Shakirat pokunso n’Ibadan, onigbese to ṣe oniduuro fun lo sa lọ

Spread the love

Ọlawale Ajao, Ibadan

Inu ọfọ lọkọ atawọn ọmọ iyaale ile kan, Shakirat Rasheed, wa bayii lẹyin ti obinrin naa ti pokunso, to si pa ara ẹ sinu ile to n gbe laduugbo Awọtan, n’Ibadan.

Ọgbẹni Rasheed, ọkọ to fẹ Shakirat sile, pẹlu awọn ọmọ bibi inu ẹ ko mọ pe nnkan kan n dun un lọkan debi to le mu un pinnu lati gbẹmi ara ẹ debi ti awọn araadugbo yoo mọ.

Ni nnkan bii aago kan ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii lọkọ ẹ pẹlu awọn ọmọ wọn deedee kan oku ẹ to n rọ dirodiro labẹ faanu to so ara ẹ kọ́ sí loke aja ni yara ninu ile.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, obinrin yii ko ba eeyan ja, bẹẹ ni ko jẹ gbese debi to fi yẹ ki ile aye su u. Ọrẹ ẹ kan lo ya owo sogún-dogójì lọdọ ileefowopamọ olowo-ele kan ti wọn n pe ni LAPO. Oun lo si ṣe oniduuro fun un. Adehun ti wọn si jọ ṣe ni pe ki ẹni to yáwó maa da a pada diẹ diẹ lọsọọsẹ. Ṣugbọn lọsẹ ti ko ba ti rowo san, dandan ni ki ọrẹ ẹ to ṣe oniduuro fun un ba a san an.

Obinrin onigbese yii ko sanwo debikan to fi sa lọ nigba ti ko rowo lati fi san gbese ọhun mọ. N lawọn ayanilowo ele ọhun, ti ọfiisi wọn wa ni Awọtan, n’Ibadan, ba n pe ẹni to ṣe oniduuro fun onigbese wọn, bẹẹ ni Shakirat bẹrẹ si i san gbese ti ọrẹ ẹ jẹ lọsọọsẹ.

Kinni ọhun ti ka Shakirat paapaa láyà, ko lowo ti yoo fi san gbese ọrẹ ẹ lọwọ mọ. Nigba ti awọn olowo-ele reti ẹ lọjọ Jimọh to yẹ ko sanwo ti wọn ko ri i, wọn pe e lori foonu. Eyi lo si mu ki obinrin ẹni ọdun mọkanlelogoji (41) yii gbẹmi ara ẹ, o gba pe iku nikan lọna abayọ nitori ẹ̀sín ti awọn olowo-ele yii yoo fi oun ṣe ko ni i mọ ni kekere gẹgẹ bi wọn ṣe maa n ṣe fawọn onigbese wọn.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, nigba ti ọkọ Shakirat beere ẹ lọwọ ọmọkunrin wọn ti iyẹn sọ pe oun ko mọ ibi ti iya oun wa, wọn bẹrẹ si i wa a kiri ninu ile. Si iyalẹnu wọn, ẹnu okun labẹ faanu ninu yara kan ninu ile ọhun ni wọn ti ba a, o ti pokunso, o si ti ku.

Awọn ti ọkọ Shakirat ba sọrọ sọ pe laaarọ ọjọ Jimọh niyawo oun too ṣalaye foun nipa ọrọ oniduuro to ṣe fun ọrẹ ẹ to jẹ gbese. Ṣugbọn nigba ti oun maa fi dele ni nnkan bii aago kan ọsan ọjọ naa, oun ko ri iyawo oun. Nibi ti awọn si ti n wa a lawọn ti ri oku ẹ nibi to pokunso si.

Ọga ọlọpaa teṣan Apẹtẹ ti ko awọn ọlọpaa lẹyin lọ sile awọn Shakirat lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. Awọn ẹlẹsin ibilẹ ni wọn si sọ oku naa kalẹ ki wọn too sin in.

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.