Sẹkẹtiri ẹgbẹ Afẹnifere, Yinka Odumakin, fẹsun kan ijọba apapọ pe wọn n fi ogun akowojẹ ti wọn n ja fi ṣe oṣelu ni

Spread the love

Nitori itakurọsọ ti PDP ati awọn ijọba apapọ ni sira wọn lo jẹ ki ijọba apapọ latara Minisita fun iroyin ati aṣa, Alaaji Lai Muhammed, gbe orukọ awọn ti wọn ti kowojẹ ninu ẹgbẹ PDP jade. Orukọ eeyan mẹfa ni wọn da sinu iwe ọhun: Uche Secondus to jẹ ṣiamaanu ẹgbẹ naa, Sẹkẹtiri eto iṣuna owo Naijiria tẹlẹri to wa lati PDP, Olisah Metuh, Raymond Dokpesi, Dudafa Waripamo-Owei ati Robert Azibaola to jẹ malẹbi aarẹ tẹlẹri Goodluck Jonathan. Sẹkẹtiri ẹgbẹ Afẹnifere, Yinka Odumakin, fẹsun kan ijọba apapọ pe wọn n fi ogun akowojẹ ti wọn n ja fi ṣe oṣelu ni, o ṣe jẹ orukọ iwọnba awọn mẹfa yii ni wọn ri darukọ latọjọ ti wọn ti lawọn n ja ija ilu. Gbogbo awọn ti wọn si darukọ yii, ọmọ PDP ni gbogbo wọn, ko si awọn PDP to wọ inu APC nibẹ. Eyi fihan pe ija oṣelu lasan ni, o daa fun APC lati maa ja iru ija ṣukẹṣukẹ bayii amọ ko yẹ ka ba ijọba apapọ nibẹ rara o.

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.