Tọkọ tiyawo to n ta ẹya ara eeyan ko sọwọ ọlọpaa ni Kwara *Agbari mọkanla ni wọn ka mọ wọn lọwọ

Spread the love

Awọn tọkọ-tiyawo kan, Azeez Yakub ati Azeez Salima, lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara tẹ l’ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, pẹlu ẹya ara eeyan gbigbẹ ati tutu.
Ọwọ tẹ awọn eeyan yii pẹlu awọn afurasi mẹta mi-in; Isah Wasiu, Abubakar Isiaka ati Soliu Yakub lojule ogun, lagbegbe Ile-Ọpa, Aromaradu, Adewọle, niluu Ilọrin.
Agbari mọkanla, awọn ẹya ara ati irun eeyan ni wọn ba ninu ile yii ti awọn afurasi yii di lekiri-lekiri.
Agbari mẹjọ lo jẹ gbigbẹ, nigba ti tutu ti wọn ṣẹṣẹ ge jẹ mẹta. Bakan naa ni awọn eegun ẹya ara eeyan mi-in wa nibẹ.
Lasiko to n ṣafihan wọn, Kọmiṣana ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Bọlaji Fafowora, sọ pe awọn eeyan lo ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo pe awọn afurasi kan wa lagbegbe Adewọle to n ṣe alapata eeyan, ti wọn si n ta a fawọn to fẹẹ fi ṣoogun.
O ni awọn ọlọpaa ya bo ile naa, nibẹ lọwọ si ti tẹ afurasi akọkọ, Azeez Yakub, atawọn mẹrin yooku.
Akiyesi wa fihan pe iyawo ọkunrin naa wa ninu oyun. Kọmiṣana ọlọpaa naa sọ pe ileeṣẹ awọn ṣi n tẹsiwaju lori iwadii awọn, o ni lẹyin eyi lawọn yoo wọ awọn afurasi naa lọ si kootu.
Bakan naa lọwọ tun tẹ afurasi kan, Ṣẹgun Bọlatito Akande, to n gbe lagbegbe Ṣapati, niluu Ilọrin, wọn ni o ji mọto Toyota Serena kan to jẹ ti ileeṣẹ KASMAG Transport Ltd, gbe.
Lasiko to n gbiyanju lati ta ọkọ ọhun ti nọmba rẹ jẹ KSF 626 XR, fun ẹnikan lọwọ tẹ ẹ. Onibaara rẹ yii ti kọkọ san owo diẹ fun un, to si ti ko risiiti ọkọ naa to ni oun loun ni in fun un, iyẹn lo ṣakiyesi pe orukọ ileeṣẹ KASMAG to n ṣowo irinna ọkọ niluu Ilọrin lo wa nibẹ. Kiakia lo si fi ọrọ naa to ọlọpaa leti.
Iwadii awọn agbofinro fihan pe afurasi naa ji mọto ọhun gbe ni.

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.