Tẹnanti fun iyawo lanlọọdu rẹ loyun ni Saki O loun lo kọkọ dẹnu ifẹ kọ oun

Spread the love

Bii ere ori itage lọrọ naa ṣi n ri loju awọn eeyan agbegbe Daru-Salam, loju ọna to lọ siluu Ọgbọọrọ, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ṣaki, ṣugbọn iṣẹlẹ naa ki i ṣe sinima, ohun to ṣẹlẹ gan-an ni, nitori ọkunrin kan, Julius Ọmọtọṣọ, ti fun iyawo lanlọọdu rẹ, Mulikat Ajọkẹ, loyun, koda, oyun oṣu mẹrin lo wa ninu obinrin naa bayii.

Gẹgẹ bii iwadii wa, iṣẹ tiṣa ni Ayanlọwọ n ṣe nileewe alakọọbẹrẹ kan niluu naa, eyi lo si mu un gba yara kan si agbegbe yii latọdun 2015. A ri i gbọ pe iyawo mẹta ni tiṣa naa ni.

***Lanlọọdu Daniel, Alaaji Adeọla, niwadii wa fi mulẹ pe ki i fi gbogbo igba gbele, nitori oniṣowo epo bẹntiroolu ni. Ọkan ninu awọn iyawo lanlọọdu naa to ṣofofo ọrọ naa fun wa sọ pe ko sẹni to kọkọ fura si iyawo kekere naa, ṣugbọn ọpọ igba lo maa n pẹẹ wọle lati ibi-iṣẹ, to si jẹ pe yoo yọ lọ si ọdọ tiṣa, ẹni to n ko ibasun fun un karakara.

Nipa bi aṣiiri ọrọ naa ṣe tu sita, o ni iyawo yii lo n pariwo inu rirun fun ọkọ awọn, ẹni to fun un lowo lati lọọ ṣayẹwo iru aisan to n ṣe e lọsibitu ti awọn n lo.

Nigba ti obinrin naa gbera, ọsibitu mi-in lo gba lọ, ṣugbọn pẹki-n-pẹki lo pade dokita mọlẹbi wọn nileewosan naa, nigba ti iyẹn pẹlu akẹgbẹ rẹ si ṣayẹwo fun un ni wọn ri i pe obinrin naa ti loyun oṣu mẹrin-in. Akọroyin wa ri i gbọ pe iyawo Tiamiyu ṣalaye pe ẹẹmẹta pere ni **Daniel ṣe ‘kinni’ foun, oun ko si mọ pe o le yọri si oyun.

(65)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.