Ta lo fun SSS laṣẹ lati dena de wọn nile-igbimọ aṣofin?

Spread the love

Titi di bi a ṣe n wi yii, ko ti i le si ẹnikan to jade pe oun loun ran awọn SSS lọ si ile-igbimọ aṣofin pe ki wọn ti ibẹ pa. Aarẹ Buhari ati awọn eeyan rẹ ni awọn kọ lawọn ran wọn. Bẹẹ awọn eeyan yii ko gbọdọ jade lai jẹ pe wọn gba aṣẹ. Ọrọ naa si buru ju bi awọn eeyan ṣe ro o si lọ. Bi ẹnikẹni ba ro pe ohun to ṣẹlẹ yii, ọrọ Bukọla Saraki, tabi Yakubu Dogara, tabi ti Ike Ekweremadu ni, a jẹ pe tọhun ko mọ ohun to n lọ rara ni. Idi ni pe ohun to ṣẹlẹ yii ju bẹẹ lọ, awọn to n ṣe eleyii, bii igba pe wọn fẹẹ doju Naijiria de patapata ni. Ṣe bo ba ṣe ọfiisi aarẹ naa ni wọn lọ ti wọn ṣe iru eleyii, ṣe bi wọn yoo ṣe maa ti kinni naa sira wọn ree, ti wọn yoo ni wọn ko mọ ẹni to ni ki SSS lọ sile-igbimọ aṣofin. Bẹẹ ọrọ APC ko ye ni ninu gbogbo ohun to ṣẹlẹ yii. Awọn ni wọn ti kọkọ sọ lakọọkọ pe awọn ko mọ kinni kan ninu ọrọ naa, pe ki awọn ti wọn n ṣewadii ọrọ wadii kinni naa daadaa, ki wọn si fiya jẹ awọn to ba lọwọ si i. Afi bi wọn tun ṣe yipada biri, ti wọn ni awọn ti gbọ nnkan mi-in, awọn ti gbọ pe Saraki n ko tọọgi bọ wa sile-igbimọ aṣofin ni, iyẹn lawọn SSS ṣe lọọ ba wọn nibẹ. Ṣugbọn ileeṣẹ aarẹ ni awọn ko ran SSS niṣẹ, ṣe EFCC lo waa ran wọn niṣẹ ni o, abi bawo. Aṣilo agbara, ati lilo agbara nilokulo lo wa lọrọ awọn ti wọn ba Buhari ṣiṣẹ, iṣẹ ti wọn ko ran wọn ni wọn n jẹ, ọpọlọpọ aburu ni wọn si ti ṣe lẹnu ọjọ mẹta yii ti ko ṣee maa fẹnu sọ. Ṣebi EFCC lọ si ipinlẹ Benue, wọn gbẹsẹ le owo wọn ni banki, bi ko si jẹ gbogbo aye pariwo, ijọba ipinlẹ naa ko ni i ri owo na. Tabi ki i ṣe awọn ọlọpaa yii naa ni wọn lọọ di Saraki mọ ile rẹ pe ko gbọdọ jade, ti awọn EFCC si jokoo ti Ekweremadu lọrun lati aarọ ṣulẹ, ti wọn ni awọn waa mu un ni. Meloo leeyan tilẹ fẹẹ ka ninu aburu ti ijọba yii n ṣe. Nigba ti ijọba kan ko ba tẹle ofin, ti ko tẹle idajọ awọn onidaajọ, ijọba bẹẹ ko fẹ alaafia niluu, bẹẹ ni ko le pẹ ti wọn yoo fi da ilu ru mọ ara wọn lori. Ta lo paṣẹ fun SSS lati lọọ tilẹkun mọ wọn nile igbimọ aṣofin? Ta ni? Afi ki ijọba wadii awọn ti wọn wa nidii ẹ ki wọn si fi wọn jofin. Bi bẹẹ kọ, ariwo tun ku lẹyin ọrọ naa, itiju nla ni yoo si maa jẹ fun ijọba Buhari titi laelae.

 

(30)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.