Tabi kin ni Adajọ Agba ilẹ yii tun ṣe fun wọn bayii?

Spread the love

Adajọ Walter Onnoghen ni adajọ agba ilẹ wa, iyẹn ni pe oun ni olori awọn adajọ patapata. Amọ lati bii ọjọ meloo yii ni ibẹru ti wa fun awọn ti wọn n ba Buhari ṣiṣẹ, wọn ko fẹ ọkunrin naa ni ipo naa rara, nitori wọn fura pe bi awọn ba ṣe eru kankan lasiko idibo, ti wọn ba gbe ẹjọ naa lọ si ile-ẹjọ to ga julọ nilẹ wa, ọkunrin yii ni olori awọn ti wọn yoo dajọ nibẹ, ohun to ba si da lẹjọ, ko sẹni to le yi i. Ko tẹ awọn ti wọn n ba Buhari ṣiṣẹ lọrun rara pe ọkunrin naa ni yoo wa nipo yii titi di asiko idibo, gẹgẹ bi ko ṣe tẹ wọn lọrun pe ki Ibrahim Idris ti i ṣe ọga ọlọpaa patapata fi ipo rẹ silẹ bo tilẹ jẹ pe ọjọ rẹ ti le ninu iṣẹ ọlọpaa, o ti yẹ ko maa lọ. Buhari ati awọn ọmọ ẹyin rẹ ko le jẹ ki ọga ọlọpaa yii fẹyinti lasiko yii, nitori oun lo n ṣiṣẹ fun wọn, ẹru si n ba wọn pe ti wọn ba jẹ ko lọ bayii, ti wọn fi ẹni ti ipo naa kan sibẹ, ti ẹni naa ki i ṣe ọmọ Hausa, ti ko si ṣetan lati ṣe magomago, nnkan yoo nira fun wọn lasiko ibo. Bẹẹ naa ni wọn fẹ ki olori awọn adajọ yii tete kuro nibẹ, ki wọn ma dibo loju rẹ, nitori o le ba nnkan jẹ fun wọn to ba jẹ eru ni wọn fi wọle. Ko si ọna ti wọn yoo fi yọ adajọ agba yii, nitori asiko ifẹyinti rẹ ko ti i pe. Iyẹn ni wọn ṣe ro kinni naa paapaa, wọn ni ko ṣe akọsilẹ iye owo to ni ati dukia to ni sinu iwe ijọba. Ni wọn ba ni ki igbimọ ti wọn n pe ni CCT to daamu Saraki titi lọọ mu adajọ agba, ko si lọọ jẹjọ lọdọ wọn lati Mọnde ana yii lọ. Ẹni to kọwe yii to fi fẹẹ ṣe akoba fun adajọ yii, ọkunrin kan to ti ba Buhari ṣiṣẹ daadaa ni, akọwe rẹ ninu ẹgbẹ oṣelu CPC ki wọn too darapọ mọ APC ni. Oun ni wọn ran niṣẹ naa. Bi wọn ba gba iru iwe akoba bayii, o gbọdọ to oṣu kan si oṣu mẹta ti wọn yoo fi ṣe iwadii, amọ igbimọ CCT ko tilẹ wadii ọrọ, wọn ni ki adajọ naa maa bọ niwaju awọn ni. Bi adajọ yii ba si ti lọ, ijọba yoo ni nitori pe o n jẹ ẹjọ, ko le di ipo adajọ agba mu, wọn yoo waa fi ẹlomiiran sibẹ, ọmọ Hausa ni. Ohun aburu pata gbaa ni lati ronu iru nnkan bayii, iwa were, iwa adaluru ati tawọn ọdaran ti wọn wa nile ijọba ni. Bi Buhari ba ro pe wọn n ṣe eleyii nitori ki oun le wọle ibo ni gbogbo ọna, gẹgẹ bii olori ijọba, o yẹ koun naa mọ pe awọn ti wọn wa nidii iru nnkan bayii n ba Naijiria jẹ ni. Wọn n ba aye awọn eeyan jẹ, wọn n da eto ijọba ati ti oṣelu ru, wọn si n di idagbasoke ilẹ wa lọwọ. Buhari gbọdọ mọ pe bi awọn kan ba n ṣe bayii lẹgbẹẹ oun, ti oun ko ba sọrọ, awọn yii ni yoo lu Naijiria fọ, nitori wọn n di iṣọkan ilẹ yii lọwọ ni. Nigba ti wọn ba yọ adajọ agba yii, a jẹ pe ko si ẹka kankan to ṣe pataki ni ti awọn agbofinro tabi ti eto idajọ ti ki i ṣe ọmọ Hausa lo wa nibẹ. Ṣe awọn Hausa nikan lo ni ilẹ yii ni, ṣe awọn nikan ni wọn gbọdọ ṣe olori ileeṣẹ ijọba ni, ki lo de ti Buhari ko fi ọkan tan awọn mi-in ju awọn to ba jẹ ẹya tirẹ lati ọdọ awọn Hausa-Fulani yii lọ. Bawo loun naa ṣe fẹ ki inu awọn to ku dun si ijọba oun, nigba ti wọn ba mọ pe ko ṣe ijọba fun Naijiria, awọn eeyan rẹ nikan lo n ṣejọba fun. Awọn to ronu bayii ko fẹ ilọsiwaju Naijiria, wọn fẹẹ fa Naijiria sẹyin ni. Ọlọrun yoo fa awọn naa sẹyin, ilọsiwaju yoo si jinna si wọn tiletile, bi wọn ti ṣe fẹ ki Naijiria daru ni nnkan tiwọn naa yoo daru, afi to ba jẹ rere ni wọn n wa fun Naijiria nikan. Nnkan ko dara nilẹ yii, Ọlọrun ma jẹ ko pẹ ko too ye wa ni.

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.