Tirela tẹ ọlọkada atero to gbe sẹyin pa l’ Abẹokuta

Spread the love

Ọlọkada kan atero to gbe sẹyin ko mọ pe awọn ko ni i ṣe ọdun tuntun 2019. Bo ṣe ku ọjọ kan ṣoṣo ka mu ọdun yii, iyẹn lọjọ Sannde, ọgbọnjọ, oṣu kejila, ọdun 2018, ni tirela tẹ wọn pa l’Ọbantoko, niluu Abẹokuta.

Nnkan bii aago kan ọsan ni lọjọ Sannde naa, lagbegbe ileewe giga Nawair-ur-deen, loju ọna Ṣomọrin, Ọbantoko, l’Abẹokuta. Asiko naa gan-an ni ọlọkada kan to gbe ero sẹyin n ki ọlọkada mi-in ti wọn jọ fẹgbẹ kẹgbẹ.

Nibi ti kiki ọlọrọ gbọọrọ naa ti n lọ loju popo ti ki i da ọhun ni ọlọkada to kagbako yii ti fura pe tirela kan to jẹ Volvo ti kan oun lara tan. Nigba ti yoo si fi gbiyanju lati sare kuro loju ọna yii, niṣe lo tun padanu ijanu ẹ, bẹẹ tirela ti kan an lara tan, bo ṣe tẹ oun ati ero to gbe sẹyin pa loju-ẹsẹ niyẹn.

Bii omi lẹjẹ ọlọkada yii ati ti ero to gbe sẹyin n ṣan loju popo naa. Alukoro TRACE, Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi, jẹ ka mọ pe ABG 413 VR  ni nọmba ọkada Bajaj to kagbako lọdun ku diẹ yii, ti ẹnikẹni ko si ri kinni kan ṣe si i.

Mọṣuari Ọsibitu Jẹnẹra to wa n’Ijaye, ni wọn ko awọn oku meji yii lọ gẹgẹ bi alukoro TRACE ṣe wi.

O ni o ṣe ni laaanu pe niṣe ni awakọ tirela to tẹ wọn pa naa sa lọ patapata bi iku ojiji ṣe pa awọn eeyan meji naa latọwọ rẹ.

 

(24)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.