Saraki si tẹ nile, o tẹ loko

Spread the love

Ki Ọlọrun ma fi abuku kan wa, ki Ọlọrun ma si da yẹyẹ wa silẹ faye. Ohun ti awọn oloṣelu ki i mọ, to si maa n ko ba wọn ni pe wọn ko jẹ nnkan kan, wọn ko ja mọ nnkan kan, eeyan lasan bii ara yooku ni wọn, akoko igbega tiwọn kan de ti Ọlọrun gbe wọn ga ni. Ọlọrun to gbe wọn ga naa yoo tun gbe ẹlomiiran ga, bi awọn ba si ga ti wọn ko ba mọ iwa i hu nibẹ, iwa wọn naa ni yoo ja wọn kulẹ. Ọlọrun Ọba ki i jaayan kulẹ bo ba ti gbe ni ga tan, awọn eeyan ti Ọlọrun gbega lo maa n fi iwa ati iṣẹ wọn ja ara wọn bọ lori oke giga ti wọn ba gun, nigba ti wọn ba ti wo gbogbo ẹda aye to ku bintin, ti wọn n ṣe bii pe awọn gan-an l’Ọlọrun. Saraki lowo, baba rẹ naa si lowo, ṣugbọn ọna ti wọn ba lowo naa ni wahala wọn. Awọn eeyan ti wọn ko da ileeṣẹ kan silẹ pato, ti wọn ko ni iṣẹ gidi kan to foju han saye pe wọn n ṣe, to waa jẹ awọn ni wọn lowo ju, ti wọn yoo maa nawo bii ẹlẹda, bii pe wọn n rọ owo nile tiwọn. Iṣẹ wo ni Saraki n ṣe? Oṣelu ni Saraki n ṣe. Eeyan to ba si fẹẹ ṣe oṣelu to fẹẹ dolowo nidii ẹ yoo mu nnkan mi-in mọ ọn. Awọn ohun ti yoo mu mọ ọn naa ni ko maa ko tọọgi jọ, ko maa lo wọn lati paayan, ko maa lo wọn lati ji apoti ibo gbe, bi oṣelu ba si ti lọ tan, ki awọn ọmọ to ko jọ ti wọn ti ko ibọn fun maa jale kaakiri. Awọn ọmọ ti Saraki n ko jọ n jale, iyẹn naa ni wọn ṣe n pe oun naa ni adigunjale kaakiri bayii. Njẹ o daa ka gbọ pe odidi ọmọ Baba Oloye ni awọn kan yoo ko ara wọn jọ ni ilu Ilọrin yii kan naa, ti wọn yoo si maa jo, ti wọn yoo maa kọrin kiri pe adigunjale ni, alapata eeyan ni, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ṣugbọn iwa oun naa lo fa a, iwa buruku, iwa were ti awọn oloṣelu Naijiria n hu kiri ni. Wọn yoo maa ran awọn ọmọ tiwọn ni ilu oyinbo, Saraki lọọ ṣe ayẹyẹ ikẹkọọjade fọmọ tiẹ ni yunifasiti ilu oyinbo lọdun to kọja, ṣugbọn oun n ko ibọn ati ọta ibọn fun awọn ọmọ ọlọmọ ki wọn maa fi paayan, ki wọn maa fi ji apoti ibo gbe, nitori ki oun le wọle ibo, ko le maa ri owo ijọba Naijiria ati owo araalu ko. Nigba wo ni oun naa ki i ṣe adigunjale. Loootọ ọga ọlọpaa to n le e kiri ni tirẹ lara, ọtọ ni ohun to n dun oun. Ṣugbọn bi awọn ọmọ ti Saraki n ko ibọn fun ko ba fi jale, ti wọn ko si darukọ ẹ pe oun lo n ko ibọn fawọn, tọọgi ẹ lawọn, ṣe ọlọpaa kan yoo mu un ni. Aṣeju ni baba aṣetẹ, nigba ti Ọlọrun ba ti gbe eeyan de ipo to ga ti ko ni itẹlọrun, bi ẹtẹ ati abuku ti n gbẹyin aye wọn niyi. Aṣọ iyi ti Saraki wọ lo n faya mọ ara rẹ lọrun yii, o ku ibi ti yoo ti rowo da aṣọ iyi mi-in, ati telọ ti yoo ba a ran an!

 

(151)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.