Saraki ti ha o Njẹ ko ni i ṣẹwọn bayii

Spread the love

Loootọ awọn ọlọpaa ko ti i sọ pe Saraki jẹbi, bẹẹ ni wọn ko ti i gbe e lọ sile-ẹjọ, ṣugbọn gbogbo ohun to wa loju ọpọn ifa ọrọ yii, bi awọn babalawo ti wọn mọ nipa ofin ilẹ yii ba wo o daadaa, olori ile-igbimọ aṣofin agba, Olubukọla Saraki, ti ha, yiyọ Ọlọrun nikan lo ku. Ibi to tilẹ waa ha si yii ko daa, ọwọ awọn ọta rẹ lo ha si, ọwọ awọn ọmọ Buhari. Ọrọ rẹ ko si yatọ si tẹni ti wọn ti fẹẹ sun jẹ tẹlẹ, to waa lọọ fi epo para, wọn yoo kan ti i lu ina gbẹyin ni. Ọrọ pupọ lo ṣee dọgbọn si, agaga bo ba jẹ ọrọ oṣelu, bi wọn si lọ si kootu nigba igba, iyẹn ko ti i ṣe kinni kan. Ṣugbọn ọrọ to maa n ṣoro lati yipada ni ọrọ iwa ọdaran to ba ti la ti ẹmi lọ. Awọn ọlọpaa ti kede bayii pe awọn ọdaran ti awọn ti ri mu ninu awọn ti wọn jale ti wọn yinbọn paayan rẹpẹtẹ l’Ọffa ti jẹwọ, wọn ni Saraki ati Gomina Abdul Fattah Ahmed ni baba isalẹ awọn.

Ko sẹni ti ko barajẹ lorilẹ-ede yii ati kaakiri ibi ti wọn ti gbọ iroyin naa lọjọ karun-un, oṣu kẹrin, ọdun yii, nigba ti awọn adigunjale wọ ilu Ọffa ni ọsan gangan, ti wọn n wọ banki kiri, ti wọn n pa awọn eeyan, ti wọn si n ji owo ko, ti wọn si ṣe bẹẹ yinbọn paayan mẹtalelọgbọn, ti ko si sẹni to ri wọn mu. Ọrọ naa ba awọn ọlọpaa paapaa lojiji, to si di ohun ti awọn alaṣẹ orilẹ-ede yii n pariwo pe afi ki awọn ọlọpaa wa awọn ti wọn ṣe ijamba naa ri. Koda, gbogbo aye lo n lọọ ba Ọba Muftau Gbadamọsi Eṣuwoye II, Ọlọfa ti ilu Ọffa daro, lati ori Saraki, to fi dori awọn minisita bii Lai Muhammed ati awọn ti Aarẹ Muhammadu Buhari tun ran lọ. Gbogbo eyi lo jẹ ki inu awọn eeyan dun, nigba ti awọn ọlọpaa bẹrẹ si i ṣa awọn ti wọn ni wọn jale naa, ti wọn si ni wọn ti n ri wọn mu nikọọkan. Bi wọn ti n mu wọn, Abuja ni wọn n gbe wọn lọ taara.

Ko si sẹni to mọ ibi ti wọn ba iwadii wọn de, afi lọjọ Satide to kọja yii ti awọn ọlọpaa ranṣẹ pe Olori ile-igbimọ aṣofin, Saraki, pe ko maa bọ lọdọ awọn, ọrọ kan an, nitori marun-un ninu awọn ọga awọn adigunjale yii ni wọn ti darukọ rẹ, ti wọn sọ pe oun ni baba awọn nidii iṣẹ ti awọn n ṣe. Ọrọ naa ṣoro lati gbagbọ fun ọpọ awọn eeyan, nitori ija ti wa laarin Ọga awọn ọlọpaa pata, Ọgbẹni Ibrahim Idris, ati Saraki tẹlẹ. Awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin ti ranṣẹ pe ọkunrin naa ti ko lọọ jẹ wọn, ọrọ si di ohun ti awọn aṣofin tori rẹ binu gan-an. Igba kan tilẹ wa ti Saraki kede pe ọga ọlọpaa naa fẹẹ ti ọran mọ oun lọrun, o ni wọn mu awọn ọdaran kan ni Ilọrin, wọn si ti pari iwadii lori wọn, afi bi ọga ọlọpaa yii ṣe ni ki wọn tun maa ko wọn bọ ni Abuja, o ni wọn fẹẹ fi koba oun ni. Ṣugbọn ẹjọ iyẹn kọ ni eyi ti wọn n ṣe yii o.

