Sharia da wahala silẹ laarin awọn to n ṣofin tuntun fun Naijiria, awọn oloṣelu ilẹ Hausa taku mọ awọn to ku lọwọ

Spread the love

Nigba ti Ọgagun Agba Oluṣẹgun Ọbasanjọ n lọ si orilẹ-ede Amẹrika lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun 1977, oun ti ro pe bi oun yoo ba fi pada de, igbimọ to fẹẹ ṣe apero lori ọrọ ofin ilẹ wa yoo ti ba iṣẹ wọn jinna, koda, awọn aṣojuṣofin naa yoo ti maa palẹmọ lati pada lọ sile kaluku wọn. Ṣugbọn ọrọ naa ko ri bẹẹ rara. Ṣebi ọjọ kẹfa, oṣu kẹwaa, naa loun ti ṣebura fun wọn, o si ti ṣe eto ijiroro lori ofin tuntun ti Naijiria yoo lo baye ba ti daye awọn oloṣelu naa, ko si sohun ti yoo tun da iṣẹ naa duro ju ki ohun gbogbo maa lọ ba a ti kọwe rẹ lọ. O kan waa jẹ pe awọn aṣoju-ṣofin ti wọn ṣebura fun naa ko lo ọjọ mẹta nibi ipade naa, kaluku fẹsẹ palẹ suẹ suẹ, wọn si pada si ibi ti wọn ti wa, awọn ti wọn wa lati ilẹ Hausa dari lọ sile, awọn ti wọn wa lati ilẹ Ibo naa ko duro, awọn Yoruba ti ki i ṣe ara Eko naa si pada si adugbo tiwọn.

Ọbasanjọ ṣe kinni naa kiakia ni, o fẹẹ dajọba pada fawọn oloṣelu, o fẹ ki awọn alagbada maa waa pada ṣejọba wọn. Ni 1977 yii, o ti di ọdun kọkanla tawọn ṣọja ti gbajọba, bo tilẹ jẹ ọdun diẹ ni wọn ṣeleri pe awọn yoo lo, wọn ti lo kọja ohun ti wọn sọ gan-an. Amọ lati igba ti awọn Muritala ti de lọdun 1975 ni wọn ti ni awọn yoo lọ lọdun 1979, ko si ni i si ṣọja nile ijọba mọ lẹyin ọjọ naa, awọn oloṣelu ni yoo ku ti yoo maa ṣejọba wọn. Bo tilẹ jẹ pe awọn ti wọn fẹẹ fi ipa gbajọba ti yinbọn pa Muritala, sibẹ, awọn Ọbasanjọ ti wọn gbajọba naa ni awọn ko ni i yi ọjọ naa pada, awọn yoo maa ba iṣẹ naa lọ gẹgẹ bi ohun ti ọga awọn ti fi lelẹ ni. Iyẹn ni wọn ṣe kọkọ gbe awọn igbimọ kan dide to ṣe ilana ofin ti awọn oloṣelu yoo lo fi ṣejọba, Rotimi Williams ni wọn si fi ṣolori igbimọ naa, wọn si ti ni

ilana ofin tigbimọ yii ṣe lawọn aṣoju-ṣofin ti wọn dibo yan pẹlu awọn tijọba apapọ funra wọn fa kalẹ fẹẹ jirooro le lori, ki wọn le sọ kinni naa dofin, ki iṣẹ si pari lori iyẹn. Ọbasanjọ ti ṣebura fun wọn, ki wọn bẹrẹ iṣẹ wọn ni gbogbo ilu n reti. Ṣugbọn wọn ko le bẹrẹ gẹgẹ bi eto naa ti lọ tẹlẹ, Ọbasanjọ funra rẹ ko si tete mọ ohun to de, nigba toun ti jade, o lọ si Amẹrika lati lọọ ki wọn. Ọhun lo wa to fi gbọ pe awọn aṣofin ko ṣiṣẹ, wọn ti pada sile. Nibẹ naa lo ti n beere ohun to de. Awọn aṣofin yii ni awọn ko le jokoo ṣiṣẹ pẹlu awọn eto ti ijọba ologun naa ṣe kalẹ fawọn, nitori ile ti awọn fẹẹ gbe ko ti i rẹdi, wọn ko ti i ṣe Satelite Village, lọna Badagiri, nibi ti wọn ni awọn fẹẹ gbe ni ko si omi nibẹ, awọn mi-in ko si ni bẹẹdi, wọn kan wa gbu-n-duku ni. Yatọ si eyi, wọn ni wọn ko ṣeto bi awọn yoo ṣe maa jẹun nibẹ fawọn.

