Tirela tun pa ọlọkada ni Sango

Spread the love

Ọjọ Sannde ọsẹ yii ni ọlọkada kan tun riku ojiji he loju ọna Ilo Awẹla, Sango, nipinlẹ Ogun, nigba ti wọn ni tirela kan to n sare bọ kọlu u, to si ku loju-ẹsẹ.

Alaye ti Alukoro TRACE nipinlẹ Ogun, Babatunde Akinbiyi, ṣe nipa iṣẹlẹ naa ni pe ni nnkan bii aago kan oru ku iṣẹju kan niṣẹlẹ yii waye niitosi olobiripo Van Milk, Ilo Awẹla.

Awọn to ṣoju wọn lo fidi ẹ mulẹ pe bi tirela naa ṣe n sare buruku bọ ni ọlọkada ti nọmba rẹ jẹ ABG 973QB naa n sare to kọja sisọ.

Bi tirela ọhun ṣẹ gba ọlọkada yii lọkunrin naa ku lẹsẹkẹsẹ, bẹẹ ni awọn eeyan meji mi-in tun farapa. Alukoro TRACE fidi ẹ mulẹ pe ile igbokuu-si Ọsibitu Jẹnẹra Ifọ ni wọn gbe oku ọlọkada naa lọ, nigba ti awọn to farapa n gbatọju labala itọju ileewosan yii kan naa.

Ẹni to wa tirela ọhun ko duro rara gẹgẹ bi alaye ọga ẹṣọ oju popo yii, bo ṣe ri i pe ijamba ti ṣẹlẹ lo sa lọ.

(41)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.