Ta ni ko jẹ ki wọn gbejọba Naijiria fun Abiọla ni 1993?

Spread the love

Kinni kan maa n dun mi, iyẹn naa ni nigba ti awọn eeyan wa ba jokoo sidii ogurọ, tabi nigba ti wọn ba wa nidii iwe iroyin ojumọ to jade, ti wọn ba n jiyan laarin ara wọn, ti wọn n sọ pe Hausa ko mọ nnkan kan, gambari lasan ni wọn, maaluu nikan ni Fulani mọ, ko mọ nnkan mi-in, puruntu ni wọn, ọdẹ ni wọn, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ohun to n jẹ ki ọrọ yii dun mi ni pe aimọkan lo n yọ awọn ti wọn n sọ bẹẹ lẹnu, (ignorance) lawọn oloyinbo n pe e. Bi Hausa ko ba mọkan, ki lo de ti wọn n ṣe akoso wa, akoso orilẹ-ede wa, akoso awa ti a n pariwo pe a lọgbọn, a mọwe, a laju, a gbajumọ lati ọjọ ti wọn ti da Naijiria silẹ. Ohun to ṣẹlẹ ni pe awọn Fulani ti wọn n sọ pe ko mọkan yii, wọn mọ ju wa lọ, paapaa nidii ọrọ oṣelu, ati ọrọ ijọba ṣiṣe. Nitori pe ede ati eto ijọba ti wọn mọ yatọ la ṣe n ro pe wọn ko gbọn, bẹẹ iriri wọn ju tiwa lọ gan-an.

Awọn onkọtan, (Historians), fi idi rẹ mulẹ nigba ti wọn bẹrẹ si i kọ itan orileede Naijiria, pe loootọ o, o ti le ni ẹgbẹrun meji (2000) ọdun ti Naijiria yii ti wa, ṣugbọn wọn ko ni akọsilẹ itan gidi kan ni apa ọdọ tiwa nibi titi di bii ọdun 1800, iyẹn bii igba ọdun sẹyin. Ṣugbọn wọn ni ko ri bẹẹ nilẹ Hausa ati laarin awọn Kanuri ni Borno, nitori awọn eeyan yii ti ni ibaṣepọ pẹlu awọn Larubawa, wọn si ni akọsilẹ to dara ju ti awọn ara Odo-Ọya lọ. Ọpọlọpọ awọn eeyan yii ni wọn mọ bi wọn ti de si apa ibi ti wọn wa, ati ibi ti wọn ti wa, bẹẹ lo si jẹ pe ọpọ awọn ti wọn jẹ ọba lawọn adugbo wọn, onkọwe, onpitan, pọ ninu wọn, paapaa awọn ọba ilu Sokoto. Ko si ohun to si fa a ju pe akọsilẹ ti tete de ọdọ tiwọn lọ, o pẹ ti wọn ti n kọ ede Larubawa silẹ, ko si ti i pẹ pupọ ti awa bẹrẹ si i kọ awọn ede tiwa bii Yoruba, Ibo ati Hausa paapaa silẹ, nigba ti Naijiria si bẹrẹ, ko sẹni to gbọ oyinbo, laarin ọdun 1842 nileewe ṣẹṣẹ de ọdọ wa.

Ohun ti eyi tumọ si ni pe akọsilẹ itan wa ni ede ti awa ko mọ, iyẹn ede Larubawa, lọdọ awọn eeyan yii, wọn si mọ nipa itan ijọba ati bi wọn ti n ṣejoba loriṣiiriṣii. Wọn mọ itan oṣelu atawọn itan ti awa paapaa ko gbọ ri, eleyii si ni eto ti wọn fi n ṣejọba kiri. Ijọba ti Fulani n ṣe yii, ki i ṣe pe wọn ṣẹṣẹ n ṣe e, wọn ti n ṣe ijọba bẹẹ kiri awọn ilẹ West Africa ati North Africa, lati igba ti wọn ti ṣe abapade pẹlu awọn Larubawa lọjọ to ti pẹ. Imọ ati ọgbọn bayii ni wọn fi n mu wa lẹru, to jẹ koda, nigba ti a ba ri i pe ẹru ni wọn mu wa, a ko le ja ara wa gba, a ko le ba wọn ja, nitori wọn mọ ọna ti wọn fi n mu wa. Bi nnkan ba le koko, ti wọn lo ṣọja, ti wọn lo ogun, ti wọn lo gbogbo agbara ti ko ṣiṣẹ, wọn yoo mu ẹni kan ninu wa, wọn yoo fi i ṣe ọba tabi alagbara, oun naa ni wọn yoo si lo le wa lori ti yoo maa ṣe gbogbo ohun ti awọn ba fẹẹ ṣe.

