Umar Sadiq n lọ si AC Perugia

Spread the love

Ọmọ ilẹ wa to n gba bọọlu jẹun ni AS Roma ilẹ Italy, Umar Sadiq, yoo kọja si AC Perugia ilẹ naa loṣu to n bọ. Ọmọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogun naa lanfaani yii ṣi silẹ fun lẹyin to pada lati Glasgow Rangers ilẹ Scotland ti Roma ya fun igba diẹ.

Adehun ọdun kan ni Roma ati Perugia ni lori Umar, ọsẹ to kọja ni wọn si jọ jokoo sọrọ lori igbesẹ to kan.

Nnkan ko fi bẹẹ rọrun fun ọmọkunrin yii nilẹ Scotland to lọ, anfaani bọọlu gbigba loorekoore ko si fi bẹẹ yọ fun un. Eyi lo jẹ ki Steven Gerrard to jẹ kooṣi ibẹ gba a laaye lati pada si Roma, bo tilẹ jẹ pe o ku bii ọsẹ mẹta ko pari iṣẹ to lọọ ṣe ni.

Ireti wa pe oni, ọjọ Iṣẹgun, ni Umar yoo ṣayẹwo ilera ni Perugia, eyi si ni yoo jẹ igbesẹ akọkọ lara awọn ayẹwo ti yoo ṣe ko too kọja sibẹ ni bii ọsẹ mẹta si asiko yii.

Abuja FC ilẹ Naijiria ni Umar ti bẹrẹ bọọlu gbigba ko too lọ si ilẹ Italy ati Netherlands, awọn kilọọbu to si ti ṣe bẹbẹ ko din ni mẹjọ.

Ọdun 2016 lo kọkọ gba bọọlu fun Naijiria nibi idije Summer Olympics. Oun lo gba bọọlu akọkọ wọle nibi ifẹsẹwọnsẹ akọkọ idije naa, bẹẹ lo gba ayo kan wọle ni eyi to tẹle e, o si tun gba meji sawọn ni ifẹsẹwọnsẹ to jẹ ki Naijiria gba ipo ikẹta lọdun naa.

 

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.