Saraki sa lọ fawọn ọmọọṣẹ Buhari

Spread the love

Gbogbo ọna pata ni Aarẹ Muhammadu Buhari ati awọn ọmọọṣẹ rẹ n wa lati mu Olori ile-igbimọ aṣofin agba, Sẹnetọ Bukọla Saraki. Wọn fẹẹ mu un ki wọn ti i mọle, tabi ki wọn ṣeto ẹwọn fun un ni kopẹkopẹ, ko si wa nibẹ titi ti wọn yoo fi ṣeto idibo to n bọ yii, ti Buhari yoo fi tun pada wọle. Ṣugbọn igbesẹ akọkọ ti wọn ti ro pe yoo mu ọrọ naa ya kankan ni ki wọn ri ibi yọ ọkunrin yii kuro gẹgẹ bii olori ile-igbimọ aṣofin yii, ki wọn si sọ ọ di korofo. Bo ba ti di korofo bẹẹ, ko ni i ṣoro lati deede mu un lọsan-an gangan ọjọ kan, ti wọn yoo si la a mọnu ẹwọn, nibẹ ni yoo si maa gbe. Ko si si ohun meji to jẹ ki ija yii le to bo ti n le yii ju pe awọn ọmọọṣẹ Buhari fẹ ko pada sipo rẹ, ko jẹ lẹyin ti wọn ba dibo tan ni ọdun 2019 to n bọ yii, oun naa ni yoo maa ṣe aarẹ Naijiria lọ. Saraki ko fẹ eleyii rara.

Nitori pe Saraki ko fẹ bẹẹ lo ṣe fibinu kuro ninu ẹgbẹ APC, ẹgbẹ ti gbogbo wọn jọ lọ lati gbe Buhari wọle, amọ nigba to ti kuro ninu ẹgbẹ naa lo ti di ọta gbogbo awọn ti wọn fẹran Buhari, awọn ọmọọṣẹ Buhari ati awọn aṣaaju APC gbogbo si ti sọ pe ko si ọna ti yoo gbe e gba, awọn yoo ba a kanlẹ dandan. Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti i ṣe aṣaaju APC lapapọ fun gbogbo Naijiria sọ pe ko sohun meji to mu Saraki kuro ninu ẹgbẹ wọn ju pe o fẹẹ du ipo aarẹ lọ, ṣugbọn ibẹru Buhari ko jẹ ko le jade si gbangba sọ ọ. “Saraki ti ri i pe ninu ẹgbẹ APC, oun ko le di aarẹ, bẹẹ ni yoo tilẹ ṣoro foun gidi gan-an lati pada si ile-igbimọ aṣofin to wa yii, ka ma ti i sọ pe yoo ṣe olori wọn. Iyẹn lo ṣe kuro ninu APC, nitori awọn PDP ti sọ fun un pe o le dupo aarