYSC. O ni bo ti purọ fun INEC naa lo ṣe ai sinru ilu lasiko ti ọjọ ori ṣi wa fun un lati ṣẹ bẹẹ.

Ẹ o ranti pe ọjọ Iṣẹgun to kọja yii ni Abiọdun fọwọ sọya pe Gomina Ibikunle Amosun yoo ṣatilẹyin foun gbẹyin ni, nigba to jẹ Akinlade ti wọn jọ n fa ipo gomina Ogun mọra wọn lọwọ ti kọja sinu ẹgbẹ Onipaki (APM) ni tiẹ.

Ṣugbọn nigba ti yoo fi di alẹ Satide ọsẹ kan naa, awọn ẹka iroyin ti n gbe e kiri pe Dapọ Abiọdun lẹjọ i jẹ lori ai ṣe agunbanirọ ti wọn ni o ṣee ṣe ki ipo to n wo lọọọkan naa ma ja mọ ọn lọwọ mọ.

Lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, ti a n ṣakojọ iroyin yii, akọroyin wa pe ondije dupo ti wọn fẹsun kan yii lori aago, ipe naa ko wọle.

A fi atẹjiṣẹ ransẹ si Ọmọọba Dapọ Abiọdun lati ṣalaye lori ẹsun nla naa, ṣugbọn a ko ri esi rẹ titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii.

Ohun ti ofin ilẹ wa sọ lori ẹni to to agunbanirọ i ṣe, ti ko ṣe e ni pe iru ẹni bẹẹ ko ni i riṣẹ kan ṣe lawọn ileeṣẹ nilẹ yii. Ẹni to ba si purọ pe oun sinru ilu nigba ti ko ṣe bẹẹ yoo fi ẹwọn jura.

Bakan naa lofin sọ pe ẹni to ba ṣetan nile iwe giga ko too pe ọgbọn ọdun, to waa kọ ti ko sinru ilu, ti lufin to le gbe e dẹwọn, koda, bi tọhun ko tiẹ ṣe ayederu iwe-ẹri agunbanirọ, dandan ni ko jiya ẹṣẹ rẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ẹsun ai ni iwe-ẹri agunbanirọ to jẹ ojulowo lo fi minisita fun eto iṣuna nilẹ yii tẹlẹ, Kẹmi Adeọsun, logbologbo, ti obinrin naa fi kọwe fipo rẹ silẹ. Kinni ọhun si foju Adebayọ Shittu, Minista fun eto ibara ẹni sọrọ naa ri mabo, nitori oun naa ko sinru ilu nigba ti aaye rẹ wa fun un.

Ohun ti yoo ṣẹlẹ lori ti Ọmọba Dapọ Abiọdun yii naa ko ti i yeeyan, ṣugbọn ALAROYE yoo maa fi bo ba ṣe n lọ to yin leti.

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.