Ko sẹni ti Fulani ko le fi ṣe olori ijọba rẹ, ṣugbọn wọn yoo fi i ṣe olori lasan ni, ko ni i ni agbara ijọba. Loju gbogbo aye, yoo da bii alagbara, yoo da bii ẹni to tobi, ṣugbọn oun naa mọ pe oun ko tobi, o si mọ pe oun ko lagbara, o mọ ibi ti agbara wa, awọn ti wọn si fun un ni agbara naa mọ pe awọn lawọn fun un lagbara, awọn si le gba agbara naa lọwọ rẹ. Bi Fulani ba fi ẹnikẹni ṣe olori ijọba, awọn naa ni wọn yoo maa paṣẹ fun un, ti wọn yoo maa kọnturoolu rẹ, ko si gbọdọ ṣe ohun kan ti wọn ko ba fọwọ si fun un. Nigbakigba to ba fẹẹ ṣe eyi ti wọn ko fọwọ si fun un, iku ni iru nnkan bẹẹ yoo ja si fun un, tabi ki wọn le e tefetefe kuro nile ijọba naa, ki wọn waa sọ ọ di ẹni yẹyẹ to n rare kiri. Awọn Fulani yii mọ ọgbọn ti wọn fi n ṣe eeyan.

Ẹẹmeji ọtọọtọ bayii ni Ẹgbọn Ṣẹgun (Ọbasanjọ), ti ṣe ijọba orilẹ-ede Naijiria, ṣugbọn ẹẹmejeeji to ṣejọba yii, awọn kan ni wọn fi i ṣe e. Awọn Fulani ni. Nigba ti Muritala ku, ẹgbọn yii funra rẹ ti kọwe lati fẹyinti ninu iṣẹ ologun, o loun ko ṣe mọ, o ni iku ọga oun ti ba oun lọkan jẹ kọja ki oun jokoo sibi kan maa ṣejọba. Dajudaju, ọrọ naa ki i ṣe bẹẹ, nitori ko si ẹni ti wọn yoo gbe gun ori ẹṣin ti ko ni i ṣe ipakọ luke, ko si ẹni ti wọn yoo fi oyin si lẹnu ti yoo tu itọ rẹ danu. Bi eeyan ba si mọ ẹgbọn daadaa, yoo mọ pe ẹni to fẹran ipo ati agbara ni, ẹni to fẹran lati maa paṣẹ ni, to si fẹ ki gbogbo aye maa darukọ oun. Bawo ni iru ẹni bẹẹ yoo ṣe waa sọ pe oun fẹẹ fijọba silẹ ni ọmọ ogoji ọdun. Irọ ni! Ẹru lo ba Ẹgbọn Ṣẹgun, o mọ awọn ti wọn niluu, o mọ pe ẹru awọn Fulani ni gbogbo awọn ṣọja ti wọn yi oun ka.

Gbogbo bi wọn ti n pe e ko waa ṣe olori ijọba, bẹẹ lo n taku, afi igba ti T. Y., iyẹn Theophilous Yakubu Danjuma, ṣẹṣẹ sọ fun un pe oun mọ ohun to n ba a lẹru, ko ma foya, awọn yoo sọ ọ. Danjuma ko deede sọ bẹẹ, o ti gba aṣẹ ko too sọ ọ, nitori oun ni olori awọn ṣọja ti wọn jẹ bii oju awọn Fulani yii, lẹyin ti wọn ti pa Muritala tan. Muhammadu Buhari kan yii naa ni wọn fẹ ko ṣe igbakeji Ọbasanjọ tẹlẹ, ṣugbọn wọn tun ro o pe nigba to jẹ Kano ni Muritala ti wa, ki wọn mu ẹni kan to wa lati ibẹ tabi itosi ibẹ, Yaradua nikan lo ti di ọga ninu awọn ṣọja ti wọn wa lati Kano si Katsina ati Kaduna. Iyẹn ni wọn ṣe gbe e lati oye Lẹfutẹnati-Kọnẹẹli, ti wọn si sọ ọ di Brigedia lọjọ kan naa. Nigba ti wọn ti ko awọn eeyan yii ti ẹgbọn, ọkan awọn Fulani yii balẹ. Eyi lo ṣe jẹ ni gbogbo igba ti Ọbasanjọ ṣejọba yii, ko le da nnkan kan ṣe.