Gbogbo iyẹn lo kọkọ jẹ ki awọn eeyan ro pe wọn fẹẹ ti kinni naa mọ Saraki lọrun ni loootọ, ṣugbọn nigba ti awọn ọlọpaa waa ko ẹjọ balẹ ti wọn ro o, ọrọ naa ko ye awọn eeyan mọ, wọn ko mọ ohun ti wọn yoo sọ. Ọga ọlọpaa to n ri si ikede fun wọn, Ọgbẹni Jimoh Moshood, lo rojọ naa faye, eyi ni bo ṣe to o:

“A ti ba iwadii ti Ọga olọpaa pata, Ọgbẹni Ibrahim Idris, ni ka ṣe lori ọrọ awọn ti wọn digunjale ni ilu Ọffa, ti wọn paayan mẹtalelọgbọn lọjọ karun-un, oṣu kẹrin, ọdun yii, de ibi to ni apẹẹrẹ o. A ti ri awọn ọga awọn adigunjale naa ko pẹlu awọn ti wọn kopa pataki ninu iṣẹlẹ naa, gbogbo wọn si ti jẹwọ pe loootọ lawọn wa nibẹ, awọn gan-an lawọn ṣe e. Awọn ọga adigunjale naa ni Ayọade Akinnibosun, Ibikunle Ogunlẹyẹ, Adeọla Abraham, Salawudeen Azeez ati Niyi Ogundiran pẹlu awọn mẹtadinlogun mi-in ti wọn kopa pataki ninu idigunjale ti wọn tori ẹ pa eeyan rẹpẹtẹ bẹẹ ati awọn alaboyun pẹlu awọn ọlọpaa mẹsan-an to sọ pe tọọgi oloṣelu lawọn, Oloye Bukọla Saraki ati Gomina Abdul **Fataih lawọn si n ṣe tọọgi awọn fun. Awọn meji ti a kọkọ mu, Kunle Ogunlẹyẹ ti wọn n pe ni Arrow, ati Micheal Adikwu, to ti ṣẹwọn ri lo jẹ ka ri awọn adigunjale to ku yii mu o.

“Awọn meji yii ti a ri fọto wọn lati ọkan ninu awọn banki ti wọn ti jale ti wọn si paayan yii, ti a si tẹ fọto wọn jade ninu awọn iwe iroyin, ni wọn sọ bi a ṣe le ri awọn to ku mu, ti wọn si sọ pe awọn marun-un yẹn lọga awọn. Nigba ti iwadii bẹrẹ, awọn maraarun-un yii ni wọn jẹwọ pe awọn kopa ninu idigunjale Ọffa yii, nibi ti awọn ti kọlu banki First Bank, Guarantee Trust Bank, Eco Bank, Zenith Bank, Union Bank ati Ibolo Micro Finance Bank ti gbogbo wọn wa ni Ọffa, pẹlu olu-ileeṣẹ awọn ọlọpaa l’Ọffa lọjọ karun-un, oṣu kẹrin, ọdun 2018. Awọn maraarun yii ni wọn gba pe miliọnu rẹpẹtẹ Naira lawọn ko kuro lawọn banki yii, ti awọn si ko ibọn mọkanlelogun to jẹ tawọn ọlọpaa Ọffa nigba ti wọn kọlu teṣan wọn. Gbgobo wọn ni wọn ṣalaye fọlọpaa, ti wọn si sọ bi awọn ṣe gbimọ lori idigunjale naa, ati igbesẹ wọn lọkọọkan.

“Awọn ọga awọn ole maraarun yii ni wọn jẹwọ pe tọọgi oloṣelu lawọn, orukọ ẹgbẹ awọn si ni Youth Liberation Movement ti wọn n pe ni “Good Boys”, ati pe Olori ile-igbimọ, Bukọla Saraki ati Gomina Abdul***Fattah Ahmed, ni baba isalẹ awọn, awọn ni wọn fun awọn ni mọto, ibọn ati owo ti wọn n lo lati fi ṣiṣẹ gbogbo. Nibi ti awọn ọlọpaa ti n ṣe iwadii wọn lọ ni wọn ti ri i pe mọto jiipu ti ọga awọn adigunjale yii, Ayọade Akinnibosun, lo, wọn ti fọgbọn da mọto naa pada sile-ijọba lọjọ kẹrinlelogun, oṣu karun-un, to kọja. Nọmba to wa lara mọto naa tẹlẹ ni “SARAKI: Kwara, State of Harmony.” Bi wọn ti gbe mọto naa dele-ijọba ni wọn sare yọ nọmba ara ẹ danu, wọn waa fi nọmba mi-in si i to jẹ ti Kwara, iyẹn KMA 143 RM. Orukọ ọga awọn ole naa, Ayọade Akinnibosun, ni wọn fi rẹjisita nọmba tuntun yii, ka le ro pe tiẹ ni.

“Ni ileeṣẹ Minisry of Enviroment la ti waa pada ri mọto jiipu yii o, bẹẹ la pada ri pileeti ti wọn kọ SARAKI si yii lọdọ Adeọla Omiyale, ẹni to wa mọto naa lọ si ileeṣẹ yii lẹyin ti wọn fi digunjale tan. Alabi Ọlalekan to jẹ PA fun Gomina ipinlẹ Kwara ti mọ pe awọn ọlọpaa n wa mọto jiipu yii lo ṣe paṣẹ fun Adeọla pe ko gbe e lọ si ileejọba. Alabi Olalekan yii ti wa lọdọ awa ọlọpaa, nitori lẹyin ti a mu un ti a tun lọọ saaji ọkọ rẹ wo, ibọn nla nla meji la ba ninu ọkọ naa, nitori nibẹ lo sọ pe ki aburo oun sare lọọ ko o sa pamọ si, nigba to ti mọ pe a n bọ wa sile oun. Nitori pe ki wọn le fi ẹri idi ọrọ yii pamọ, olori awọn oṣiṣẹ Gomina Kwara, Alaaji Yusuf Abdulwahab, lo yọ orukọ ati pileeti ti wọn lẹ mọ ara mọto jiipu ti awọn adigunjale naa lo, iyẹn Lexus Jeep ti Ayọade Akinnibosun n gun kaakiri yii.

“Oun lo yọ gbogbo orukọ SARAKI ati Kwara, State of Harmony pẹlu sitika ti wọn lẹ mọ ọn kuro. Alaaji Yusuf Abdulwahab yii naa lo si yọ pileeti-nọmba ati nọmba mọto naa danu. Oun gangan lo lọọ ṣe rẹjisita tuntun fun mọto yii lorukọ Ayọade Akinnibosun, olori awọn adigunjale yii. Bẹẹ, ko too di pe o lọọ ṣe rẹjisita tuntun to fi Ayọade Akinnibosun ṣe yii, awa ọlọpaa ti mu Akinnibosun si ọdọ wa, o ti le ni ọjọ mẹta ko too lọọ fi orukọ rẹ ṣe iwe mọto tuntun. A ti mu Alaaji Yusuf Abdulwahab yii, oun naa si ti wa lọdọ awa ọlọpaa, koda, o ti sọrọ to nitumọ, o si ti jẹwọ awọn ohun to mọ nipa ọrọ yii gan-an. Bi a ti n wi yii, iwadii ṣi n tẹ siwaju o, gbogbo awọn ti ọrọ kan la n wa kaakiri, a oo si mu gbogbo wọn laipẹ rara. Bi a ba ti pari iwadii wa la n ko wọn lọ sile-ẹjọ, ti wọn yoo le lọọ ro ẹjọ ẹnu wọn.

“Ṣugbọn ko too di igba naa, a n fi akoko yii pe Olori ile-igbimọ aṣofin agba, Bukọla Saraki, lati waa fi ara han niwaju awọn ọlọpaa Force Intelligence Response Team ti ọfiisi wọn wa ni Guzape, Abuja. Ohun ti a ṣe pe e ni ki oun naa le waa dahun ẹsun ti awọn ọga awọn adigunjale maraarun ti a ti mu, ti wọn si ti jẹwọ ẹṣẹ wọn yii fi kan an. Awọn ọga awọn adigunjale maraarun ti wọn fẹsun kan an yii ni Ayọade Akinnibosun, Ibikunle Ogunlẹyẹ, Adeọla Abraham, Salawudeen Azeez ati Niyi Ogundiran. Ninu awọn ọdaran mẹtadinlogun ti a tun mu pẹlu wọn naa darukọ ẹ o, wọn si fẹsun kan olori ile-igbimọ aṣofin naa. Iyẹn la ṣe ni ko waa sọ ohun to ba mọ nipa ọrọ naa. Awọn ọdaran mejilelogun lo wa lọwọ wa bayii o, a ko si ni i sinmi titi ti a oo fi ri awọn to ku mu, ti a oo si yanju ọrọ naa pata.”

