Tabi ẹyin ko ri ohun tawọn ọlọpaa Sai Baba n ṣe ni

Spread the love

Ni orilẹ-ede yoowu ti ẹ ba ti ri i ti ọlọpaa n purọ, ti ọlọpaa n ṣeke, ti ọlọpaa wa ninu awọn agbẹyin-bẹbọ-jẹ, ti ọlọpaa n gbe sẹyin oloṣelu, ko si bi orilẹ-ede naa yoo ṣe gberi. Idi ni pe idagbasoke kan ko ni i ṣẹlẹ nibẹ, nnkan yoo kan maa daru fun wọn ṣaa ni. Ninu aburu oriṣiiriṣii to n ba Naijiria loni-in yii, idaji ninu rẹ, ọwọ awọn agbofinro wa lo wa. Ijọba ti fiya jẹ wọn, ijọba ti fi oṣi ta wọn debii pe o loju ọlọpaa ti ẹ gbe sidii owo ti ko ni i ji i, o loju ọlọpaa ti ẹ le fi si ipo kan ti ko ni i jẹ bi yoo ti lo ipo naa lati fi lowo ni yoo maa ṣe, o si loju ọlọpaa ti ki i gba owo ẹyin. Bẹẹ ọlọpaa lo yẹ ko mu ole, ọlọpaa lo yẹ ko mu oloṣelu akowojẹ, ọlọpaa lo si yẹ ko mu awọn ajinigbe ati apanilẹkunjaye gbogbo. Ṣugbọn bo ba jẹ ọlọpaa funra rẹ ni ajinigbe, to jẹ ọlọpaa funra rẹ ni ole, tabi ọrẹ awọn ole, to n gbowo lọwọ wọn, to si n fi ibọn rẹnti fun wọn, tabi to jẹ ọlọpaa funra rẹ ni ọmọọṣẹ awọn oloṣelu, oun gan-an ni wọn n lo lati ṣebajẹ, lati paayan tabi lati kowo-jẹ, bawo ni ọlọpaa yoo ṣe mu awọn oniṣẹ-ibi, ṣebi wọn yoo kan maa pọ si i naa ni. Awọn ọlọpaa Naijiria n purọ, irọ ba aye wọn jẹ, irọ ti wọn si n pa ju ti adigunjale lọ. Awọn ọlọpaa yii ni wọn lọ si ile Saraki, wọn dena mọ ọn pe ko ni i jade. Ṣugbọn nigba ti aṣiri tu, ti gbogbo aye n beere pe iru awọn ọlọpaa wo ree, awọn eeyan naa jade, wọn ni ki i ṣe awọn lawọn lọ sibẹ, wọn ni ọga ọlọpaa ti ni ki wọn wadii awọn ọlọpaa to lọ sile Saraki. Bẹẹ awọn ọga yii mọ pe irọ ni, bo ba jẹ nibi ti epe ti n pa ẹni to ba purọ fun ilu ni, awọn eeyan naa ko ni i ṣe ọjọ keji, bi wọn ba ṣe ọjọ keji laye, wọn ko ni i ṣe ọjọ kẹta, epe araalu ni yoo pa wọn, nitori irọ ni wọn n pa. Awọn agbofinro yii naa ni wọn lọ si ile Ekweremadu ti i ṣe igbakeji Saraki, wọn ko si jẹ ki oun jade, wọn di i mọle. Ọga ọlọpaa to tilẹ wa nibẹ yii ko jọ pe o ni itiju kan bayii, nitori irọ pipa ko jẹ kinni kan loju tiẹ, ati awọn ti wọn n ba a ṣiṣẹ. Wọn yoo purọ naa faa, wọn yoo si maa ṣe bii ẹni pe ko si kinni kan ninu ki eeyan purọ. Bẹẹ aburu ti wọn n ṣe fun ilu yii ju ti ọdaran lọ, o ju ti awọn apaayan lọ, nitori awọn gan-an ni wọn n jẹ ki ọdaran, awọn apaayan ati adigunjale pọ si i. Bi eeyan ba jale, ẹ mu un, bi eeyan ba daran, ẹ mu un, bi eeyan kan ba ṣẹ sofin ilu, ẹ jẹ ko fi imu danrin. Ṣugbọn ka maa gba owo lọwọ ọdaran ati awọn ọbalujẹ, ka maa waa fi awọn aja ọlọpaa le awọn ti ija oṣelu jọ pa wa pọ, iyẹn ko daa, aburu nla ni. Ko si tabi ṣugbọn, bi Buhari ko ba pe awọn eeyan yii ko kilọ fun wọn, awọn yii gan-an ni wọn yoo ba ijọba rẹ jẹ, bi ọrọ naa ba si ṣẹlẹ, ko si ki oun naa ma jere iṣẹ aburu ti awọn ọlọpaa yii ba ṣe.

 

(18)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.