Bi Ọbasanjọ ṣe de lo bẹrẹ iṣẹ, o ni ki wọn tun abule naa ṣe kia, ki wọn si ri i pe gbogbo ohun to yẹ ki wọn ni lo wa nibẹ. Otẹẹli ti wọn pe ni Federal Palace ni wọn gbe iṣẹ ounjẹ fun, wọn ni ki awọn oṣiṣẹ wọn tete lọ sibẹ, ki wọn si ṣe ile ounjẹ nla kan, nibi ti wọn yoo ti maa se ounjẹ fawọn aṣoju-ṣofin yii ni tọsan-toru, ati nigba yoowu ti wọn ba ti fẹ ounjẹ. Wọn ṣeto ibusun to daa fun wọn, wọn ṣe sinima ati ile igbafẹ sibẹ pẹlu, wọn ni bi wọn ba de ti wọn fẹẹ ṣe faaji, aaye wa fun wọn lati ṣe e. Ninu awọn aṣoju-ṣofin yii ti sọ tẹlẹtẹlẹ pe awọn ko le ṣe kawọn ma mu iyawo awọn dani lọ si iru irin-ajo bẹẹ, bo si tilẹ jẹ pe ijọba ti sọ fun wọn pe ki i ṣe ode faaji, ode iṣẹ ni, awọn kan ninu wọn ni aja ki i lọ ki kolokolo ẹ gbẹyin, bi igbin ba fa, ikarahun yoo tẹle e, awọn yoo mu awọn iyawo awọn dani dandan. Abi wọn fẹ kawọn aṣẹwo waa maa ka awọn mọ ni.

Ọbasanjọ ni oun ti gbọ, ẹni to ba fẹẹ mu iyawo rẹ dani ko mu un dani. Kinni kan ni ṣaa o, ijọba ko lowo lati bọ iyawo aṣofin kankan o, wọn ko si ni i ṣeto mi-in fun wọn yatọ si eyi ti wọn ba ti ṣe fun ọkọ wọn. Ẹni to ba mu iyawo rẹ wa, ko ti mura lati ra ohun ti yoo se fun un, tabi ohun ti yoo fẹ, ati bi yoo ṣe ṣetọju ọkọ rẹ, nitori ijọba ko ni i fun ẹnikẹni lowo o. Awọn aṣofin naa ni awọn gbọ, awọn ti wọn si le mu iyawo wọn wa mu un wa, ṣugbọn ọpọlọpọ wọn ni ko mu iyawo wa mọ nigba ti wọn ti gbọ pe awọn funra awọn lawọn yoo sanwo ounjẹ ati gbogbo ohun ti iyawo wọn ba fẹ, ijọba ko ni i ba wọn da si i. Ọbasanjọ ti paṣẹ pe gbogbo atunṣe abule ti awọn aṣofin naa fẹẹ gbe gbọdọ ti pari ki oṣu kẹwaa, ọdun 1977 naa to pari, ohun ti wọn si ṣe naa niyẹn, nigba ti oṣu naa yoo fi fẹyin lelẹ, ijọba ti tun abule Satelite ṣe.

Eyi dun mọ awọn aṣoju-ṣofin naa ninu, wọn si bẹrẹ si i rọ de lati ọgbọnjọ, oṣu kẹwaa, nigba ti yoo si fi di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa, 1977 yii, ẹsẹ gbogbo awọn ti wọn fẹẹ ṣofin tuntun fun Naijiria ti pe siluu Eko, ọgbọn-o-le-nigba (230) ni gbogbo wọn. Gbọngan nla ti wọn n pe ni National Hall, ni gbagede Tafawa Balewa, lawọn aṣofin yii fẹẹ lọ, awọn oṣiṣẹ ibẹ naa si ti mura silẹ de wọn, ko tun sohun to gbọdọ fa idaduro kankan. Bẹẹ lo si ri lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu kọkanla, ọdun 1977, ti gbọgan Tafawa Balewa Square kun fun oriṣiiriṣii awọn eeyan, ti agbada n pe agbada ran niṣẹ, ti awọn mi-in si wa sibẹ pẹlu kootu jimba jimba, tawọn alaṣẹ ibilẹ si lọ bii rẹrẹ. Ko sẹni ti yoo ri wọn ti ko ni i mọ pe awọn ara-ọtọ eeyan kan lawọn yii, awọn to si ti n tẹle iroyin nipa wọn tẹlẹ mọ pe awọn aṣojuṣofin ni gbogbo wọn.