Ṣugbọn awọn eeyan ti ni ọrọ naa ko ri bẹẹ rara, o jọ pe ijọba Buhari ti mura lati fi Saraki wọlẹ, ki wọn si fi han an pe awọn lagbara gidi lati fiya jẹ ẹ ni. Akọkọ ni pe loootọ lawọn adigunjale ti wọn mu naa sọ pe awọn wa ninu ẹgbẹ awọn ọdọ kan ti awọn n ṣiṣẹ fun Saraki, ati pe tọọgi rẹ lawọn, wọn ko sọ pe oun lo ran awọn ni oko ole, koda, wọn ni ko mọ pe awọn tun fi ole jija kun ohun ti awọn n ṣe. Ohun to tilẹ ṣẹlẹ ni gbara ti ọrọ naa ṣẹlẹ ti fi han pe ọrọ naa ni ọwọ ijọba ninu gan-an ni. Idi ni pe bi awọn ọlọpaa ti fi awọn adigunjale yii han, ileeṣẹ DSS ko duro rara ki wọn gbọ ohun to ṣẹlẹ, wọn ti ko awọn ẹṣọ ti wọn n ṣọ Saraki kuro lẹyin rẹ, wọn ko si sọ idi ti wọn fi sare ṣe iru nnkan bẹẹ, nigba ti ki i ṣe pe wọn ti i da a lẹbi pe ọga awọn adigunjale ni, ti ọrọ ti olori awọn adigunjale naa si sọ ko fi Saraki han bii olori ole.

Ayọade Akinnibosun ni olori wọn, nigba ti wọn si mu un jade si gbangba lọjọ Sannde yii, to bẹrẹ si i sọrọ, ọrọ to sọ da bii pe o yatọ si ohun ti awọn ọlọpaa fẹ ko sọ. Alaroye gbọ pe ohun ti awọn ọlọpaa fẹ ko sọ ni pe Saraki lo n ran awọn ni iṣẹ gbogbo ti awọn n ṣe, ṣugbọn ọmọkunrin ole naa ko sọ bẹẹ, ohun to n tẹnu mọ ni pe Saraki lawọn n ṣiṣẹ fun, ko si mọ pe awọn n fi ibọn ati awọn ohun ti wọn ko fun awọn jale kaakiri ni. Koda, ibọn ti wọn ba lọwọ wọn, ọmọkunrin naa sọ pe Micheal Adikwu lo mọ bi awọn ṣe ri ibọn naa, iyẹn ni pe ki i ṣe ibọn ti Saraki ko fun wọn rara, bẹẹ ni ko si ẹri pe Saraki ko ibọn kankan fun wọn. Eyi ni ohun ti Ayọade Akinnimosun sọ gan-an niwaju gbogbo oniroyin aye:

“Emi ni alaga ẹgbẹ Youth Liberation Movement ni Kwara South, ọmọ olori ile-igbimọ aṣofin agba ni wa, oun la n ṣiṣẹ fun. Awa la di agbegbe Kwara South mu fun un, loootọ adugbo nla mẹta la ni ni Kwara, Kwara North ati Kwara Central, ẹkẹta ni Kwara South, ẹkẹta yẹn lawa di mu ni tiwa. Lati igba to ti n ṣe gomina to wa ninu PDP la ti n ṣiṣẹ fun un. Awa la maa n ba a wa awọn ero nibẹ, awa la dẹ maa n ba a ṣeto oṣelu ẹ ni gbogbo agbegbe yẹn. Bii apẹẹrẹ, ni awọn ibi ti a ba ti mọ pe a ko le wọle, awa la maa ṣeto dabaru nibẹ ta a fi maa wọle. Gbogbo nnkan lo maa n fun wa o. Jiipu ti ẹ n wo yẹn, Chief Of Staff lo ni Gomina AbdulFattah Ahmed ni ki wọn gbe e fun mi lati ọdọ Sẹnetọ Bukọla Saraki. Nigba ti a dẹ n lọọ jale ni Ọffa yẹn, mo gbe e dani lọ sibẹ.

