Sẹki fẹẹ fẹkun ṣera ẹ leṣe si mi lọrun

Spread the love

Ọlọrun lo ma yọ mi o. Eṣu ma ti pofo laye mi o. Ọlọrun o kuku ni i jẹ ki n raburu, aye o si ni i ṣe ko tan ndi mi. Sẹki ni o, Sẹki yin kan naa ni o, Sẹki fẹẹ ko ba mi. Diẹ lo ma ku, Ọlọrun lo ba mi ṣe e. Ohun ti ko ṣe daa keeyan maa fi ọmọ ẹ silẹ nile ọkọ pupọ ju naa niyẹn, iyẹn ọmọ obinrin o. Ki i ṣe keeyan lọọ jokoo sibẹ ko maa fẹju mọhun ti wọn n ṣe o, amọ ko maa debẹ lẹẹkọọkan, o kere tan, ko debẹ lẹẹmeji lọsẹ, iru awọn ti ile wọn ba si sun mọra, ko sigba teeyan o le yọju, ko lo iṣẹju marun-un ko maa ba tiẹ lọ, mo kan ni ki n ya wo yin ni o, ko ju bẹẹ lọ.

Ohun ti Ọlọrun fi yọ mi niyẹn. Mo pẹ ki n too kuro nile nijọ Alamiisi yẹn, n o kuku tiẹ mọ ohun to fa a, boya ara lo si n sọrọ fun mi. Igba ti mo jade ti mo n lọ, mo tiẹ ti kọkọ fẹẹ wọ mọto nita, ni mo ba ni ki Lati jẹ ki n kọkọ yọju sọmọ mi na, ni mo ba gba ile awọn Sẹki lọ. Mo ṣa deta mi o ri i, mo yọju si ọrẹ mi, mo ni ki n kan wo o ni o ki dẹ maa lọ si ṣọọbu, o digba ti mo ba n bọ, tabi lọla ka too le sọrọ daadaa. Wọn ni ko si ọkọ wọn naa nile, ṣugbọn o ni Sẹki wa nile nitori ko ti i dagbere foun pe oun n lọ sibi kan, o kan waa ki oun laaarọ ni, o wa ni yara ẹ.

Ibi ti ara ti kọkọ fu mi niyẹn, Sẹki wa nile kẹ. Ọmọ mi ki i ṣe iru iyẹn, ko ma ti i jade ni aago mọkanla, nnkan kan n ṣẹlẹ ni. Koda, nigba to bimọ yii naa, yoo ti lọọ jokoo si ṣọọbu. Ni mo ba wọle, mo ri kinni naa to rọjọ sori ṣia, o ti wule, bẹẹ o ti sunkun sunkun tẹlẹ naa, gbogbo oju lo ti wu. Haa, ki lo ṣẹlẹ! Bo ṣe lanu pe koun ki mi bayii, niṣe lo tun bu sigbe, afi gbamuu. “Iyaa mi, temi bajẹ! Temi ti bajẹ ooo!” Aya mi ti ja, n ko mọ ohun ti o n ṣe e. Amọ mo mọ pe iru ọrọ to n pa a nigbe bẹẹ ko ni i ṣe e sọ nile wọn, ohun ti mo si kọkọ ṣe naa ni pe mo ni ko dakẹ.

Mo mu aṣọ, mo fi nu un loju, mo ni o ya, ko jẹ ka lọ, ko gbe ọmọ ẹ, mo maa sọ fun Iyaale ẹ pe mo kan fẹẹ fi nnkan han an ni, ko ni i pẹẹ pada. Ko niṣo nile wa. Ni mo ba rora n fọgbọn mu un jade, mo ni ko kan igo dudu to maa n lo yẹn mọ oju, ki awọn eeyan ma le ri oju ẹ, ki wọn ma le mọ pe o n sunkun ni. Bo ṣe kango mọju bii awọn ọmọ alakada niyẹn, ni mo ba fọgbọn mu un pada sile, ba a ṣe goke tan bayii to tun wọ inu yara, ọmọ mi tun bu sigbe ni. Ni mo ba fọwọ ko o mọra, “Abẹjẹ, ki lo de, ṣo o fẹ kemi naa maa sunkun ni!”

