Tabi ẹ o ri ohun to ṣẹlẹ ni Zamfara ni

Spread the love

Bi ẹ ba ranti wahala to ṣẹlẹ nilẹ yii lọdun 1999 si 2003, laye ijọba Ọbasanjọ, nigba ti ọkunrin kan ti wọn n pe ni Yerima gbe ofin Sharia jade, to ni ni ipinlẹ tawọn o, Sharia lawọn yoo maa lo, ẹni yoowu to ba ṣe ohun ti ko dara, Sharia lawọn yoo fi dajọ fun un. Kia lọwọ wọn ti tẹ ọkunrin kan ti wọn ni o ji ẹran gbe, Jangade lorukọ ọkunrin naa, ninu oṣu kẹta, ọdun 2000, ni wọn si dajọ fun un, ni wọn ba ge e lọwọ ni gbangba ode. Lẹyin ti wọn ge oun lọwọ, wọn tun mu awọn mi-in, ṣugbọn mẹkunnu ati araalu ni wọn, niṣe ni inu wọn n dun pe wọn n ge awọn lọwọ, ohun ti wọn n pe ni ofin Sharia niyẹn, wọn ni ofin ti wọn yoo maa lo ree. Amọ gomina to ṣe ofin naa, Yerima, awọn EFCC fẹsun kan an pe o ko owo jẹ, niṣe lo sa kuro nibẹ, o ni oun ko fẹ ki wọn lo ofin Sharai foun, kootu ijọba loun fẹ. Lọsẹ to kọja yii, wọn ju ọkan ninu awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin ti wọn fọwọ si ofin Sharia yii ṣẹwọn ọdun mẹrin, wọn loun naa ko owo jẹ. Owo bii miliọnu mọkanlelọgbọn ni wọn tori ẹ fẹsun kan an, o si jẹwọ pe oun ko jẹ ninu owo naa loootọ. N ladajọ ba ni oun ju u sẹwọn ọdun mẹrin, tabi ko san ẹgbẹrun lọna ọgọfa (120, 000). Akọkọ ni pe eeyan ji miliọnu rẹpẹtẹ bẹẹ ko, o si funra rẹ waa jẹwọ ni kootu pe loootọ loun ji owo yii ko, adajọ si da ẹwọn ọdun mẹrin fun un, ṣugbọn o ni ti ko ba fẹẹ ṣẹwọn, ko san owo itanran, owo itanran naa si waa jẹ owo ti ko to ida mẹwaa iye ti wọn lo ko jẹ. Ọkunrin naa yoo kan mu ninu owo to ji san owo taṣẹrẹ ti wọn bu fun un yii ni. Nibo ni iwa ibajẹ waa pin si o? Ta lo n tan ẹni kan gan-an? Ẹni epe lo pọ ninu awọn ti wọn n ṣejọba yii, epe yoo si pa wọn nijọ kan. Ẹyin lẹ ṣofin pe idajọ Sharia lẹ oo maa lo, bi ẹjọ kan ba si ṣẹlẹ to jẹ mẹkunnu, ẹ oo ti sare fa Sharia yọ, bi ẹ ti n ge wọn lọwọ, bẹẹ lẹ oo maa ge wọn lẹsẹ, tabi ki ẹ maa lu wọn ni aarin ọja ati ni gbangba ode. Ṣugbọn bo ba jẹ awọn oloṣelu ole ti wọn ṣofin yii naa lọwọ tẹ, wọn yoo ni awọn ko lo ofin Sharia ni tawọn, kootu ijọba lawọn fẹẹ lọ, nibi ti wọn yoo ti ju wọn sẹwọn tabi ki wọn fun wọn lowo itanran. Bi ẹ ba waa wi wọn yoo sọ pe Naijiria ko toro, bawo ni orilẹ-ede ṣee toro ti i nilọsiwaju pẹlu iru awọn iwa bayii! Afi ki Ọlọrun gba wa lọwọ awọn eeyan wọnyi, nitori wọn ko ro rere fun wa rara o.

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.