“Ki i ṣe pe wọn ni ka lọọ jale o, ṣugbọn nitori pe awa ni tọọgi oṣelu wọn, iyẹn lo ki wa laya ti a fi lọọ ṣe rọbiri ti a ṣe. Ọkan ninu wa, Micheal Adikwu lo mọ bo ṣe ri gbogbo ibọn ti a lo nibẹ, oun lo ko wọn wa. Lọjọ yẹn, awa marun-un naa la pade: Arrow, Alex, Stand Well Well ati Niyi. Ajaṣẹ-Ipo la ti gbera, mọto mẹsidiisi kan la gbe de Ọffa yẹn. Igba ti a de Ọffa la ba Michael, oun gbe mọto Audi kan wa, oun lo ko gbogbo ibọn AK maraarun ti a lo fun wa. Oloye Saraki ati gomina ko ni ka lọọ jale o, awọn kọ ni wọn ran wa lati lọọ digunjale o, ṣugbọn nitori pe tọọgi oṣelu wọn la n ṣe la ṣe laya lati ṣe bẹẹ. Bo ba jẹ tọọgi oṣelu la fẹẹ lọọ ṣe, Chief Of Staff lo maa fun wa ni ibọn ti a ba fẹẹ lọ, ṣugbọn ko mọ pe a fi n jale o. Iṣẹ eṣu ni mo ṣa le pe gbogbo ẹ. Wọn ki i fun wa lowo oṣu, ṣugbọn bi Oloye ba wa siluu, wọn le fun wa ni 200, 000 tabi 300,000 pe ka lọọ pin in.”   

Ọrọ ti olori awọn adigunjale naa sọ niyi, o si jọ pe o wẹ Saraki mọ pe ko ran awọn niṣẹ idigunjale, inu awọn ọlọpaa ko si dun si eyi rara, nitori Alaroye gbọ pe Ọga ọlọpaa pata, Idris, ti lọọ sọ fun Aarẹ Buhari tẹlẹ pe o le ni ogun eeyan ti awọn eeyan ti pa fun Saraki, iyẹn si ti sọ pe oun ko lodi si i, bi ẹri gidi ba ti wa lọwọ ẹ, ko lọọ mu Saraki to ba fẹẹ mu un. Eleyii ni wọn ṣe sare ko awọn SSS to n ṣọ ọ kuro, nitori wọn ti mura rẹ pe ti ko ba fi yọju sawọn bi awọn ti ṣe ni ko wa, awọn ọlọpaa yoo fi tipatipa mu un. Loju awọn eeyan, ọrọ naa jọ bii igba ti Ọga Ọlọpaa Idris ti pinnu lati fi han Saraki pe oun ju u lọ, oun si sun mọ Buhari daadaa debii pe ko si itu ti oun ko le fi olori ile-igbimọ aṣofin naa pa. Nigba ti wọn ti ko awọn ọdaran kan wa si Abuja lọjọsi ni Saraki ti pariwo sita, pe ọga ọlọpaa naa fẹẹ koba oun ni.

Awọn ọlọpaa taku nigba naa, wọn lawọn ko mọ kinni kan. Ohun ti ọga ọlọpaa n ṣe yii jọ pe o dun mọ Buhari ninu, nitori iroyin ti kun eti rẹ tẹlẹ pe Saraki yoo di i lọwọ lati du ipo aarẹ to fẹẹ du lọdun to n bọ, awọn kan si ti sọ fun un pe Saraki ko ni i pẹẹ ko awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin to ku lọ sinu ẹgbẹ oṣelu tuntun. Ibinu eyi wa fun Buhari, o si n wa ọna ti wọn yoo fi fi ajulọ han Saraki, nigba ti ọga ọlọpaa waa gbe eto nla ti wọn le fi fi oju Saraki gbolẹ dide, deede ara Buhari lo ṣe. Eleyii ki Idris, Ọga ọlọpaa laya, o si ni ko le pẹ tawọn yoo fi mu Saraki, nitori ẹri ti wa daadaa. Awọn ti wọn mọ nipa ofin ti Alaroye ba sọrọ sọ pe bo ba jẹ ọrọ tawọn adigunjale yii sọ ni wọn fẹẹ lo bii ẹri, ko sibi kan ti wọn ti sọ pe Saraki lo ran awọn niṣẹ; tọọgi ni wọn loootọ, ṣugbọn bi gbogbo awọn oloṣelu pata ṣe n lo tọọgi nilẹ yii niyẹn.

Saraki ti mura bayii lati ri awọn ọlọpaa, gbogbo aye si n reti ohun ti yoo tibẹ jade.

 

 

 

 

 

(132)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.