N ni wọn ba wọle o, iṣẹ ba bẹrẹ pẹrẹwu lẹsẹkẹsẹ ti wọn de. Lọjọ akọkọ yii ni wọn ti sọ laarin ara wọn, ti wọn si sọ kinni naa dofin, ti wọn fi ranṣẹ sijọba pe ọjọ mọkanlelogun pere lawọn yoo fi ṣe gbogbo ohun ti awọn ba fẹẹ ṣe, eleyii jẹ bii oṣu kan, nitori wọn ko ni i ka Satide ati Sannde mọ ọn. Bi wọn ti jokoo lọrọ bẹrẹ lori ofin Naijiria tawọn oloṣelu yoo lo, ohun to si kọkọ fa wahala nibẹrẹ eto naa ni ọrọ ofin Sharia ti wọn fẹẹ gbe wọnu ofin. Oloye Rotimi Williams to jẹ alaga eto agbekalẹ ofin yii ti kọkọ ṣalaye lori ẹsẹ kọọkan ofin ti wọn gbe kalẹ, ki awọn aṣoju-ṣofin yii le mọ ohun ti wọn yoo jiroro le lori ati ibi ti wọn yoo ti mu ijiroro wọn. Nibẹ lo ti ṣalaye fun wọn lori ọrọ ofin Sharia ati idi ti awọn ṣe ṣe agbekalẹ rẹ. Ọrọ ofin yii lo si kọkọ mu awọn aṣofin naa maa tutọ sira wọn loju nijọ akọkọ ti wọn jokoo gan-an.

Aṣofin kan to wa lati agegbe Ọwọ, Reverend Joseph Agbowuro, lo ṣide ijiroro naa lẹyin ti Williams ti ṣalaye ọrọ rẹ tan. Agbowuro ni oun dupẹ lọwọ Rotimi Williams ati awọn ọmọ igbimọ rẹ fun iṣẹ ribiribi ti wọn ṣe lori ọrọ ofin yii o, eyi to kan n ba oun lẹru ni ofin Sharia ti wọn fẹẹ gbe wọ inu ofin Naijiria yii, nitori ohun ti yoo di wahala lọjọ iwaju ni. O ni bo ba ṣe pe ero ati ọgbọn ori wa ri bakan naa, to si jẹ laakaye awọn eeyan lori ọrọ ẹsin ṣe bakan naa ni, ko ni i si wahala rara lori pe ki wọn maa lo ofin Naijiria pẹlu ofin toloyinbo lẹgbẹẹ ara wọn ni Naijiria, sugbọn awọn kan wa ti wọn jẹ alakatakiti, iwa wọn ko si ni i fi wọn silẹ, wọn si le fi ofin yii kẹwọ ki wọn fi da wahala ọrọ ẹsin silẹ, iyẹn ni gbogbo awọn ti awọn jokoo lati jiroro lori ọrọ ofin yii ṣe gbọdọ ronu wo lori ẹ daadaa.

Awọn aṣofin ti wọn wa lati ọna ilẹ Hausa ko ri ọrọ naa bẹẹ rara. Akọkọ, bi ẹnikẹni yoo ba tilẹ jiroro lori ọrọ ofin Sharia, ko ni i jẹ Rẹfurẹẹni, ọga awọn Kristẹni. Ki lo mọ nipa ẹsin Islaamu, ki lo si mọ nipa ofin Sharia ti yoo fi maa da si i. Atojubọ lasan leleyii, ko sẹni ti yoo gba fun un. Iyẹn lawọn ti wọn jẹ Musulumi, paapaa awọn ara Oke Ọya ṣe mura rẹ silẹ, wọn n reti pe ko sinmi ki awọn ya bo o ni. Nigba ti ko si tete dakẹ, ọkunrin kan, Alaaji Nuhu Bamalli, to jọ pe ọrọ naa ka lara ju awọn ẹlẹgbẹ rẹ lo pariwo mọ Agbowuro, o ni ko sinmi jare, ọrọ to n sọ ko ba nnkan ti awọn waa ṣe mu. O ni awọn ko wa lati jiroro lori ohun ti yoo da wahala silẹ, ki rẹfurẹẹni yii ma da wahala kan saarin awọn o. Ṣugbọn Rẹfurẹẹni Agbowuro fun un lesi lẹsẹkẹsẹ, o ni ọrọ toun n sọ ko le da wahala silẹ, ọrọ to le mu nnkan rọgbọ ni.