Awọn ọmọ Yoruba ti wọn fẹẹ fa oju ẹgbọn mọra, ti wọn fẹẹ sọ ohun ti awọn ṣọja Hausa n ṣe fun un, gbangba lo ti n tu aṣiri wọn, yoo pe Danjuma ati Yaradua pọ pe ki wọn waa jokoo, yoo si pe ẹni naa si aarin wọn pe ko waa sọ ohun to sọ foun ni kọrọ ni gbangba nibẹ. Eleyii ki i ṣe iwa Ẹgbọn Ṣẹgun, nitori lati tẹ awọn Fulani lọrun ni. Awọn eeyan yii lo ṣeto lati ri i pe Sheu Shagari ni wọn fa kalẹ pe ko gba ijọba lọwọ ẹgbọn yii. Ohun ti wọn ṣe ṣe bẹẹ ni lati da gbogbo agbara pada si Sokoto, nigba to jẹ ọmọ Sokoto ni Shagari, ọkan ninu awọn ọmọlẹyin Sardauna Ahmadu Bello ni, minisita si ni lasiko ti baba wọn naa fi ṣejọba. Ko si ohun ti Ọbasanjọ le ṣe si i, afi ki ijọba pada si Sokoto, bo si tilẹ jẹ pe Yaradua ro pe ko si ohun ti oun ko le ṣe nitori ara wọn lohun, nigba ti Danjuma ti faramọ ẹgbẹ NPN tawọn Shagari, ẹgbọn ko le gbin.

Loootọ oju ẹgbọn la nigba to jade nile ijọba, ṣugbọn ko si kinni kan to tun le da ṣe mọ, ko fi bẹẹ niyi laarin awọn Yoruba, ko si ri agbara kan nibomi-in titi ti ọrọ ẹ fi la ẹwọn lọ, inu ẹwọn naa lo si wa ti wọn fi tun lọọ pe e pe ko waa ṣejọba. Bi Fulani ti ri niyẹn, wọn ti fọkan tan Ẹgbọn Ṣẹgun, wọn mọ pe ẹni kan ṣoṣo ti awọn le lo ni ilẹ Yoruba niyẹn. Wọn mọ pe ko ni i da awọn, paapaa nitori iwa to hu lasiko ti wọn ko fẹẹ gbejọba fun Abiọla, to duro ti wọn, to ni Abiọla ki i ṣe Mesaya ti Naijiria n reti. Ẹgbọn ja raburabu lati ṣe kinni kan tabi meji nigba to gbajọba tan, ṣugbọn kia ni wọn ti da a pada saaye rẹ, ko si gbọdọ ma ṣe ohun ti wọn ni ko ṣe. Akọkọ ni pe yoo da ijọba pada fawọn Hausa-Fulani, ko si ni i tu ọrọ iku Abiọla wo rara. Ẹgbọn ṣe bi wọn ti paṣẹ fun un, eyi lo mu un gbejọba fun Yaradua, bo tilẹ jẹ pe gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ, Peter Odili, tabi ẹlomi-in to sun mọ ọn lo fẹẹ gbejọba fun, bẹẹ ni ko si da sọrọ Abiọla titi to fi lọ, ṣugbọn igbẹyin rẹ ree foun naa.

Ariwo ti ẹgbọn pa pe wọn fẹẹ pa oun laipẹ yii, ẹgbọn mọ pe ki i ṣe Buhari lo fẹẹ pa oun, o mọ pe awọn Fulani ni. O mọ pe bi ọwọ wọn ba tẹ oun loootọ, ọrọ naa yoo le foun o, iyẹn lo ṣe tete pariwo. Ki lo de ti Fulani le fọkan tan Ẹgbọn Ṣẹgun, ti wọn ko le fọkan tan Abiọla? Ki lo de ti wọn ko gbejọba fun un gan-an? A o ma ba alaye ọrọ yii lọ lọsẹ to n bọ. Ẹ fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si mi, mo fẹẹ mọ ero yin lori ọrọ yii, mo fẹẹ mọ bi ọrọ ti mo n sọ ye yin tabi ko ye yin!

 

(47)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.