Ti ile-ẹjọ ba da ajọ INEC lẹbi lori idibo gomina Ọṣun, ma a kọwe fipo silẹ – Agbaje

Spread the love

Kọmisanna fun ajọ eleto idibo orilẹ-ede yii, INEC, to wa nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Oluṣẹgun Agbaje, ti ni ti ile-ẹjọ ti wọn gbe kalẹ lati gbọ ẹsun to ṣuyọ lẹyin idibo gomina to waye nipinlẹ Ọṣun (Election Petition Tribunal), ba le sọ pe ajọ naa ṣe magomago lasiko idibo ọhun, oun ṣetan lati kọwe fipo silẹ.

Agbaje sọrọ yii lasiko ti gomina ti wọn kede pe o jawe olubori, Alhaji Isiaka Adegboyega Oyetọla, ati igbakeji rẹ, Benedict Olugboyega Alabi, n gba iwe-ẹri ‘mo yege’ lọọfiisi ajọ INEC niluu Oṣogbo.

Agbaje ni ti ogun ẹni ba da ni loju, ṣe la maa n fi ọwọ rẹ gbari, o ni iṣẹ takuntakun ni ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọṣun ṣe ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo manigbagbe naa, ko si si ẹni ti ko ni imọlara eto naa laarin gbogbo awọn ọmọ ajọ eleto idibo.

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn gbiyanju gẹgẹ bii eniyan ẹlẹran ara lati ko akoyawọ ninu idibo naa, bo tilẹ jẹ pe ko ṣee ṣe lati tẹ gbogbo eeyan lọrun, paapaa, awọn oloṣelu to ba da bii ẹni pe ẹgbẹ wọn ko rọwọ mu ninu eto idibo to ba waye.

O ni ko si ọgbọn tawọn oloṣelu ki i da lasiko ibo, ṣugbọn ti ile-ẹjọ ba le sọ pe ajọ INEC lọwọ ninu ohunkohun ti wọn ba pe ni iwa ibajẹ ninu idibo gomina nipinlẹ Ọsun, oun yoo kọwe fipo silẹ.

Agbaje waa rọ Oyetọla lati ri bo ṣe jawe olubori rẹ gẹgẹ bii oore-ọfẹ nla ti Ọlọrun yọnda fun un lati fi mu aye dẹrun fun tolori tẹlẹmu nipinlẹ Ọṣun.

Ninu ọrọ idupẹ rẹ, Alhaji Gboyega Oyetọla, ti ẹgbẹ oṣelu APC dupẹ lọwọ Ọlọrun ati gbogbo awọn ti Ọlọrun lo fun aṣeyọri idibo naa. O ni ki i ṣe nnkan to rọrun rara, ṣugbọn Ọlọrun faaye gba a lati le jẹ ki oun mọ riri awọn eeyan si i ni.

Oyetọla ni oun ko ni i ja awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun kulẹ rara ninu igbẹkẹle ti wọn ni ninu oun, ati pe nigba ti oun ba pari ọdun mẹrin akọkọ, gbogbo wọn ni wọn maa kan saara si Ọlọrun to fun oun laaye lati di gomina.

O waa pe fun ifọwọsowọpọ gbogbo awọn ti wọn ba nifẹẹ idagbasoke ipinlẹ Ọṣun, ki awọn iṣẹ rere Gomina Arẹgbẹṣọla le maa tẹ siwaju.

Lara awọn ti wọn wa nibi eto naa ni alaga ẹgbẹ APC l’Ọṣun, Gboyega Famọọdun, Ọnọrebu Olubunmi Etteh, Aragbiji ti ilu Iragbiji, Ọba Ọlabomi, Ọnọrebu Adejare Bello, Ọnọrebu Salinsile ati bẹẹ bẹẹ lọ.

(29)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.