Tọkọ-tiyawo padanu ẹmi wọn nigba ti won n bo lati ibi idupẹ igbeyawo n’Ileṣa

Spread the love

Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to lọ lọhun-un, ni awọn lọkọ-laya kan ti a ko ti i mọ orukọ wọn lasiko ti a fi n kọ iroyin yii pade iku ojiji lasiko ti wọn n ti ibi idupẹ igbeyawo ti wọn lọọ ṣe ni ṣọọṣi bọ. Ilu Ileṣa ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, ori ọkada si ni awọn mejeeji wa, ti ọkọ ayọkẹlẹ kan fi kọlu wọn, nibẹ ni awọn mejeeji si gba jade laye.
Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju ẹ to ṣalaye fun akọroyin wa sọ pe o ku ọsẹ kan si asiko igbeyawo naa ni pasitọ kan ti ṣekilọ fun wọn pe wọn ko gbọdọ ṣe idupẹ igbeyawo naa, nitori oun riran si wọn pe awọn mejeeji maa ku ti wọn ba ṣe bẹẹ.
Ikilọ pasitọ naa ni awọn mejeeji ko ka si, lasiko ti wọn si n ti ibi idupẹ naa bọ ni ọkọ ayọkẹlẹ kan kọlu wọn lori ọkada ni opopona to lọ si ileewe olukọni, College of Education, to wa niluu Ileṣa, lẹsẹkẹsẹ ni wọn si ku.
Lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, oku awọn mejeeji wa ni mọṣuari Wesley, to wa niluu Ileṣa.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, DSP Fọlaṣade Odoro, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, pẹlu alaye pe awọn ti bẹrẹ iwadii lati mu afurasi to kọlu wọn naa.

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.