Ta ni yoo gba Ronkẹ silẹ lọwọ wahala yii! Ọrẹkunrin ẹ to ba a laṣepọ fi aṣọ nu un loju ara *N lẹjẹ ba n jade nibẹ lati bii oṣu meji

Spread the love

O ti n lọ bii oṣu meji bayii ti wọn ti ba ọmọbinrin ẹni ọdun mejilelogun (22) kan, Ronkẹ Awoniyi, lajọṣepọ. Lati igba naa lẹjẹ ti n jade loju ara ẹ, ẹjẹ ọhun ko si da titi di ba a ṣe n kọ iroyin yii.

 

Ọrẹkunrin ẹ to n jẹ Ọpẹyẹmi lo ba a laṣepọ, to si fi gele aṣọ ankara nu un loju ara to fi di ohun ti ọmọọlọmọ n ṣe nnkan oṣu fun odidi bii oṣu meji, tẹjẹ ko si dawọ duro mọ.

 

Alejo oloṣooṣu tawọn obinrin to ti balaga maa n gba lasan ni Ronkẹ, ẹni ta a fi ojulowo orukọ ẹ bo laṣiiri kọkọ pe e, afi bi ẹjẹ ọhun ṣe kọ ti ko da mọ fun odidi ọsẹ meji to si bẹrẹ si i ru hangogo bii ẹni ti aisan buruku ti n ba ja lati ọdun pipẹ.

 

Nigba ti wahala yii tẹsiwaju di bii ọjọ mẹtala lọmọbinrin naa jẹwọ ohun to ṣẹlẹ fawọn obi, ẹ ti wọn si gbe e lọ sileewosan, ṣugbọn ti gbogbo itọju awọn oniṣegun oyinbo ko da nnkan kan fun un, kaka bẹẹ, niṣe ni kinni ọhun n buru si i.

 

Lọjọ kẹta to bẹrẹ itọju lọsibitu, iyẹn ọjọ kẹẹẹdogun ti kinni ọhun bẹrẹ lo di ohun ti Ronkẹ ko le sọrọ mọ. Nigba naa lawọn ẹbi ẹ too mọ ọn ni nnkan nla, ti wọn si gbe e gba ile oniṣegun ibilẹ lọ n’Iyana Ọffa.

 

Iwadii ALAROYE fi han pe ololufẹ ni Ọpẹyẹmi ati Ronkẹ jẹ sira wọn, ṣugbọn ti wọn ti kọ ara wọn silẹ fun bii ọdun meji ko too di pe Ronkẹ tun wa a lọ sile, ti iyẹn si ba a laṣepọ, bo tilẹ jẹ pe eyi kọ ni igba akọkọ ti ọrọ a-n-bara-ẹni-laṣepọ yoo waye laarin wọn.

 

Latigba ti Ronkẹ ti ko sinu ajaga yii ni ko ti ri Ọpẹyẹmi ba sọrọ mọ, jagunlani ti pa ẹrọ ibanisọrọ ẹ patapata.

 

Ẹgbọn Ronkẹ kan to n jẹ Wasiu Ayọọla, ẹni tawọn aladuugbo ẹ n pe ni Koba lo fọgbọn agba tan afurasi ọdaran naa mu fun awọn agbofinro n’Iyana Ọffa, nipinlẹ Ọyọ, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹta, oṣu kin-in-ni, ọdun 2019 yii.

 

Ariwo ti awọn ẹbi Ronkẹ n pa seti awọn ọlọpaa ni pe ki wọn mu Ọpẹyẹmi daadaa, nitori niṣe lo fẹẹ fọmọ awọn ṣoogun owo.

 

Bo tilẹ jẹ pe wọn l’Ọpẹyẹmi ti kọkọ jẹwọ fawọn ọlọpaa pe loootọ loun fi aṣọ nu Ronkẹ loju ara lẹyin ti oun ba a laṣepọ tan, ọmọ bibi ilu Ibadan yii sẹ kanlẹ pe oun ko pete aburu kankan si ọmọ wọn nitori ololufẹ oun ni i ṣe, ọrọ pe a n ko owo ẹyọ ati aṣọ funfun jade ko si waye rara.

