Sẹnetọ ati Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹsẹ bo ṣokoto kan naa

Spread the love

 

O maa n ṣoro lati lo ohun ija oloro to lagbara nigba ti ọta ẹni ba sun mọ ni ju loju ogun. Bi awọn agbo meji paapaa ba sun mọ ara wọn ju loju ija, awọn mejeeji aa tadi mẹyin lọọ mu akọtun agbara wa ki wọn le ribi kan ara wọn karakara ni. Iyẹn lawọn agba ṣe maa n powe pe agbo to tadi mẹyin, agbara lo lọọ mu wa. Bi ọrọ ṣe ri gan-an ree laarin Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo Gusu ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣofin apapọ orileede yii, Sẹnitọ Rilwan Adesọji Akanbi, ati gomina ipinlẹ naa.

Akanbi lo lo ete ija agbo-to-tadi-mẹyin, nigba to fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lati le ribi to lagbara gidigidi kan gomina ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi nikankukan ninu idibo ọdun 2019.

Ta o ba gbagbe, ọjọ kan naa, iyẹn ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkandinlogun (19), oṣu karun-un, ọdun 2018 yii, ni wọn ṣeto idibo yan awọn to n tukọ iṣakoso ẹgbẹ oṣelu APC kaakiri awọn ipinlẹ gbogbo lorileede yii, eyi to mu ki ẹgbẹ  naa pin si meji meji ni ọpọlọpọ awọn ipinlẹ ti ọkẹ aimọye sẹnetọ atawọn ọmọ ileegbimọ aṣofin keji nilẹ yii si tori ẹ fi ẹgbẹ oṣelu wọn silẹ ba ẹgbẹ oṣelu alatako to wu kaluku wọn lọ.

Nigba ti iroyin igbesẹ ti awọn aṣofin apapọ APC gbe yii kọkọ lu jade, Sẹnetọ Akanbi naa wa lara awọn ta a gbọ pe o gbe igbesẹ ọhun, ṣugbọn lọgan lọkunrin naa pariwo, o ni oun ko fi ẹgbẹ APC silẹ ni toun.

Akanbi fẹẹ dupo to wa yii fun saa keji, ṣugbọn ipenija kan ṣoṣo to n koju ẹ ko kọja gomina ipinlẹ rẹ.  Sẹnetọ Ajimọbi yoo pari saa keji rẹ nipo gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọyọ, oun naa fẹẹ dupo yii ni ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Ọyọ kan naa ti Sọji Akanbi ti wa.

Bo tilẹ jẹ pe Ajimọbi funra rẹ ti ṣẹnu foro sọ ọ ri pe o ṣee ṣe ki oun dupo sẹnetọ lọjọ iwaju, Ajimọbi ko sọ nnkan kan nipa ipinnu ẹ mọ titi dasiko ti awọn aṣofin APC kan binu kuro ninu ẹgbẹ lẹyin idibo wọn yii. Ohun to fi Akanbi lọkan balẹ gan-an ree, o mọ pe yoo rọrun foun lati ri tikẹẹti ẹgbẹ APC gba bo ba jẹ pe ẹlomin-in lo ba oun fori gbari fun tikẹẹti ipo sẹnetọ.

Tohun ti bi Ajimọbi ko ṣe ti i lẹ posita kankan pe oun fẹẹ dupo, o n ṣiṣẹ labẹnu lati ri i pe oun ni tikẹẹti ọhun ja mọ lọwọ ninu ẹgbẹ APC. Bi aṣiri igbesẹ yii si ti lu si Sẹnetọ Akanbi lọwọ lo ti fi ẹgbẹ APC silẹ, to si ba ADC lọ. O mọ pe oun ko le ba Ajimọbi fori gbari fun nnkan kan ninu ẹgbẹ APC lasiko yii ki oun jẹ

Lọjọ keji ti Akanbi di ọmọ ẹgbẹ ADC ni Ajimọbi kede ni gbangba pe oun fẹẹ dupo sẹnetọ. Akanbi wọnu ADC l’Ọjọbọ, (Tọsidee), to kọja, Ajimọbi kede lọjọ Jimọ to tẹle e.

Ṣaaju idibo to gbe e wọle si ipo gomina ipinlẹ Ọyọ lọdun 2011, eyi ti saa keji rẹ yoo pari lọdun 2019, Ajimọbi ti figba kan ṣe sẹnetọ laarin ọdun 2003 si 2007. Pẹlu ipo gomina to si wa yii, yoo ṣoro ki ẹnikan too le ba a fori gbari fun tikẹẹti lati dupo lorukọ ẹgbẹ oṣelu ẹ, nitori ọwọ ẹ ni ida iṣakoso ẹgbẹ oṣelu ẹ wa ni ipinlẹ rẹ. Idi ree ti Akanbi fi kuro ninu ẹgbẹ APC, ki ilẹkun ikẹ ẹgbẹ yii too ti mọ ọn patapata, debi ti ko ti ni i si lara awọn ti yoo dije dupo sẹnetọ ninu idibo gbogbogboo ọdun to n bọ.

Ọjọruu, Tọsidee, ọjọ kẹta, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ni eto idibo abẹle yoo waye ninu ẹgbẹ APC, nibi ti awọn ipinlẹ gbogbo nilẹ yii yoo ti dibo yan ẹni ti ẹgbẹ yoo fa kalẹ lati du ọkan-o-jọkan ipo ninu eto idibo ọdun 2019.

 

(34)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.