Wahala awọn darandaran: Poli Ado bẹrẹ iṣẹ lori fẹnsi tuntun

Spread the love

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ileewe gbogboniṣẹ ijọba apapọ (Federal Polytechnic), to wa niluu Ado-Ekiti ti bẹrẹ iṣẹ lori kikọ ọgba yika oko nla ti wọn da silẹ nileewe naa lẹyin tawọn darandaran ba nnkan to to miliọnu mẹwaa Naira jẹ.

Ṣe lọdun to kọja niṣẹlẹ naa waye, nigba tawọn darandaran ko maaluu wọ oko nla to jẹ tileewe naa, ti wọn si ba ọpọlọpọ nnkan jẹ, eyi to ko ifasẹyin nla ba ẹka eto ọgbin ileewe ọhun.

i Ọmọwe Dayọ Hephzibar Ọladebẹyẹ to jẹ ọga-agba ileewe naa ṣalaye pe igbesẹ yii yoo ran ileewe naa lọwọ loriṣiiriṣii ọna, paapaa lori aabo fawọn dukia wọn.

Lori awọn nnkan to ti ṣe ki ayẹyẹ ikẹkọọ-jade kẹtadinlogun ileewe naa too waye lopin ọsẹ yii, ọga-agba naa ni oun ti san lara miliọnu ọọdunrun-le-aadọta (350m) Naira owo alajẹṣẹku ati owo igbega awọn oṣiṣẹ ti wọn n pe ni CONTEDISS 15.

Bakan naa lo ni oun ti ṣatunṣẹ sawọn dukia ileewe naa pẹlu oriṣiiriṣii eto lati ran awọn oṣiṣẹ ati akẹkọọ lọwọ, eyi to jẹ ki ẹka ijọba to n ri seto ẹkọ fọwọ sawọn ẹka ẹkọ kan.  

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii, nileewe naa yoo ṣayẹyẹ apapọ fawọn akẹkọọ-jade bii ẹgbẹrun mẹtadinlogun (17,000) ti wọn jade ni saa marun-un sẹyin.

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.