Tunde loun yoo fẹ Funmilayọ, lo ba dọgbọn gba mọto lọwọ ẹ l’Abeokuta

Spread the love

Adehun fifẹ ara ẹni to wa laarin ọkunrin kan, Tunde Matthew, ẹni ọdun mẹtadinlaadọta, ati ọrẹbinrin ẹ, Funmilayọ Ọdẹsanya, ti yipada bayii, o ti di ẹjọ si Tunde lọrun, nitori to dọgbọn gba mọto atowo nla lọwọ ọrẹbinrin rẹ yii, tiyẹn si fọlọpaa mu un,to fi waa yọri sile-ẹjọ.
Kootu majisreeti to wa n’Iṣabọ, l’Abẹokuta, ni wọn ti gbọ ẹjọ yii lọsẹ to kọja, nibi ti Supol Morakinyọ Adejuwọn ti ṣalaye pe mọto ayọkẹlẹ Nissan Tino kan ti owo rẹ jẹ miliọnu kan ati ẹgbẹrun lona igba Naira (1.2m), eyi ti i ṣe ti Funmilayọ, ni olujẹjọ yii fi ọgbọn buruku gba lọwọ ẹ, to si n lo o lai jẹ ki obinrin naa ni anfaani si i mọ.
Agbefọba yii ṣalaye pe ọrọ ifẹ to wa laarin awọn mejeeji ni ko jẹ ki Funmilayọ tete fura pe gbaju-ẹ ni Tunde n ṣe foun, ki i ṣe pe o fẹẹ fẹyawo rara.
Lati 2016 ti ajọṣepọ naa ti bẹrẹ, o ni Tunde ko mu Funmilayọ dele rẹ, otẹẹli lo maa n mu un lọ ti wọn yoo jọ wa fun bii ọjọ meji, bẹẹ awijare olujẹjọ yii ni pe ọga ọlọpaa loun, igbakugba si ni wọn le gbe oun kuro nibi kan lọ sibomi-in, iyẹn loun ko ṣe gbale l’Abẹokuta, to jẹ oun kan maa n paara ilu Eko to jẹ olu ileeṣe oun ni, toun si maa n sun lotẹẹli nipinlẹ Ogun.
Funmilayọ ko fura rara pe opurọ paraku lẹni toun n ba jade naa, o ṣebi oun ti rọkọ ni. Eyi naa lo si fa a to fi jẹ pe Tunde lo n gun mọto obinrin yii ju, ti yoo gbe e lọ siluu Eko fun ọpọlọpọ ọjọ ko too gbe e wa s’Abeokuta pada nigba to ba fẹẹ ri ọrẹbinrin rẹ yii.
Ṣugbọn nigba to di laarin kan nibẹrẹ ọdun yii, olujẹjọ gbe ọkọ naa lọ kanrin, ko wa siluu Ẹgba, bẹẹ ni ko beere ololufẹ rẹ to ni moto naa, nigba naa lo si ṣẹṣẹ ye obinrin yii pe oun ti ko sọwọ gbaju-ẹ.
Yatọ si mọto, agbẹnusọ ijọba fi ye kootu pe owo to din diẹ ni idaji miliọnu, iyen ẹgbẹrun lọna irinwo le lọgọta Naira (460, 000), ni olujẹjọ tun gba lọwọ obinrin to n wa ọkọ ọhun, pẹlu ileri pe oun yoo da a pada fun un. Ṣugbọn Matthew ko da owo pada, bẹẹ lo tun gbe moto lọ lai wẹyin rara.
Lẹyin ọpọlọpọ wiwa, ọwọ ba afurasi to n pe ara ẹ ni ọlọpaa yii, awọn agbofinro ti ọrẹbibnrin rẹ fẹjọ sun si mu un, wọn taari rẹ wa si kootu.
Nigba to n ka awọn ẹsun ti ijọba fi kan Matthew si i leti, agbefọba sọ pe mẹta ni, eyi ti i ṣe fifi ọna ẹtan gba mọto onimọto, pipe ara ẹni loun ti a ko jẹ, ati fifi ọgbọn ẹtan gbowo lọwọ ẹni keji ẹni.
Awọn ẹsun yii lodi si abala irinwo ati mọkandinlogun (419) ati irinwo din mẹẹwaa, (390), ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ogun ti wọn tun ṣe ni 2006, ijiya si wa fun wọn.
Gbogbo ẹsun yii ni olujẹjọ ni oun jẹbi ẹ. Adajọ S.Ṣolẹyẹ paṣẹ pe ki wọn da a pada satimọle ti wọn ti gbe e wa, o si sun igbẹjọ siwaju.

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.