 

Ninu ifọrọwerọ ẹ pẹlu akọroyin wa, Ronkẹ, ẹni to jade iwe girama lọdun 2016, to si bẹrẹ ẹkọṣẹ telọ ni nnkan bii oṣu meloo kan sẹyin ṣalaye pe “ilu Ìgbàró (nitosi Iyana Ọffa) lemi ati Ọpẹyẹmi ti mọra nigba ti mo ṣi wa nileewe, nitori nibẹ nileewe girama ti mo lọ wa.

 

“Emi pẹlu Ọpẹyẹmi ko fẹra mọ bayii. Ohun to fa ija ni pe o fun ọrẹ mi loyun. Ba a si ṣe pinya lọdun 2016 lemi ti wa si Ibadan, ti oun naa si lọ si Eko.

 

“Nigba ti mo lọ si Igbaro lọdun to kọja (2018), ni mo ri aburo ẹ kan to n jẹ Ọlabisi. Iyẹn lo fun mi ni nọmba foonu Ọpẹyẹmi, o ni ki n pe e ka pari ija wa nitori inu oun ko dun si bi emi pẹlu ẹgbọn oun ṣe n ja.

 

“Mo pe Ọpẹyẹmi, o loun ko si nile, oun maa pe mi ti oun ba de. Lẹyin oṣu kan sigba yẹn lo pe mi pe oun ti de, ki n waa ba oun nile awọn ni Olopoomẹta, to wa lọna Ọlọrunṣogo, n’Ibadan. Mo si lọ sibẹ lọjọ keji ọjọ yẹn, iyẹn ọjọ kejidinlogun (22), oṣu kọkanla, ọdun to kọja.

 

“O ni ṣe ija to wa laarin wa ko ti i tan naa ni, mo ni ti ija ko ba ti i tan, mi o ni i wa a wa. O ni ṣe a ṣi le maa fẹ ara wa lọ, mo ni iyẹn ko le ṣee ṣe mọ niwọn igba to ti fun ọrẹ mi loyun, ati pe emi naa ti lẹni ti mo n fẹ.

 

“Bo ṣe gbọ pe mo ti lẹni ti mo n fẹ lara ẹ ko balẹ mọ. O ni iṣẹ kin ni ẹni ti mo n fẹ n ṣe, mo ni ki lo kan an pẹlu iyẹn. O waa ni bi mo sọ ọ, bi mi o sọ ọ, oun maa mọ ọn. Bo ṣe ko owo ẹyọ jade pẹlu aṣọ funfun kan niyẹn. O ba bẹrẹ si i da owo ẹyọ sori aṣọ funfun. Bo ṣe n ṣe bẹẹ lo n jẹnu wuyẹwuyẹ, ṣugbọn mi o gbọ nnkan to n sọ.

 

“Nigba to ṣe iyẹn tan, o fi ọwọ ẹ mejeeji ra ara wọn. o si fi ọwọ kan mi lori. Lẹyin iyẹn lo sọ pe oun fẹẹ ba mi laṣepọ. Nigba ta a ṣetan lo fun mi ni gele aṣọ ankara kan pe ki n fi nu oju ara mi.”

 

“Lọjọ keji ọjọ yẹn ni nnkan oṣu mi de. O too dá ko dá, n ni mo ba sọ fun awọn obi mi, wọn si mu mi lọ si ọsibitu. Nigba to ya, awọn dokita ni awọn ti ṣe ohun ti agbara awọn ka ni tawọn, ka lọọ fi ẹsẹ ile tọ ọ.

 

“Nigba to di ọjọ kẹẹẹdogun ni mi o le sọrọ mọ ko too di pe wọn gbe mi lọ sile oniṣegun ibilẹ.”

 

Ni ibamu pẹlu ibeere akọroyin wa, obinrin ẹni ọdun mejilelogun (22), yii sọ pe, ‘a ko fi ija tuka lọjọ yẹn. Nigba ta a ṣetan, o (Ọpẹyẹmi), ni ki n je ka ṣere jade, o ra nnkan fun mi ni bia palọ.

 

‘Nigba to di pe nnkan oṣu mi kọ ti ko da mọ ti mo si bẹrẹ si i ru, mo pe Ọpẹyẹmi, obinrin lo gbe e, ẹni yẹn loun ni iyawo ẹ. Igba ti oun funra ẹ waa pe mi pada, bi mo ṣe fẹẹ maa ṣalaye nnkan to n ṣe mi fun un lo kọọti foonu mọ mi leti. Awọn ẹgbọn mi waa ni ki n fi i silẹ pe ṣebi o maa wale ọdun. Awọn ẹgbọn mi ni wọn ba mi mu un ti wọn fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.’