Nigba naa ni Alaaji Abubakar Rimi dide, lati adugbo Gwarzo ni wọn ti yan oun wa si ipade ohun. O ni oun dupẹ lọwọ Oloye Williams fun iṣẹ daadaa to ṣe lori ofin Sharia, nitori awọn eeyan ti n sa fun un tẹlẹ, bẹẹ ohun to yẹ ko ti wa ninu ofin ilẹ yii tipẹ ni. Rimi ni ṣebi gbogbo awọn ti wọn ṣejọba nilẹ yii mọ pe ohun ti awọn n lo nilẹ Hausa niyẹn, awọn oyinbo alawọ-funfun mọ ọn fawọn, awọn ṣọja ti wọn ṣejọba naa mọ ọn, ko si nnkan tuntun ninu rẹ rara, o ti pẹ to ti wa nibẹ, ko si yẹ ko ja ẹnikẹni laya, ko yẹ ko mu ariyanjiyan kankan wa. O ni loootọ lo yẹ ki awọn fẹsọ ṣalaye ẹ daadaa ko le ye ara wọn, ṣugbọn ki i ṣe ohun ti ẹnikan yoo maa tori rẹ ko awọn araalu lọkan soke, ti yoo ni kinni kan yoo ṣẹlẹ bi wọn ba lo Sharia. O ni ko sohun to jọ ọ, nitori ofin alaafia ni Sharia o.

Alaaji Ibrahim Dazuki to wa lati Rodinga ni Sokoto naa ko jẹ ki ọrọ naa tutu, bo tilẹ jẹ pe ohun ẹrọ loun fi ṣalaye ọrọ Sharia fawọn ti wọn jọ n ṣejiroro naa gbogbo. O ni kawọn eeyan ma fi oju ofin lasan wo Sharia, o ni bi wọn ba fi oju ofin lasan wo Sharia, wọn yoo maa ṣe aṣiṣe lori rẹ ni. O ni ki i ṣe ofin lasan, nitori Sharia lo ṣaaju aye awọn Musulumi, Musulumi kan ko si le si bi ko ba si Sharia, aye Musulumi ko si le pe bi ko ba si labẹ ibi ti wọn ti n lo ofin Sharia lawujọ wọn. O ni ko si ohun to le sọ pe ki awọn Musulumi ma lo Sharia ni Naijiria, nigba ti awọn kan wa nilẹ yii ti wọn n lo ofin oyinbo ti wọn ko tilẹ mọ bo ṣe jẹ, ki waa ni wọn yoo ni ki awọn Musulumi ma lo Sharia si, nigba to jẹ ofin to n ṣe atọna aye wọn ni. O ni ofin Sharia ti wa tẹlẹ, ohun ti awọn n beere fun bayii ni ki ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun to jẹ ti Sharia naa wa, gẹgẹ bi wọn ṣe ni ninu ofin tawọn oyinbo ti a n lọ.

Nigba naa ni Ọladimeji Longẹ to wa lati Muṣin sọrọ. O ni gbogbo ohun ti wọn n fa yii ko ti i yẹ ki wọn bẹrẹ si i fa a o, ko si yẹ ko jẹ oun lawọn yoo fi bẹrẹ iṣẹ gidi ti awọn waa ṣe. O ni iṣẹ pọ lọwọ awọn ju ki awọn ti asiko naa gbe ọrọ Sharia lọwọ lọ, nitori bi awọn ko ba mura daadaa, idi ọrọ naa lawọn yoo wa ti awọn ko ni i lọ nibẹ, nitori lara awọn ohun to n yọ Naijiria lẹnu lati ọjọ yii wa ni. Joseph Wayas ti wọn yan lati agbegbe Obudu lo sọrọ naa to pa gbogbo awọn eeyan lẹrin-in ṣugbọn ko dun mọ awọn Hausa ti wọn jẹ Musulumi ninu rara. O ni bi oun ba raaye ni, bo ba si jẹ toun ni, oun yoo pa kinni naa rẹ pata kuro ninu iwe ofin ati ijiroro awọn ti awọn waa ṣe yii ni, nitori ki i ṣe ohun to yẹ ki wọn gbe wa siwaju awọn rara. O ni awọn ọrọ gidi wa nilẹ ju gbogbo eleyii lọ, ki waa ni wọn yoo fi ọrọ Sharia da awọn duro si.

