Sport Awọn iṣẹlẹ nla 2018 lagbo ere idaraya Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kin-in-ni

Spread the love

 

Ori ko ẹgbẹ agbabọọlu MFM FC yọ ninu ijamba ọkọ niluu Akungba, nipinlẹ Ondo, awọn diẹ farapa.

Ọjọ kẹwaa, oṣu keji

Abraham Kiprotich, ọmọ ilẹ Kenya, gba ipo kin-in-ni  Access Bank Lagos City Marathon.

Ọkọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹta

Anthony Joshua na Joseph Parker ilẹ New Zealand lati gba ami-ẹyẹ WBO, WBA, IBF ati IBO.

Ogunjọ, oṣu kẹrin

Kooṣi Arsenal ilẹ England, Arsene Wenger, kede pe oun yoo fiṣẹ silẹ lẹyin ọdun mejilelogun.

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹrin

Ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona ilẹ Spain gba ife-ẹyẹ Copa del Rey nigba ọgbọn lẹyin ti wọn na Sevilla lami-ayo marun-un si odo.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹrin

Awọn ololufẹ Kilọọbu Heartland FC lu Yusuf Garba to ṣe rẹfiri ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Plateau United daku lẹyin ẹsun magomago.

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu karun-un

Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ilẹ England gba ife-ẹyẹ FA Cup kejila lẹyin ti wọn na Manchester United lami-ayo kan si odo.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu karun-un

Kilọọbu Real Madrid ilẹ Spain gba ife-ẹyẹ Champions League kẹtala lẹyin ti wọn na Liverpoool ilẹ England lami-ayo mẹta si ẹyọ kan.

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu karun-un

Zinadine Zidane, Kooṣi Real Madrid, kede ifẹyinti rẹ latari aigbọra-ẹni-ye to waye laarin oun atiAarẹ Madrid, Florentino Perez.

Ọjọ keji, oṣu kẹfa

Aṣọ ti Super Eagles ilẹ wa fẹẹ wọ ni idije agbaye gba ipo kin-in-ni laarin awọn orilẹ-ede to ku.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹfa

Goli Super Eagles ati Wolverhampton Wanderers, Carl Ikeme, kede pe oun ti bọ lọwọ kansa lẹyin ọdun kan to bẹrẹ itọju.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹfa

Super Eagles ilẹ Naijiria ja nibi idije agbaye nilẹ Russia lẹyin ti Argentina na wọn lami-ayo meji si ẹyọ kan.

Ọjọ karun-un, oṣu keje

Ajọ ere bọọlu Afrika (CAF), yan Amaju Pinnick, Aarẹ NFF ilẹ Naijiria bii igbakeji aarẹ CAF.

Ọjọ keje, oṣu keje

Ọmọ ilẹ Naijiria ti wọn bi si New Zealand, Israel Adesanya, fiya jẹ Brad Tavares ilẹ Amẹrika lati gba ami-ẹyẹ Welterweight Ultimate Fighting Championship.

Ọjọ kẹwaa, oṣu keje

Olokiki agbabọọlu ilẹ Portugal, Cristiano Ronalso, darapọ mọ Kilọọbu Juventus ilẹ Italy lẹyin ọdun mẹsan-an ni Real Madrid, ilẹ Spain.

Ọjọ kẹta, oṣu kẹjọ

Atamatase ilẹ Naijiria, Ahmed Musa, darapọ mọ Al-Nassr ilẹ Saudi Arabia, lati Leicester ilẹ England.

Ọjọ kejila, oṣu kẹjọ

Ogbontagiri agbabọọlu ẹlẹyin ori tabili, Aruna Quadri, di ọmọ Naijiria akọkọ lati gba ife-ẹyẹ ITTF Challenge Nigeria Open.

Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹjọ

Agbabọọlu Super Eagles ati Chelsea ilẹ England, Victor Moses, fẹyinti ninu bọọlu gbigba fun Naijiria.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹjọ

Ẹgbẹ agbabọọlu awọn obinrin wa, Falconets, ja kuro nibi idije agbaye ni France leyin iya ami-ayo meji si ẹyọ kan lọwọ Spain.

Ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹjọ

Ayara-bii-aṣa agbaye nni, Usain Bolt, balẹ silẹ Australia lati bẹrẹ igbesi-aye tuntun gẹgẹ bii agbabọọlu fun Central Coast Mariners.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹjọ

Salwa Eid Naser, ọmọ ilẹ Naijiria to ti n sare fun Bahrain gba goolu fun ilẹ naa  nibi idije Asian Games. Ebelechukwu Agbapuonwu lorukọ rẹ tẹlẹ, ipinlẹ Anambra lo si ti wa.

Ọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan-an

Naomi Osaka, ọmọ ilẹ Japan na Serena Williams lati gba ife-ẹyẹ US Open. Oun ni ọmọ Japan akọkọ to gba iru rẹ ninu itan.

Ọjọ kẹrinla, oṣu kẹwaa

Adewale Maṣebinu tawọn eeyan mọ si Masevex gba ami-ẹyẹ Light Heavyweight Boxing Champion ilẹ Naijiria lẹyin to na Kabiru Towolani lalubami.

Ogunjọ, oṣu kẹwaa

Atamatase ilẹ wa, Asisat Oshoala, gba ife-ẹyẹ liigi awọn obinrin ilẹ China lẹẹkeji laarin ọdun meji pẹlu Dalian Quanjian.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹwaa

Baaluu agberapa Vichai Srivaddhanaprabha to ni Kilọọbu Leicester City ilẹ England ja bọ, oun atawọn mẹrin mi-in padanu ẹmi wọn.

Ọjọ kejilelogun, oṣu kọkanla

Ogbontagiri agbabọọlu Cote d’Ivoire, Didier Drogba, fẹyinti ninu bọọlu gbigba lẹyinọgbọn ọdun.

Ọjọ kejidinlogun, oṣu kejila

Awọn alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ilẹ England yọ Jose Mourinho gẹgẹ bii kooṣi lẹyin ọdun meji.

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu kejila

Ole Gunnar Solskjaer di kooṣi Arsenal ilẹ England titi di ipari saa 2018/2019.

 

Other News

Mikel Obi n lọ Fenerbahce

Balogun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ilẹ Naijiria, Mikel Obi, n lọ ẹgbẹ agbabọọlu Fenerbahce ilẹ Turkey laipẹ ti nnkan ko ba yipada. Eyi waye lẹyin to fagile adehun rẹ pẹlu Tianjin Teda ilẹ China.

Ẹni ọdun mọkanlelọgbọn naa gbe igbesẹ ọhun lopin ọsẹ to kọja lẹyin ọdun meji to de kilọọbu naa.

Oṣu kin-in-ni, ọdun 2017 ni Mikel tọwọ bọ iwe adehun ọdun mẹta pẹlu Tianjin Teda leyin to kuro ni Chelsea ilẹ England to wa lati ọdun 2006, latigba naa lo si ti n ṣe bẹbẹ fun wọn.

Plateau United ni Mikel ti bẹrẹ lọdun 2002, 2004 lo si kọja si Lyn Norway, nibi to gba de Chelsea ni 2006.

Lati ọdun 2005 lo ti n gba bọọlu fun Naijiria, Flying Eagles lo si ti bẹrẹ ko too gba igbega.

…bẹẹ ni Efe Ambrose kuro ni Hibernain FC

Bakan naa ni Ambrose Efe to n gba bọọlu jẹun ni Hibernian FC ilẹ Scotland ti fi ẹgbẹ naa silẹ. Agbabọọlu Super Eagles yii igbesẹ ọhun lẹyin ti wọn fẹẹ ba a ṣe adehun mi-in, ninu eyi ti wọn ti fi kun awọn ẹtọ rẹ.

Bo tilẹ jẹ pe awọn alaṣẹ kilọọnu naa parọwa si i nitori ọkan ninu awọn aayo wọn ni, ẹni ọgbọn ọdun naa ti pinnu lati gba kilọọbu mi-in lọ, eyi ti lara rẹ jẹ Cardiff City ilẹ Wales to ti fifẹ han si i.

Oṣu keji, ọdun 2017 ni Efe darapọ mọ Hibernian FC, lẹyin oṣu diẹ lo si tọwọ bọ iwe adehun ọdun meji, ṣugbọn ko lo o pari bayii.

Kaduna United ati BayelsaUnited ilẹ Naijiria lo ti kọkọ gba bọọlu ko too kọja si Ashdod ile Israel lọdun 2010, nibi to gba de Celtic ni 2012.

Ọdun 2007 lo bẹrẹ si i gba bọọlu fun Naijiria, Flying Eagles lo si kọkọ ṣe bẹbẹ fun ko too gba igbega.

 

 

 

(27)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.