Tunde to gun ọrẹ rẹ pa nitori ẹgbẹrun meji Naira dero ẹwọn

Spread the love

Tunde Kareem tawọn eeyan tun mọ si ‘Star Boy’, to n ṣiṣẹ telọ lagbegbe Alore, niluu Ilọrin, lo ti wa lahaamọ ọgba ẹwọn bayii, nitori ẹsun ti wọn fi kan an pe o gun ọrẹ rẹ kan, Sulu Isaika, pa nitori ẹgbẹrun meji Naira.

Iwe tileeṣẹ ọlọpaa fi wọ ọkunrin naa lọ sile-ẹjọ fi han pe ẹgbọn oloogbe naa ti orukọ rẹ n jẹ Isiaka Bashiru to n gbe ni Alimi Alore lo fi iṣẹlẹ naa to agọ ọlọpaa leti lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2019.

Baṣhiru loun gba ipe lọjọ naa pe Star Boy ti gun aburo oun pa. Loju ẹsẹ toun sa de ibi tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ loun ba oku Sulu ninu agbara ẹjẹ.

Iwadii awọn ọlọpaa fi han pe nibi ti Kareem ti n sun ni iyana Oko Olowo, nita gbangba, ni wọn ti ji ẹgbẹrun meji Naira rẹ.

Oloogbe naa ni wọn ni ọkunrin ọhun furasi pe o ji oun lowo to dawati naa.

Nibi ti wọn lo ti koju rẹ lati gba owo naa pada ni wahala ti bẹ silẹ laarin awọn mejeeji.

Kareem ko tilẹ fi akoko ṣofo to fi lọọ fa ọbẹ yọ, aya oloogbe naa lo mu un lọ taara, to si gun un.

Nigba tọwọ tẹ olujẹjọ naa, o jẹwọ fawọn ọlọpaa pe loootọ loun ṣe si ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan oun.

Ọlọpaa to ṣoju ijọba, Sgt. Innocent Ọnọọla, tako beeli olujẹjọ naa, o ni ẹsun ti wọn fi kan an ki i ṣe eyi ti wọn le gba oniduuro rẹ rara. O rọ ile-ẹjọ lati fi sahaamọ ọgba ẹwọn.

Adajọ Hauwa Buhari paṣẹ ki wọn lọọ fi olujẹjọ naa pamọ si ẹwọn titi di ọjọ kaarun-un, oṣu keji, ọdun 2019.

 

 

 

(16)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.