Shehu Shagari ni, ni toun, oun o fẹran ofin awọn ṣọja rara

Spread the love

Alaaji Shehu Shagari to ṣẹṣẹ ku lọsẹ to kọja yii lo lọọ ba wọn yanju gbogboọrọ Sharia yii nibi ipade apero lori ofin tuntun fun Naijiria ti awọn aṣoju-ṣofin ṣe ni 1977 si 1978. Ṣe ọrọ naa ti di ohun ti awọn Musulumi lati ilẹ Hausa ati awọnẹlẹsin to ku, paapaa awọn Kristẹni, ti wọn jọ wa nibi apero yii ti n tori ẹ tutọ si ara wọn loju. Bawọn Musulumi ilẹ Hausa naa ti n tẹnu mọ ọn pe ko si kinni kan ti yoo ṣẹlẹ ti awọn ko ni i gbe ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun to jẹ ti Sharia wọle sinu ofin Naijiria yii, bẹẹ lawọn Kristẹni aarin wọn n sọ pe kinni naa ko dara, yoo tubọpin Naijiria si meji ni. Bi awọn kan ti n fi ohun lile sọ ọ, bẹẹ lawọn kan n fi ohunẹrọ sọ ọ, ṣugbọn-tabi kan ko si si nibẹ, ọrọ naa ti fẹẹ da ọta saarin awọn ti wọn n ṣe ijiroro naa, kaluku ti n foju si ara wọn lara pe eleyii ni ko fẹ Sharia, eleyii leeyan tiwa to fẹ Sharia. Nigba naa ni Shagari ju ọrọ lulẹ.

Awọn ti Shagari bu ni awọn ti wọn ṣẹṣẹ lọọ ṣe agbekalẹ ofin tuntun yii, iyẹn igbimọ ti ijọba awọn ologun gbe dide, ti wọn fi ogbologboo lọọya nni, Rotimi Williams, ṣe olori wọn. Ṣe awọn ni wọn ṣe agbekalẹ gbogbo ofin tuntun yii, ofin naa si ni awọn aṣoju-ṣofin tawọn eeyan dibo fun yii n yẹwo, ti wọn fẹẹ mu eyi to dara ninu rẹ, ki wọn si sọ awọn ti ko ba dara nibẹ nu, to si jẹ ninu agbekalẹwọn yii ni Sharia wa, ti Sharia naa si fẹẹ dija laarin awọn to n sọrọ ofin. Shagari ni ki awọn aṣofin yii ma yọ ara wọn lẹnu, o ni igbimọ Rotimi Williams ni ko ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ, o ni bo ba jẹ wọn ṣe iṣe wọn bii iṣẹ ni, gbogbo ariyanjiyan to fẹẹ dija to n waye yii ko ni i waye rara. O ni wọn ko ṣiṣẹ kankan o, wọn kan jokoo, wọn n pariwo lasan ni. O ni bo ba jẹ wọn ṣiṣẹ tawọn ọmọNaijiria gbe fun wọn, gbogbo awọn naa lawọn iba foju ri i.

Shagari ni idi ti oun fi sọ pe awọn eeyan naa ko ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ ni pe iyatọ kan ko si ninu awọn ofin ti wọn gbe kalẹ yii ati ofin ti awọn ologun ti gbe kalẹ latiọjọ yii, o ni bii igba ti wọn ko wọn jọ lasan ki wọn waa fọwọ si ofin awọn ologun ni, nitori igbimọ naa ko ṣe ofin tiwọn funra wọn. Alaaji Shehu Shagari ni nibi tiọrọ naa de duro bẹẹ, oun yoo fi apẹẹrẹ mẹwaa silẹ ni kiakia, to jẹ ofin awọn ologun ti wọn mu wa ni 1966 si 1976 ni. O ni awọn ologun lo ṣeto pe ki Naijiria ni ipinlẹ mọkandinlogun, ipinlẹ mọkandinlogun yii naa si ni awọn Rotimi Williams tun ni oun lo daa ju yii. Awọn ologun ni wọn ṣeto pe ki ijọba apapọlagbara ju awọn ijọba ipinlẹ lọ, eyi naa si ni awọn Williams tun mu wa pe ki awọn maa tẹle yii, ko jẹ ijọba apapọ ni yoo maa paṣẹ fun awọn ipinlẹ, eyi ti ko yẹ ko ri bẹẹ rara.