Nigba to ri i pe omi ti n le roro soju emi naa lo ba sinmi. O bẹrẹ si i nuju, o ni “Iya mi, ẹ ma sunkun o, ẹ ma sunkun o!” Lemi naa ba sọ fun un pe bawo ni n ko ṣe ni i sunkun, nigba to n ke ti ko sọ ohun to ṣẹlẹ fun mi. Lo ba ni,  “N oo ṣalaye fun yin, ẹ ṣa ma sunkun!” Bo ṣe fẹẹ bẹrẹ ọrọ naa lo tun n leri ẹkun, igba to ri i pe oju temi naa ti pọn lo ṣa sinmi, lo waa ni, “Dele ni, Dele lo fẹẹ pa mi!” Mo ni. “Ọkọ ẹ, abi ta ni? Ki lo de, ki lẹ jọ fa pọ, ki lo ṣe fun un? Haa, ọmọ ọkunrin jẹẹjẹ yẹn, Sẹki, o si ti tun ṣe nnkan kan fọmọ ọkunrin yii!”

Sẹki, ọmọ nla kan bayii ni! Pẹlu bo ṣe n sunkun to yẹn, niṣe lo bu sẹrin-in! “Ẹ wo o, Iya mi, ẹ jẹ ki n gbọran o! Ẹ ẹ si maa sọ nnkan tẹ ẹ mọ! Dele leeyan jẹẹjẹ, eeyan jẹẹjẹ naa ni, boya ẹyin lẹ n ba a gbele! Emi leeyan buruku, abi! Ẹ maa bu mi!” Ni mo ba tun fa a mọra, o ti tun fẹẹ maa ke. Mo ni ki i ṣe bẹẹ, bi emi ṣe n ri ọkọ ẹ yẹn ko jọ oniwahala, iru ọkọ to daa keeyan maa fi bẹ Ọlọrun ni. O ni o daa ki emi gbọ ohun to ṣe na, ti mo ba gbọ to ba jẹ oun loun jẹbi, nigba naa ni ki n too maa sọrọ bẹẹ. Ni mo ba ni ko ṣaa wo o!

O ni o daa kemi gbọ ohun to ṣe. Lo ba tẹnu bọrọ. Ẹ wo o, awọn ọkunrin wa yii ko ṣee jẹrii, ọgbọn leeyan yoo maa fi ba wọn ṣe. Sẹki ni niwọnba igba ti oun fi loyun ti oun n tọmọ yii, Akinfẹnwa ti ni awọn ọrẹbinrin, o ni meji loun ri, ṣugbọn afaimọ ki wọn ma ju meji lọ. Niṣe ni mo tun ijokoo ṣe, n o le gba a gbọ, abi ki i ṣe Akinfẹnwa temi n ri yii ni! Mo ni ko yaa duro nibi to de yẹn o, ko ma jẹ ki awọn eeyan kan waa po ẹkọ ibanujẹ foun, ko ma jẹ ki awọn ti inu wọn ko dun pe oun ri ijokoo ayọ waa sọrọ ti ki i ṣe toun foun o. Lo ba tun rẹrin-in musẹ.

O loun mọ pe emi o ni i gba loun o ṣe fẹẹ waa sọ fun mi. Mo ni ṣe funra ẹ lo ka wọn mọ ni. O loun o ka wọn mọ, o ni foonu ẹ loun ji wo nigba to n sun. Mo ni haa, o ni beeyan o ba maa ṣe bẹẹ fawọn ọkunrin, wọn yoo kan maa gbe nnkan gbẹyin eeyan kọja ni. O ni foonu ẹ loun ji wo, nibẹ loun ti ri awọn atẹjiṣẹ ti oun ati ọrẹbinrin ẹ kan n ko sira wọn, ti iyẹn n royin pe oun gbadun kinni to ṣe foun, oun ti gbadun ẹ ju. O loun to ya oun lẹnu ni pe ọmọbinrn yẹn moun, nitori o kọ ọ sibẹ pe ki Dele kilọ foun, pe boun Sẹki o ba ṣọra, oun aa gba Dele lọwọ ẹ.

