Suleman ba awon omobinrin e meji lo po lÉkoo ti balẹ sọgba-ẹwọn

Spread the love

Ni ti Suleman Usman, ẹni ọdun mẹtadinlogoji, ọrọ rẹ da bii pe o lọwọ kan aye ninu, nitori awọn ọmọbinrin meji to bi lo ki mọlẹ, to si ba wọn sun karakara, koda, oun lo gba ibale awọn ọmọbinrin mejeeji naa.     Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja ni awọn ọlọpaa wọ Suleman lọ si kootu majisreeti to wa ni Igboṣere, niluu Eko, niwaju Adajọ M.F Ọnamusi. Ẹsun ti Agbefọba to moju rẹ ba kootu, Sajẹnti Friday Mameh, fi kan an ni pe o gba ibale awọn ọmọbinrin rẹ meji, ti ọkan jẹ ọmọ ọdun mẹjọ, ti ekeji si jẹ ọmọ ọdun marun-un.

Ile rẹ to wa ni ojule keji, adugbo Balle, Apapa, niluu Eko, ni awọn ọlọpaa lo ti huwa naa. Agbefọba ni ọpọ igba lo ti ki awọn ọmọdebinrin mejeeji naa mọlẹ, to si ba wọn sun. O ṣalaye pe iyawo rẹ lo ka a mọ ibi to ti n ba ọkan ninu wọn sun, kia lo si mu ẹjọ rẹ lọ si tesan ọlọpaa to wa ni Igboṣere, nibi to gba de kootu.

Ẹsun naa tako awọn abala kan ninu ofin to de iwa ọdaran ti ipinlẹ Eko n ṣamulo rẹ, tọdun 2015.

Sulema, ẹni to tako ẹsun naa loun ko jẹbi rẹ pẹlu alaye. Adajọ M.F Ọnamusi paṣẹ pe ki wọn maa mu olujẹjọ naa lọ si ahamọ ọgba-ẹwọn, to si ni ki wọn fi ẹda iwe ẹsun rẹ ṣọwọ si ẹka to n gba adajọ nimọran fun amọran lori ẹsun ti wọn fi kan an naa.

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.