Ta lo n tan Atiku to bayii tori Olorun

Spread the love

Boya awọn eeyan naa lo maa n tan awọn oloṣelu to bayii ni o, boya awọn oloṣelu funra wọn ni wọn si maa n tan ara wọn, awọn nikan lọrọ naa ye. Abubakar Atiku ni ko si ẹlomi-in ninu ẹgbẹ PDP to le fibo gbajọba lọwọ awọn APC bi ki i ṣe oun nikan. O ni oun nikan loun mọ gbogbo ọgbọn ati ete wọn, oun si le lo ọgbọn wọn naa lati fi gbe wọn ṣubu, pe ti ẹgbẹ PDP ko ba fa oun kalẹ, nnkan le ṣoro fun wọn. Nibi ti wahala ti n wa naa ree o. Saraki naa ti sọ pe bi PDP ba mọ pe loootọ lawọn fẹẹ le APC lọ, afi ki wọn fa oun kalẹ, Makarfi ni bi oun ba wọle, ọmọ Naijiria gbogbo yoo fi ọkan tan oun, bẹẹ ni Kwankwaso si sọ pe boya ẹnikẹni fẹ boya ẹnikẹni ko fẹ, oun ni ipo aarẹ Naijiria kan ni ọdun 2019. Gbogbo awọn ti wọn n sọrọ yii, ọmọ ẹgbẹ PDP ni wọn o, ohun to si tumọ si ni pe afaimọ ki ija nla ma bẹ silẹ lẹyin ti wọn ba dibo abẹle wọn to n bọ lọna yii tan. Gbogbo awọn alagbara yii le sa pada ninu ẹgbẹ yii ki wọn sare wa ẹgbẹ mi-in ti ko loluwa tabi orukọ lọ, ki wọn ni awọn yoo du ipo aarẹ. Amọ ni ti Atiku, tiẹ yatọ diẹ, nitori o pẹ ti oun ti n rin kiri nitori ọrọ yii kan naa, o si ti ba ẹgbẹ APC yii fa a naa to ọjọ mẹta, o ba wọn fa a nigba to wa ni PDP, o tun ba wọn fa a ninu ẹgbẹ naa funra rẹ, bo ṣe waa tun ro pe oun loun le gbajọba lọwọ wọn yii, oun nikan lo ye. Ijọba ti ko ri gba nigba to wa ni sango-ode, ti eegun ọmọde wa lara rẹ, bawo ni yoo ṣe gbajọba naa ni aago mẹjọ alẹ bayii, nigba ti baba ti le lọmọ aadọrin ọdun. Loootọ Atiku lorukọ ati okiki, kinni naa iba dara fun un bi awọn ọmọde inu ẹgbẹ rẹ ko ba jade, nitori pẹlu bi gbogbo wọn ṣe rọ jade yii, yoo ṣoro fun ẹnikẹni ninu wọn lati bori APC. Atiku, yaa tun ọrọ rẹ ro, ko o tun ero rẹ pa, ko o ma jẹ ki awọn kan tan ọ gbowo lọwọ rẹ, ki iwọ funra rẹ naa ma si tan ara rẹ jẹ o.

(34)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.