Tobi jale ni ṣọọṣi, ladajọ ba ran an lẹwọn

Spread the love

Ẹni ọgbọn ọdun kan, Tobi Ọlafusi, ti balẹ sọgba ẹwọn bayii pẹlu  bi awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo ṣe wọ ọ lọ si kootu Majisreeti to wa niluu Ondo, nibi ti wọn ti fẹsun kan an pe o jale ni ṣọọṣi Gospel Faith Mission, to wa laduugbo Gani Fawẹhinmi, nipinlẹ Ondo.

Agbefọba to n rojọ tako o ni kootu, Gbenga Akinsulurẹ, ṣalaye pe laipẹ yii ni Tobi ati awọn yooku rẹ ti ileeṣẹ ọlọpaa ṣi n wa bayii lọọ ja ilẹkun ṣọọṣi naa, ti wọn si ji awọn ohun eelo orin, sipika,  faanu, ṣọkẹẹti atawọn nnkan mi-in, eyi ti iye owo rẹ din diẹ ni ẹgbẹrun lọna igba Naira (195,000). Akinsulurẹ ṣalaye pe awọn ẹsun yii tako awọn abala kan to de iwa ọdaran, eyi ti ipinlẹ Ondo n ṣamulo rẹ, ti wọn si gbe kalẹ lọdun 2006.

Agbẹjọro olujẹjọ, Amofin Ayọ Afọlayan, bẹbẹ fun beeli onibaara rẹ pẹlu ileri pe ko ni i sa lọ fun igbẹjọ.

Akinsulurẹ tako ọrọ agbẹjọro yii, o ni ki kootu fi Tobi ṣọwọ si ọgba ẹwọn titi asiko ti igbẹjọ yoo fi pari.

Lasiko to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Ọdẹnusi Fadeyi paṣẹ pe ki wọn ṣi maa mu Tobi lọ si ọgba ẹwọn na, o si sun igbẹjọ siwaju.

 

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.