Sifu Difẹnsi ṣekilọ fawọn darandaran atawọn agbẹ

Spread the love

Latari bi ibẹru awọn ajinigbe ṣe gba ọkan araalu.; ikilọ ti wa fawọn darandaran atawọn agbẹ lati so ewe agbejẹ mọwọ, nitori ko saaye fun rogbodiyan mọ; paapaa lasiko ọdun yii.

Solomon Iyamu to jẹ ọga-agba ajọ Ajọ Nigeria Security and Civil Defence Corps (NSCDC), ta a mọ si Sifu Difẹnsi nipinlẹ Ekiti lo ṣe ikilọ ọhun lopin ọsẹ to kọja nibi ipade to ṣe pẹlu akojọpọ ẹgbẹ awọn agbẹ, awọn darandaran atawọn to n ta nnkan jijẹ. O ni alaafia gbọdọ jọba laarin awọn eeyan naa ti wọn ko ba fẹẹ ri pipọn oju ijọba.

 

Iyamu ṣalaye pe ko saaye fawọn darandaran lati ko maaluu sun mọ awọn oko FADAMA nipinlẹ Ekiti, ati pe ẹni ti Sifu Difẹnsi ba ri to n gbe ibọn kiri yoo da ara rẹ lẹbi.

 

Bakan naa lo kilọ fawọn to n fi oogun kokoro sawọn ounjẹ ti wọn n ta lasiko ti wọn ba ko o de ọja tan, o ni ko si aaye iru ẹ mọ, nitori o lewu fun jijẹ. Iru ikilọ yii naa lo wa fawọn kan ti wọn ti lọọ fi oogun sinu awọn odo lati pa ẹja, atawọn to fẹẹ maa dana sun igbo kiri lati ri ẹran pa.

 

O waa sọ pe kawọn Fulani ati Hausa darandaran forukọ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn silẹ fun idanimọ, ko le rọrun lati mọ awọn ajoji to fẹẹ ṣiṣẹ ibi.

 

Nigba to n fesi, alaga ẹgbẹ darandaran, Miyetti Allah Cattle Breeders Association of Nigeria, Alaaji Mohammad Nasamu, sọ pe awọn ajoji lo n da wahala silẹ, bẹẹ lo rọ ijọba ipinlẹ naa lati ran awọn fijilante ẹgbẹ naa to n ṣiṣẹ lọsan-an loru ninu igbo lọwọ.

 

Bakan naa ni ojugba rẹ to jẹ alaga awọn ẹya Hausa ṣeleri lati fọwọ sowọ pọ pẹlu ijọba atawọn agbofinro lori eto aabo ati ọrọ alaafia.

 

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.