Boun ti sọ ni Arabinrin Janet Akinriande sọ, o ni gbogbo ohun ti wọn n wi yii, oun ko ri si i ni toun. O ni gbogbo ofin ti awọn Oloye Williams ni awọn ṣe agbekalẹ rẹ, gbogbo alaye to si ṣe lati gbe awọn ọrọ wọn lẹyin fihan pe wọn ko ka awọn obinrin si kinni kan. O ni ninu gbogbo ofin ọhun ti wọn n pariwo, ọọkan ibo ni wọn ti darukọ awọn obinrin tabi ti wọn ṣeto ti yoo daabo bo awọn obinrin lọwọ oriṣiiriṣii awọn iya ti wọn fi n jẹ wọn lawujọ. O ni bo ba jẹ iyẹn ni wọn fẹẹ sọ bayii, ko sẹni ti yoo jiyan tabi ti yoo ni ọrọ naa ko dara, ṣugbọn kaka ki wọn ṣe iyẹn, ọrọ Sharia ni wọn lo ọpọlọpọ wakati ti wọn fi n sọ, bii ẹni pe Sharia gan-an lawọn tori rẹ wa si ijokoo ni. Arabinrin Abigael Ukpabi naa sọ bẹẹ, o ni ofin naa ko sọrọ awọn obinrin to rara, afi bii ẹni pe wọn ko tilẹ si ni Naijria ni tiwọn.

Lọrọ kan, ọrọ naa ni wọn fa ti ilẹ fi ṣu, nigba ti ọjọ si n lọ ni wọn ni ki kaluku maa waa lọ sile, awọn yoo tun maa ba kinni naa lọ bo ba di ọjọ keji ti i ṣe ọjọ keji, oṣu kọkanla, ọdun 1977. Amọ ki ọrọ too da bẹẹ, ọkunrin kan lo pa gbogbo eeyan lẹrin-in nijọ yii, nigba ti oun ati alaga igbimọ naa, Adajọ Udo Udoma, woju ara wọn gidigidi. Ṣẹgun Ọkẹowo lorukọ rẹ, oun laṣoju awọn ọmọleewe, ṣe ọkan ninu awọn aṣaaju ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni. Nijọ akọkọ to n lọ sipade naa, aṣọ to wọ ba ni lẹru gidigidi. Ṣokoto turọsa nla kan lo wọ, ti iyẹn pupa yoo, ṣẹẹti to si wọ le e naa, niṣe niyẹn pupa. Bẹẹ lo de fila pupa, o si wọ bata pupa, afi bii igba ti Ṣango ba n lọ sode ija, to waa ṣe ohun gbogbo ni pupa ni pupa. Bẹẹ ni Ṣẹgun Ọkẹowo ki i ṣe Ṣango, o jọ pe o fẹẹ dẹruba awọn ẹlẹgbẹ ẹ ti wọn jọ pe jiroro lori ofin yii lasan ni.

oun naa fẹẹ sọrọ, o si n nawọ, Adajọ Udoma ko da a lohun. Amọ nigba ti adajọ naa ti i ṣe alaga ijokoo yii ri aaye tirẹ, o kọju si i, “Ọgbẹni, ki lo waa de ti iwọ ṣe gbogbo aṣọ ni pupa bayii, iru imura yii ko ba ijokoo yii mu!” Ọkunrin olori ẹgbẹ awọn akẹkọọ naa dahun, “N ko jẹ ẹnikẹni lalaye lori aṣọ ti mo ba wọ, ohun to ba wu mi ni mo le wọ lọ sode!” Adajọ ni, “Haa, ijokoo yii ki i ṣe ode lasan, ijokoo ofin ni, a si gbọdọ ṣe ohun gbogbo lọna to ba ofin mu. Bi o ba mọ pe o fẹẹ maa sọrọ nibi, afi ki o wọ aṣọ to ba ijokoo yii mu, bi bẹẹ kọ, n ko ni i jẹ ki o sọrọ!” Ṣẹgun Ọkewo dahun, “Hẹn-ẹn, ẹ ma jẹ ki n sọrọ nigba yẹn, ko sija nibẹ bi ẹ ko ba fẹẹ gbọrọ lẹnu mi. Ẹ maa sọ ọ!” Bẹẹ lọkunrin naa jokoo, ko si sẹni kan to le sọrọ fun bii iṣẹju-aaya, ko too waa di ẹẹkan naa ti gbogbo wọn bu gbamu, nigba ti ẹni kan ninu awọn ọmọ Yoruba ibẹ pariwo, “Ṣango Ọba Kosooo!”

 

(18)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.