 

Ọmọ bibi ilu Igbaro, nipinlẹ Ọyọ, ni Ọpẹyẹmi. Iṣẹ fọto yiya lo n kọ lọwọ l’Ekoo lẹyin to jade iwe girama nileewe Anglican Grammar School, to wa niluu Oyedeji, nitosi Iyana Ọffa lọdun 2015.

 

ALAROYE gbọ pe wahala ti baba ọrẹ Ronkẹ ti Ọpẹyẹmi fun loyun mura lati ba a fa lo jẹ ki Ọpẹyẹmi jẹwọ pe oun loun fun ọmọ wọn loyun lẹyin to ti kọkọ yari pe oun ko mọ nnkan kan nipa ẹ. Ṣugbọn awọn obi ọmọbinrin naa ni wọn pada tọju ọmọ wọn titi to fi bimọ nitori ọmọkunrin naa ko ya si ọrọ ẹni to fun loyun ati oyun inu ẹ debi ti yoo tọju ọmọ ti obinrin naa bi.

 

Ọpọ awọn to gbọ nipa iṣẹlẹ yii lo gba pe o ṣee ṣe ko jẹ ara awọn ọdọ iwoyii ti wọn maa n fi obinrin ṣoogun ti wọn n dà pè ni yahoo plus ni Ọpẹyẹmi.

 

Bakan naa ni wọn da Ronkẹ funra ẹ lẹbi, wọn ni ki loun paapaa wa lọ sile Ọpẹyẹmi lẹyin to ti fun ọrẹ ẹ loyun tan, ti ko si si ọrọ a-n-fẹra-ẹni laarin wọn mọ.

 

Ṣugbọn ki i ṣe iyẹn nikan ni kudi-ẹ kudi-ẹ to wa ninu ọrọ Ronkẹ. Obinrin yii ko mọ orukọ ọkunrin ti wọn fi bii ọdun meji fẹra wọn naa lẹkun-un rẹrẹ. Ko mọ orukọ baba ẹ, kikidaa Ọpẹyẹmi to mọ ọn si ọhun paapaa, boya ni ki i ṣe adamọdi orukọ ọkunrin naa ni. Idi ni pe ẹbi ọmọkunrin ọhun kan to ba akọroyin wa sọrọ sọ pe Ọpẹifa lafurasi ọdaran naa n jẹ.

 

Akọroyin wa pe ẹgbọn Iya Ọpẹyẹmi kan ti wọn n pe ni Baba Bukky, o ni gbogbo igbiyanju oun lati gba ọmọkunrin naa silẹ ko seso rere pẹlu bi awọn ọlọpaa ṣe sọ pe oun ko kunju oṣunwọn to lati ṣe bẹẹ nitori Eko loun n gbe, mọlẹbi ẹ to si n gbe agbegbe Iyana Ọffa nikan lawọn le gba laaye lati gba beeli ẹ nitori bi afurasi ọdaran ọhun ba sa lọ mọ awọn lọwọ, iru ẹni bẹẹ ni yoo rọrun fun awọn lati lọọ fi pampẹ ọba gbe rọpo ẹ.

 

Titi ta a fi kọroyin yii pari, inu ahamọ awọn ọlọpaa l’Ọpẹyemi ṣi wa, ara Ronkẹ ti n balẹ diẹ diẹ, ṣugbọn ẹjẹ to n jade loju ara ẹ ko ti i da rara.

 

Awọn ẹbi ọmọbinrin naa ti waa rawọ ẹbẹ si awọn agbofinro lati tẹ afurasi ọdaran naa ninu daadaa ko le tete mọ bi yoo ṣe tọju ọmọ awọn ko too di pe ọrọ naa bọwọ sori.

 

Gẹgẹ bi ẹgbọn baba ọmọbinrin naa, Oloye Ajani Michael ṣe sọ, “mo fura pe ọmọkunrin yẹn fẹẹ fi ọmọ wa ṣoogun owo ni. Ẹbẹ ti a n bẹ awọn ọlọpaa ni pe ki wọn mọ ọna ti wọn maa gba  lati jẹ ko tọju ọmọ wa, nitori ẹni to mọ oju siso okun naa lo mọ ati tu u.

 

 

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.