Shagari ni ki wọn lọọ wo ọrọ naa lati ilẹ, wọn yoo ri i pe eto ti ijọba ologun ṣe pẹlu ofin wọn lori ọrọ Sharia naa ni awọn ti wọn gbe ofin tuntun ti awọn n jirorole lori kalẹ yii naa tun bẹrẹ si i sọ. O ni awọn ologun yii ni wọn ti ni awọn yoo ni ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun fun Sharia to ba ya, iyẹn naa si ni awọn Rotimi Williams gbe wa pe ki awọn sọ dofin, ki awọn kuku fọwọ si i lati ni ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun fun ofin Sharia, gẹgẹ bi awọn ṣọja ṣe fẹ. O ni bo tilẹ jẹ pe kinni naa dara fun awọn Musulumi loootọ, ẹni yoowu ti yoo ba ṣejọba pẹlu ofin naa bi awọn baṣe e bi wọn ti wi yii, ko si ki tọhun ma koju iṣoro. O ni bo ba jẹ awọn igbimọ yiiti ṣe eto naa, ti wọn yẹ ofin naa wo daadaa ni, o ṣee ṣe ki wọn ma gbe e wa rara, tabi ki wọn ti ni kinni naa yoo di igba mi-in, tabi ki wọn fi i silẹ fawọn oloṣelu ki wọn yanju rẹ bi ijọba ba de ọwọ wọn.

Ọrọ to sọ niyi ti gbogbo eeyan patẹwọ fun Alaaji Shehu Shagari, paapaa nigba ti wọn ri i pe ọrọ gidi lo n sọ, ti awọn ẹri si wa ninu agbekalẹ ofin ti awọn Rotimi Wiliams ṣe loootọ, bẹẹ ọkan awọn eeyan ko lọ sibẹ rara, afi nigba ti ọkunrin to ti ṣe minisita eto inawo labẹ awọn Yakubu Gowon yii (Ṣe oun lo gba ipo lọwọOloye Ọbafẹmi Awolọwọ lẹyin ti iyẹn kuro ninu ijọba Gowon ni 1971) gbe kinni naa jade. Ọkunrin kan ti wọn pe ni Olu Awotesu to ti agbegbe Rẹmo lọ si ibi ipade yii lo da si ọrọ ti Shagari sọ, nigba ti yoo si fi pari ọrọ rẹ, ẹrin lawọn kan bu si, bẹẹ lawọn ti ọrọ naa ye gan-an fajuro. O ni, “Ni Naijiria, ara gbogbo wa ko ya rara! (We are all sick)” O ni ki awọn eeyan ma ro pe oun n ṣe were tabi pe oun ko mọ ohun ti oun n sọ, o ni ori oun ko yi rara, oun kan mọ pe gbogboọmọ Naijiria ni ara wọn ko ya ni.

“Ara Naijiria ko ya. Loootọ loootọ, ara Naijiria ko ya rara! Orilẹ-ede to n ṣaarẹni Naijiria, o ti bajẹ denudenu, o ti ra, koda, o n yọ idin! Ohun to ba Naijiria jẹyii ki i ṣe nnkan meji ju pe awa ti a jẹ ọmọ Naijiria ko ni ootọ lọ. Ootọ jinna si wa pupọ, a ki i ṣododo pẹlu ara wa!” Bi Olu Awotesu ti wi naa ree, awọn eeyansi n wo ẹnu rẹ bi wọn ti n bu si ẹrin, ṣugbọn niṣe loju oun funra rẹ pọn, ẹrin ko pa ẹrẹkẹ rẹ rara ni. O ni loootọ ẹni ti yoo ba sọ ọ yoo ni awọn oloṣelu lo ba ilẹyii jẹ, wọn si ba a jẹ loootọ, nitori iwa adanikanjẹ, iwa ko-ṣa-jẹ-tiwa-nikan, iwa afemi-afemi ati ẹlẹyamẹya to ba gbogbo nnkan jẹ fun wọn. O ni bo ba jẹ awọn oloṣelu wọnyi ronu, ti wọn si ṣe ijọba daadaa ni, ki i ṣe ibi ti Naijiria wa nigba naa ni yoo wa, wọn yoo ti goke agba, wọn yoo si ti bọ lọwọ ewu gbogbo.Ṣugbọn awọn oloṣelu lo ba nnkan jẹ julọ.

