Ta lo sọ pe Buhari ko mọ oṣelu i ṣe

Spread the love

Oṣelu ti bẹrẹ bayii, oriṣiiriṣii nnkan lẹ o maa ri. Saraki ati awọn ẹmẹwa rẹ ki i ṣe ole bayii mọ, koda, Aarẹ Muhammadu Buhari ko ba a ja mọ, bẹẹ ni ko si de ara rẹ mọ inu ile ko ni ki awọn sikiọriti sọ fun Saraki pe oun ko fẹẹ ri i. Buhari lo ku to n ranṣẹ pe Saraki, oun lo ku to n wa ojuure rẹ, oun lo ku to n beere ọna ti awọn yoo gba lọwọ ẹ, ọna ti awọn yoo gba ti awọn le fi wọle lọdun to n bọ. Ohun ti awọn eeyan n sọ tẹlẹ ni pe Buhari ko mọ nipa oṣelu, wọn ni ko mọ kinni kan, ki i ṣe oloṣelu, iyẹn lo ṣe n ṣe bo ṣe n ṣe. Bi Buhari ko ba mọ nipa oṣelu, ko le rọ awọn Aṣiwaju Bọla Tinubu ti wọn gbe e wọle da si ẹgbẹ kan. Bi ko ba mọ nipa oṣelu, ko le le awọn Atiku Abubakar ati Rabiu Kwankwaso ti wọn jọ du ipo aarẹ kuro ninu ẹgbẹ APC ti gbogbo wọn jọ n ṣe. Paripari rẹ ni pe bi Buhari ko ba mọ nipa oṣelu, ko ni i ranṣẹ pe Saraki bayii o. Ṣebi o ti ri i pe Saraki n lọ bayii, wọn ti lo ọgbọn ofin titi lati fi dẹruba a ki wọn si le e, ṣugbọn Saraki yọ mọ wọn lọwọ, lati igba ti ile-ẹjọ si ti da a lare pe ko ji owo, bo tilẹ jẹ pe gbogbo aye mọ pe ole paraku ni, lati igba naa loun naa ti jade, to sọ ara rẹ di ọba, to n kawọn oloṣelu ẹgbẹ rẹ jọ. Ko si ohun meji ti wọn fẹẹ ṣe, wọn fẹẹ kuro ninu ẹgbẹ APC, wọn fẹẹ lọ sibomi-in, o ṣee ṣe ko jẹ inu PDP, Buhari si mọ pe eleyii yoo jẹ iṣoro foun. Nitori pe Buhari n mura lati wọle lẹẹkeji bayii, nitori rẹ lo ṣe tun fẹẹ di ọrẹ Saraki, ti yoo si pa gbogbo aṣiṣe ati iwa ole to hu rẹ pata rẹ. Bi iru nnkan bayii ba n lọ laarin awọn oloṣelu, ko si ẹni ti adanu ọrọ naa maa n ba ju awọn araalu funra wọn lọ. Asiko yii ni wọn yoo fi ori ji gbogbo awọn oloṣelu ti wọn ba ji owo ko, koda, awọn mi-in ti wọn jẹ apaayan ati awọn agbẹyin-bẹbọjẹ ti wọn ti ṣe aburu ti ko lounka fun orilẹ-ede yii, asiko yii ni olori ijọba yoo fori ji wọn, wọn yoo ni ki wọn maa lọ lalaafia. Bẹẹ ni ki i ṣe pe iwa aburu ti wọn hu ti tan, bẹẹ ni ki i ṣe pe ijọba ri owo ti wọn ji ko gba pada, bẹẹ ni ki i ṣe pe wọn ko tun ni i ṣe aburu bayii mọ. Nigba ti awọn aṣebajẹ ba n fi gbogbo ọjọ wa ni ipo agbara, ti awọn ọbayejẹ n fi gbogbo igba di ipo oṣelu mu, iṣoro gidi ni yoo jẹ fun orilẹ-ede yii lati ni idagbasoke gidi kan. Bi Buhari ba mọ pe Saraki ko dara, ole ni, o ji owo ilu ko, to si ti fi odidi ọdun mẹta kọyin si i, ko yẹ ko jẹ asiko to fẹẹ du ipo bayii ni yoo tun maa fa oju rẹ mọra. Bo ba fa oju Saraki mọra ti Saraki tun di nnkan nla, nigba wo ni ko tun ni i pada sidii awọn iwa ibajẹ to ti hu sẹyin, nigba wo ni ko ni i ran awọn onibajẹ mi-in lọwọ lati tọju owo ti wọn ba ji, tabi lati fi agabagebe bo ododo mọlẹ, ti wọn yoo si maa ko ba orilẹ-ede Naijiria yii nibi gbogbo. Loootọ ni Buhari fẹẹ fi han aye pe oun mọ nipa oṣelu, ṣugbọn ẹ ma tori oṣelu ba Naijiria jẹ, ẹ jẹ ka ni ilọsiwaju bi gbogbo aye ṣe n nilọsiwaju o!

(48)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.