Eyi ti mo dẹ tun ri le ju. Sẹki yọ foonu ẹ jade, lo ba ṣi i, o lọmọ tọkọ oun n gbe kiri niyẹn o. Ni mo ba n wo fọtọ, ọmọ yii ṣi ọmu silẹ, lọmu ẹ ri lekete lekete, lo n dan pala, boya kiriimu lo fi pa a mi o mọ, ṣugbọn mo mọ pe ko sọkunrin to maa ri i ti ko ni i fẹẹ ba a ṣe. Ki i ṣe fọto kan lo fi ranṣẹ, o to mẹjọ, o ya eyi to ti gbe idi sita, to ran idi sẹyin bayii. Sẹki ni nnkan to kọ sibẹ ni pe “Dele, maa bọ, waa ki doro ẹ sinu kanga mi!” Mo ni, “Haa, awọn ọmọ yii si ba ile aye jẹ bayii!” Sẹki ni oun n reti ẹ ko de ni, awọn maa pa ara awọn sinu ile yẹn ni.

Ni mo ba dakẹ, mi o sọrọ. Nigba to ya ni Sẹki ba ni mi o wi nnkan kan ni. Mo ni ohun ti Dele ṣe ya mi lẹnu, ṣugbọn ki i ṣe bo ṣe fẹẹ mu un yẹn ni yoo mu un. Mo ni ti ọkọ ẹ ba de, oun gan-an ni yoo bẹ ẹ! Lo ba pariwo, “Iya mi! Ọlọrun ma jẹ! Bawo loun ṣe maa bẹ ẹ!” Ni mo ba tun sinmi, nigba to tun ya, ti inu ẹ ti tun rọ, lo ba tun ni, “Iya mi, ki lo n ṣe yin bayii, ẹ ẹ si sọrọ!” Mo ni ọrọ ti mo fẹẹ sọ naa ni mo ti sọ yẹn, yoo bẹ ọkọ ẹ ni, ṣugbọn ki i ṣe ẹbẹ bẹẹ. Yoo sọ pe oun ri gbogbo awọn fọto ti wọn fi n ranṣẹ si i, ati ọrọ ti wọn n sọ ranṣẹ si i, ṣugbọn oun fẹẹ bẹ ẹ ni.

Oun fẹẹ bẹ ẹ ko ma ṣe iru ẹ, nitori eeyan pataki ni, gbogbo eeyan lo si n foju apọnle wo o, bo ba n ṣe bẹẹ bi aṣiri iru iwa bẹẹ ba tu sita nkọ, nibo lo fẹẹ gba, itiju ni yoo jẹ fun un. Mo ni, “Idi to o fi ṣe bẹẹ ni pe ko sohun tọkunrin n ṣe fun’yawo ẹ ti ọkọ ẹ o ṣe fun ẹ. Ọmọ kan ṣoṣo lo ṣi bi, o ra mọto fun ẹ, o fun ẹ nikan ninu ile ẹ, o ti ṣi ṣọọbu nla fun ẹ, ki lo tun ku ti ko ṣe. Eeyan ki i ba iru ọkunrin bẹẹ ja, ẹbẹ lo o bẹ ẹ, ti o oo si fi gbogbo ohun to ba fẹ tẹ ẹ lọrun, ati ounjẹ ati ara ẹ, ti o oo fi le yiju ẹ kuro nita. Ọwọ ẹ ni iṣẹ to pọ wa, gbogbo ọkunrin lo n ṣe bẹẹ!”

Ni Sẹki ba n rẹrin-in, lo ba so mọ mi,  “Iyaa mi, n o ṣe bẹẹ!” Nigba yẹn lọkan mi ṣẹṣẹ balẹ.

 

 

(59)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.