O ni ṣugbọn eeyan ko le maa bu awọn oloṣelu nikan, o ni nigba ti awọn ṣọja gbajọba, awọn eeyan ro pe wọn yoo mu nnkan daa ni, ṣugbọn ọrọ wọn ko yatọ si ẹni ti a ni ko waa wo gọbi, to de ọhun tan to ni kin niyi gọbigọbi yii. O ni awọn ti wọn ni awọn waa tun ilu ṣe, awọn naa tubọ ba gbogbo ẹ jẹ ni, koda wọn lu u fọ ju bi awọn oloṣelu ti ṣe e sibẹ tẹlẹ lọ, nitori awọn tun ni agbara ibọn ti wọn fi n halẹ mọ gbogbo eeyan, agbara naa lo si pada waa bu wọn lọwọ, nigba ti wọn si ti ba gbogbo rẹ jẹ tan ni wọn n wa ẹni ti yoo ba wọn tun un ṣe. O ni yoo ṣoro lati tun un ṣe, nitori lati abule titi de ilu, titi de awọn ipinlẹ ni wọn ti ba ofin jẹ, ko si si ẹni to le mu awọn ofin ologun ti wọn n ṣe ṣẹ bi ki i baa ṣe agidi tabi agbara ibọn. O ni bo ba jẹ loootọ lawọn fẹẹ ṣe ofin tuntun fun Naijiria, afi ki awọn kọkọ bura lati fi ootọ inu ba ara awọn ṣe.

Abiọla lo gba wọn lọwọ wahala lọjọ naa lọhun-un, nitori oun ni ki awọn eeyan yii ma laagun jinna, ofin to dara ju ti wọn yoo ṣe ni eyi ti yoo fun awọn ọmọwọn, iyẹn awọn ti wọn ba n bọ lẹyin wọn, lanfaani lati le ṣe ijọba ilẹ yii daadaa, ki wọn si ni ifẹ Naijiria ju bi awọn ti wọn wa nibẹ nigba naa ti ni ifẹ orilẹ-ede naa lọ. O ni bi awọn ba si fẹẹ ṣe eyi, akọkọ ohun ti awọn gbọdọ ṣe ni ki wọnṣofin kan ni Naijiria ki ofin naa si mulẹ, ofin naa si ni pe ko sẹni kan to gbọdọran ọmọ rẹ lọ si ilẹ okeere lati lọọ kawe kankan. O ni ki gbogbo ọmọ ti awọn bi wa nile, ki wọn kawe wọn nile, ki wọn duro lọdọ awọn ẹbi ati awọn araale wọn, ki wọn mọ aṣa ati iṣe awọn eeyan, ki wọn si ni imọ to jẹ ti ibilẹ, yatọ si imọ tiwe nikan. O ni bi gbogbo olowo ati ọlọla ti n ran awọn ọmọ wọn lọ siluu oyinbo yii, ti wọn n lọọ kawe, ti wọn n sare pada wa, tabi ti pupọ ninu wọn n jokoo sọhun-un, o ni o ṣee ṣe kawọn ọmọ naa ma wulo fun wa o.

Niṣe ni wọn sinmi si i lọjọ naa, wọn si ni ijirooro naa yoo tun maa lọ ni. Afi lojiji ti nnkan yipada, awọn oloṣelu gbe iṣe wọn de poo!

 

 

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.