Tọla ati ọrẹ rẹ faṣọ ọlọpaa ya, ni wọn ba foju bale-ẹjọ

Spread the love

Aṣe loootọ nibinu ko mọ pe olowo oun ko lẹsẹ nilẹ, gbangba lo han loju awọn ọkunrin meji ti wọn ko lọ sile-ẹjọ Majisreeti ilu Oṣogbo l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja lori ẹsun pe wọn ba ọlọpaa meji ja, ti wọn si fa aṣọ ya mọ awọn oniṣẹ ọba naa lọrun, pe wọn kabaamọ iwa ti wọn hu.

Yatọ si eleyii, a gbọ pe awọn olujẹjọ naa, Ajayi Oyetọla ẹni ọdun mẹtalelogoji ati Adewunmi Tọla, toun jẹ ẹni ọdun mejidinlogoji, tun kọju ija si afurasi kan toun wa lakolo awọn ọlọpaa ni tiẹ.

Inspẹkitọ Ọladoye Joshua to n ṣoju ileeṣẹ ọlọpaa lori ọrọ naa ṣalaye pe ni nnkan bii aago mọkanla aabọ aarọ ọjọ kẹwaa, oṣu kẹwa, ọdun yii, lawọn olujẹjọ naa gungi rekọja ewe, koda, layiika kootu niluu Osogbo ni wọn ti huwa naa.

Ẹsun marun-un ọtọọtọ ni wọn ka si awọn olujẹjọ naa lẹsẹ, iyẹn igbimọ-pọ huwa buburu, didoju ija kọ eeyan, biba nnkan jẹ, igbiyanju lati paayan ati dida omi alaafia agbegbe ru.

Ọladoye ṣalaye pe ṣe ni Tọla ati ọrẹ rẹ rọjo igbaju fun Ọlakunle Mohammadu ti adajọ majisreeti kan paṣẹ pe kawọn ọlọpaa lọọ fi pamọ sakolo wọn, bi awọn ọlopaa meji ti wọn wa lẹnu iṣẹ lasiko yẹn ṣe sọ pe kawọn da si ọrọ yii bayii, tibinu tibinu lawọn olujẹjọ yii fi doju ija kọ wọn.

Bi wọn ṣe n gba SP Adeniyi Fẹmi loju ni wọn n gba DSP Abioye Sanjọ nimu, koda, aṣọ fa ya mọ awọn agbofinro yii lara kawọn ojugba wọn too gbe wọn nija, ti ọwọ si tẹ awọn mejeeji.

O ni ṣe lawọn olujẹjọ fẹẹ pa afurasi to wa lakolo ọlọpaa, bẹẹ ni wọn ko si fẹ ki awọn ọlọpaa raaye fidi otitọ mulẹ pẹlu bi wọn ṣe kọlu wọn lẹnu iṣẹ.

Nitori idi eyi, Ọladoye ni awọn olujẹjọ naa ti huwa to lodi, to si nijiya nla labẹ ipin kẹrindinlaaadọrun-un abala kẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran ti ọdun 2003 tipinlẹ Ọṣun.

Nigba ti wọn ka ẹsun maraarun ti wọn fi kan awọn olujẹjọ yii, wọn sọ pe awọn ko jẹbi. Agbẹjọro wọn, Ọgbẹni Kazeem Badmus, rọ ile-ẹjọ lati ṣiju aanu wo awọn olujẹjọ, ki kootu si fi aaye beeli silẹ fun wọn lọna irọrun.

Adajọ A. O. Ajanaku gba beeli ọkọọkan awọn olujẹjọ pẹlu ẹgbẹrun lọna ọtalelugba Naira o din mẹwa (250, 000), ati oniduuro kọọkan ni iye kan naa.

Ajanaku ni oniduuro naa gbọdọ maa gbe lagbegbe kootu, ko si ni iwe ẹri idaniloju pe o n san owo-ori funjọba deede, bẹẹ lo gbọdọ jẹ oṣiṣẹ ijọba.

Lẹyin naa lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kọkandinlogun, oṣu kejila, ọdun yii.

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.