Tobi Oluwayẹmi darapọ mọ Celtic

Spread the love
Tobi Oluwayemi

Ọmọ ilẹ wa to n ṣe bẹbẹ nilẹ England, Tobi Oluwayẹmi, ti darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Celtic Glasgow, lẹyin to tọwọ bọ iwe adehun ọlọdun mẹta pẹlu wọn lopin ọsẹ to kọja.

Ẹni ọdun mẹrindinlogun to kẹkọọ jade ni Tottenham Academy ọhun lo jẹ amule ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin laarin awọn ẹgbẹ ẹ, eyi to jẹ ki Celtic tete le e ba kawọn mi-in too ra a.

Nigba to n sọrọ lori eto tuntun naa, Oluwayẹmi ni inu oun dun gidi nitori afojusun oun ni lati ṣe iru oriire bẹẹ.

Nnkan yoo tun rọrun fun ọdọmọde naa pẹlu bo ṣe jẹ pe kilọọbu to ṣẹṣẹ balẹ si yii ni Karamoko Dembele ti wọn ti jọ n ṣe bẹbẹ fun ilẹ England wa. Awọn mejeeji ti jọ sọrọ lori kilọọbu yii, eyi lo si ran ipinnu rẹ lọwọ.

Ilẹ England ni wọn bi Oluwayẹmi si, bẹẹ lo lanfaani lati gba bọọlu fun wọn tabi orilẹ-ede Naijira. Lọwọlọwọ bayii, ipele U16 ilẹ England lo n gba bọọlu fun.

Oun ati ẹgbọn rẹ, Joshua Oluwayẹmi, toun wa ni ipele U18 Kilọọbu Tottenham ni wọn jọ kẹkọọ nipa bọọlu ko too kuro nibẹ.

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.