Simeon to ji adiẹ ati kireeti ẹyin repete ti foju bale-ẹjọ

Spread the love

Ọjọ Aje, ana yii, ni kootu majisireeti to wa n’Iṣabọ, l’Abẹokuta, fi oju ọkunrin kan, Simeon Obi, han pe o ji ọgọta adiẹ ati kireeti ẹyin rẹpẹtẹ, gbogbo owo ohun to ji naa si jẹ aadọrun-un Naira (90,000), oun naa si loun jẹbi ẹsun ọhun loootọ.
Inspẹkitọ Bukọla Abọlade to ka ẹsun naa setiigbọ kootu ṣalaye pe lọjọ kẹrin, oṣu kẹsan-an, ati lọjọ karun-un, oṣu kẹwaa yii, ni Simeon atawọn yooku ẹ ti wọn ti sa lọ bayii, wọ ile ọsin adiẹ Bamifunho Ọlawale, eyi to wa ni abule Ọgbagba, Ajebọ, l’Abẹokuta, ti wọn si ko ọgọta adiẹ atawọn kireeti ẹyin to pọ gidi.
Nigba tọwọ ba Simeon lo jẹwọ fawọn ọlọpaa pe ọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Julius Lawson loun maa n ta awọn adiẹ naa fun toun ba ji wọn tan.
Gbogbo awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ ole adiẹ yii ni wọn ti na papa bora, ṣugbọn Simeon nikan tọwọ ba naa ko jiyan rara, bi wọn ṣe beere lọwọ ẹ pe ṣe o jẹbi ẹsun igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi ati ole jija lo ti ni bẹẹ ni, oun jẹbi.
Adajọ agba S.T Bello faaye beeli silẹ fun un pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta Naira (50,000), pẹlu oniduuro meji niye kan naa. O paṣẹ pe awọn oniduuro naa gbọdọ maa gbe ni agbegbe kootu, ki wọn si le ṣafihan ẹri owo-ori wọn sisan deede.
Bi awọn eto yii ko ba pe, adajọ ni ki wọn maa gbe ọdaran naa lọ si ọgba ẹwọn titi di ọjọ keji, oṣu kọkanla, ti igbẹjọ rẹ yoo tun waye.

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.