Tonile-talejo ni yoo gbadun ijọba mi bi mo ba di gomina Eko-Sanwoolu

Spread the love

Oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Jide Sanwoolu, ti sọ pe tẹru-tọmọ, tonile-talejo, lo maa gbadun ijọba oun bi awọn eeyan ba le fibo gbe oun wọle gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Eko.

O sọrọ yii ni Sannde, ọjọ Aiku, ọsẹ yii, lasiko to n fi erongba rẹ lati dupo gomina lọdun to n bọ to awọn ọmọ ẹgbẹ APC atawọn alatilẹyin rẹ leti ni City Hall, to wa ni Lagos Island, niluu Eko.

Ọkunrin to ti figba kan jẹ kọmisanna nipinlẹ naa lasiko iṣejọba Oloye Bọla Tinubu sọ pe ni kete toun ba gbajọba, ohun akọkọ ti yoo jẹ oun logun ni bi oun yoo ṣe da ogo ipinlẹ Eko to da bii pe o ti fẹẹ maa wọmi pada. Bẹẹ ni ma a mu ọrọ awọn araalu ni pataki ninu eto iṣejọba.

O gboriyin fun awọn aṣaaju to ti ṣejọba nipinlẹ Eko bii Hubert Macaulay, Akitoye Ajasa ati Adeniyi Jones, pẹlu alaye pe ẹnikẹni ti yoo ba ṣejọba ipinlẹ Eko gbọdọ ṣe awokọṣe awọn eeyan yii.

Sanwoolu ni, ‘Ni kete ti ẹ ba fi ibo yin gbe mi wọle, ohun akọkọ ti yoo jẹ mi logun ni lati mu ogo ipinlẹ yii pada bọ sipo, ki n si ri i pe gbogbo agbegbe ati ayika ni ipinlẹ Eko di mimọ tonitoni lai si idọti kankan gẹgẹ bi ẹyin eeyan ipinlẹ yii ṣe n pongbẹ fun un. Bakan naa ni ma a ri i pe opin de ba gbogbo akọlukọgba kaakiri ilu, eyi to mu aye nira fun gbogbo awọn olugbe ipinlẹ yii.

‘Mo pe gbogbo ẹyin eeyan mi sibi yii lonii lati ṣeleri fun yin pe ohun ti yoo jẹ afojusun mi ni lati wa rere olugbe ipinlẹ Eko kọọkan, ki n si ṣe amulo alakalẹ ẹgbẹ wa lati mu ayipada rere ba ipinlẹ yii.

‘Mo mọ pe ipinlẹ Eko tuntun ta a ni latigba ti ẹgbẹ wa ti n ṣe ijọba nipinlẹ yii ko ṣẹyin aṣaaju rere to ni iran fun ọjọ iwaju ti a ni. O si pọn dandan fun mi ki n ki Aṣiwaju Bọla Tinubu fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati mu ki ipinlẹ Eko di ti igbalode.

‘Mo ṣeleri pe ọmọ ẹgbẹ tọkantọkan ni ma a jẹ ninu gbogbo eto iṣejọba mi, bẹẹ ni ma a si ṣe ijọba akoyawọ ti ko ni i yọ ọmọ ẹgbẹ kankan sẹyin gẹgẹ bi ofin ati ilana ẹgbẹ wa ṣe la a kalẹ. Mo ṣeleri lati jẹ oloootọ si gbogbo eeyan ipinlẹ Eko ati awọn aṣaaju ẹgbẹ wa.’

Bakan naa lo gboriyin fun gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko to tun jẹ minista fun ọrọ iṣẹ, ile gbigbe ati agbara, Babatunde Raji Fashọla. O ni gbogbo awọn ti wọn ti jẹ aṣaaju ti wọn ti gbe nnkan ṣe fun idagbasoke ipinlẹ Eko jẹ iwuri fun oun, bẹẹ ni wọn si fun oun ni igboya. Latari eyi lo fi sọ pe oun ti pinnu lọkan oun bayii gẹgẹ bii ọrọ ọmọ ilẹ Amẹrika nni, John Kennedy, pe oun ko ni i duro de ohun ti ilu oun yoo ṣe foun, bi ko ṣe ohun ti oun naa le ṣe lati ran ilu oun lọwọ.

‘Mo n pe gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu wa nija pe iṣẹ pọ fun wa lati ṣe lati ri i pe a ni ipinlẹ Eko ti a ti n pongbẹ fun. Nidii eyi, mo fi ara mi silẹ bii ẹni to ni gbogbo ohun to pe fun lati mu ki ipinlẹ Eko tẹsiwaju’

Awọn eeyan jankan jankan ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko lo peju pesẹ sibi ti ikede Sanwoolu ti waye yii. Lara wọn ni Sẹnetọ Gbenga Aṣafa to n ṣoju agbegbe Iwọ-Oorun ipinlẹ Eko nile igbimọ aṣofin agba l’Abuja, ọkan ninu awọn agba ẹgbẹ naa, Oloye James Ọdunbaku. Awọn mi-in tun ni: Demọla Seriki, Oloye Kaoli Olusanya, Oloye Ajọsẹ, Họnọrebu James Faleke. Bẹẹ ni gbogbo awọn alaga ijọba ibilẹ mẹtadinlọgọta to wa nipinlẹ Eko, awọn ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin agba ati ti ipinlẹ, atawọn agbaagba oloṣelu mi-in.

Pẹlu ikede yii, o ti han gbangba bayii pe ko ni i si anfaani pe Gomina Ambọde to wa lori ipo bayii yoo kan gba tikẹẹti ẹgbẹ naa lọfẹẹ lofo, o di dandan ko dije pẹlu ọkunrin yii ati Dokita Jide Hamzat ti oun naa ti gba fọọmu lati dupo gomina yii kan naa.

(42)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.