Ta la waa fẹẹ gbagbọ bayii Ọlọrun

Spread the love

Awọn oloṣelu ti wọn n ṣejọba nilẹ Naijiria yii ko lọrun, Ọlọrun funra rẹ ni yoo si da wọn lẹjọ to ba yẹ. Lọsẹ to kọja ni iroyin buruku kan jade pe awọn alakatakiti ẹsin kan ti tun de si adugbo ijọba ibilẹ Tangaza, ni ipinlẹ Sokoto. Wọn ni wọn de tibọn-tibọn ni o, wọn si mura bii Boko Haram, wọn n gba owo iṣakọlẹ lọwọ awọn oniluu, wọn ni ki wọn maa sanwo bi wọn ba fẹran ẹmi ara wọn. Bi iroyin yii ṣe jade lawọn ọlọpaa sare bẹ sita giragira bii iṣe wọn, wọn ni ko si ẹni kankan to n gbowo onilẹ ni Sokoto, wọn ni bẹẹ ni wọn ki i ṣe Boko Haram, njẹ awọn wo waa ni. Wọn ni awọn mọ wọn daadaa, awọn Fulani onimaaluu to wa lati Mali ni. Nigba ti wọn beere pe ki lawọn ohun ija oloro bii ibọn bii ada n wa lọwọ awọn Fulani onimaalu lati Mali, awọn araabi ko ri esi gidi fọ sibeere yii, wọn n jẹnu mẹ-in mẹ-in lasan ni. Bawo lawọn ọlọpaa yii ṣe sare mọ pe awọn Fulani onimaalu lawọn eeyan yii lati Mali? Ṣe wọn ti mọ pe wọn ti wa nibẹ tẹlẹ ni? Bi wọn ba mọ pe wọn wa nibẹ, ṣe wọn faramọ ibọn ati awọn ohun ija oloro to wa lọwọ wọn ni? Awọn eeyan yii n purọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari ni, wọn n tan an, wọn ko fẹ ko mọ aṣiri ohun to n lọ. Tabi boya wọn si sọ fun un, oun ni ko ka ọrọ naa si nnkan kan. Tabi bawo ni awọn alakatakiti, awọn afẹmiṣofo mi-in yoo ṣe tun gba ọna ẹburu wọ ipinlẹ Sokoto, ti awọn ọlọpaa yoo si sọ pe onimaalu ni wọn. Aṣiri awọn ọlọpaa yii ti tu, nitori awọn ọmọ oniluu ti sọ pe awọn kan lo ko awọn eeyan naa wa sibẹ tẹlẹ pe ki wọn le daabo bo awọn lọwọ awọn ọmọ ogun Boko Haram ti wọn ba fẹẹ waa ba awọn, diẹ ni wọn gba tẹlẹ, afi bi wọn ṣe rọ ara wọn de ti wọn si di pupọ ni agbegbe naa, ti wọn ko ṣee le jade mọ, ti wọn fi ibẹ ṣebugbe, ti wọn si bẹrẹ si i ṣejọba le awọn eeyan lori. Njẹ ẹ gbọ iru iwa were bẹẹ yẹn ri lode aye yii? Ohun to ṣẹlẹ tawọn ọlọpaa n purọ fun wa niyẹn o. Bawo ni Ọlọrun ko ṣe waa ni i mu awọn eeyan to n ṣejọba ẹtan bayii? Ọlọrun yoo mu wọn dandan ni!

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.