Tubọsun ati Titi to maa n fipa ba awọn akẹkọọ poli lo pọ l’Abẹokuta ni aisi itọju obi lo fa a

Spread the love

Ọkan awọn akẹkọọ ileewe Gateway City ICT Polytechnic, to wa ni Iṣara, nipinlẹ Ogun, ṣẹṣẹ balẹ, pẹlu bi ọwọ ṣe tẹ awọn meji kan ti wọn gbadun ki wọn maa fipa ba wọn lo pọ, ti wọn yoo si tun ja wọn lole awọn dukia wọn.

   Ogunlẹyẹ Ọlatunbọsun ati Fadimu Titilọpẹ, ni aṣiri wọn tu, ti wọn si ti n ka boroboro fun awọn ọlọpaa lori ohun ti wọn mọ nipa awọn iṣẹlẹ idigunjale to n ṣẹlẹ si awọn akẹkọọ ileewe naa nigba gbogbo.

Nigba to n ṣafihan awọn afurasi ọdaran mejeeji lọsẹ to kọja, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ni ọjọ ti pẹ ti awọn afurasi yii ti maa n ṣiṣẹ laabi wọn, ṣugbọn ọwọ palaba wọn ṣegi lẹyin ti wọn ṣiṣẹ buruku naa tan lọjọ kejidinlogun, oṣu yii.

   Oyeyẹmi ni ṣe ni wọn gba ọpọlọpọ foonu, ẹrọ agbeletan, goolu atawọn nnkan mi-in lọwọ awọn akẹkọọ yii. Ipe pajawiri ti awọn ọlọpaa si gba lo jẹ ki wọn tọpasẹ awọn adigunjale naa lọ tọwọ fi tẹ Tubọsun ati Titilọpẹ.

Nigba ti wọn n ba akọroyin wa sọrọ, Fadimu Titi ni “ẹni ọdun mọkanlelogun ni mi. Mi o mọ nipa pe wọn fipa ba awọn kan lo pọ, irọ ni awọn akẹkọọ naa n pa mọ wa. Loootọ, a gbọ pe awọn kan lọọ ja awọn akẹkọọ yii lole ki a too debẹ, ti wọn si fipa ba wọn lo pọ, ṣugbọn ki i ṣe awa rara, ole nikan la ja wọn. O ti to ọsẹ meji ti awọn ọlọpaa ti mu wa, mi o ro pe wọn sọ pe mo fipa ba awọn kan lo pọ, afi laaarọ yii ti awọn ọmọbinrin kan ṣadeede de, ti wọn si n nawọ si wa pe a fipa ba awọn lo pọ.

“Ọkada ni mo pinnu lati lọọ ji ni agbegbe Iṣara-Rẹmọ. Ohun to dẹ sun mi de idi iwa ole jija ni pe awọn obi mi lo fa a. Iyawo mẹta ni baba mi fẹ, iya to bi mi si ni iyawo ti wọn fẹ kẹyin. Lati kekere ni iya mi si ti kọ baba mi silẹ. Nigba ti mo dagba, baba mi le mi danu. Ati baba ati iya mi ko ri temi ro lati ọdun meje sẹyin. Awọn obi mi ki i bikita fun jijẹ ati mimu mi, nnkan to sun mi de idi ole jija niyẹn.

Ninu ọrọ Tubọsun, o ni, “mi o mọ nnkan kan nipa ọrọ ifipabanilopọ. Ọkada ni mo n ji. Ẹ wo oju mi to wu yii, lilu ni awọn ọlọpaa fi ba temi jẹ debẹ. Ọkada la maa n ji ni tawa. Igba akọkọ ti awọn ọlọpaa maa mu mi niyi.”

Ni idahun si ibeere akọroyin wa nipa bi tatuu ṣe kun ara rẹ, Tubọsun ni, “bọbọ kan bayii lo ba mi ya awọn tatuu ti ẹ n wo yii si ara mi, ṣugbọn mi o ki i fipa ba eeyan lo pọ rara, bẹẹ mi o paayan ri laye mi.”

Abimbọla Oyeyẹmi ti ni awọn akẹkọọ ti wọn lọọ ja lole ti tọka si wọn pe awọn ni wọn ṣiṣẹ ibi naa, bẹẹ wọn si tun ja awọn lole ara pẹlu.

Agbẹnusọ ọlọpaa naa ni awọn afurasi mejeeji yii ni alaye lati ṣe to pọ fun ijọba, nitori laipẹ lawọn yoo wọ wọn lọ si kootu lati le ṣalaye tẹnu wọn fun ile-ẹjọ.

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.