Wahala ṣẹlẹ l’Ado-Ekiti lori ile oriṣa tijọba fẹẹ wo

Spread the love

Titi di asiko yii ni ibẹru ati ibinu ṣi wa lọkan awọn eeyan ilu Ado-Ekiti pẹlu bi wahala ṣe ṣẹlẹ lopin ọsẹ to kọja lori ile oriṣa ti wọn ni ijọba fẹẹ wo. Igbesẹ naa tijọba sọ pe yoo mu idagbasoke ba ilu lo ti bẹrẹ lati bii oṣu meji, ninu eyi ti wọn ti wo ọpọlọpọ ile.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja lọrọ yiwọ nigba tawọn alagbaṣe ijọba ko katakata meji lọ si agbegbe Ọja Ọba, tawọn araalu si ya bo wọn pe wọn ko le wo ile Ogun ati ti oriṣa Ejeye Ọka Ere, eyi to jẹ kawọn yẹn dawọ iṣẹ duro.

Ọpẹlọpẹ awọn ẹṣọ alaabo ti wọn da si ọrọ naa, nnkan iba yiwọ gidi pẹlu bawọn eeyan ṣe n pariwo, ti wọn si n ṣepe, koda wọn ko gba ẹnikẹni laaye lati ya fọto iṣẹlẹ ọhun.

Gẹgẹ bi awọn kan ti wọn ba ALAROYE sọrọ, ṣugbọn ti wọn kọ lati darukọ wọn ṣe sọ, bii iboji mẹrin nijọba ti bajẹ, tawọn mọlẹbi wọn si sare hu eyii to ku lọọ sin sibomi-in. Wọn ni awọn ile oriṣa ati iboji tijọba n hu kiri ko nitumọ, wọn kan n da ibanujẹ sawọn eeyan lọkan ni.

Ninu alaye tijọba ṣe ni wọn ti ni bii irinwo biliọnu lawọn ti san fun awọn ti idagbasoke ilu mu kawọn wo ile wọn, ati pe gbogbo ibi to ba yẹ kawọn wo lawọn yoo wo. Kọmiṣanna fọrọ ilẹ ati idagbasoke ilu, Ọgbẹni Tayelolu Otitọju, to sọrọ lori bi nnkan ṣe n lọ sọ pe ki i ṣe Ado-Ekiti nikan ni ile wiwo ti n waye, Ikẹrẹ, Ẹfọn Alaaye, Omuo, Isẹ, Emure, Ijero atawọn ilu mi-in naa fara gba a.

O sọ ọ di mimọ pe bii ọọdunrun ile lawọn ti wo, eto ti yoo mu irọrun ba araalu si ni gbogbo rẹ da le lori, ṣugbọn ijọba ko ni i sanwo kankan fun awọn ti wọn kọle sibi ti ko bofin mu.

(55)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.