Sultan, ẹ sọrọ naa fun Buhari jare

Spread the love

Sultan ilẹ Sokoto, Ọba Muhammad Sa’ad Abubakar, sọ laipẹ yii pe nnkan ko lọ deede ni Naijiria, afi ti a ba n tan ara wa. O ni nnkan ko dara rara, sibẹ awọn oloṣelu ko yee purọ fawọn eeyan pe nnkan n lọ daadaa, ṣugbọn gbogbo ẹni to ba wa niluu yoo foju ara rẹ ri i pe nnkan ko dara. Bi iru ọrọ bayii ba ti ẹnu Sultan ilẹ Sokoto jade, ko si ohun to dun to o, nitori ohun ti ọpọ awọn onilaakaye eeyan ti n sọ ree, ti awọn oloṣelu n pa wọn lẹnu mọ, ti wọn n sọ pe irọ ni wọn n pa. Ṣugbọn nibi ti ọrọ de duro yii, oore kan ni Sultan yoo ṣe fun gbogbo ọmọ Naijiria, oore naa si ni pe yoo wọle tọ Buhari lọ, yoo sọ fun un pe nnkan ko daa ni Naijiria, boya baba naa yoo gbọrọ si i lẹnu. Sultan, gbera! O dọdọ Buhari!

(36)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.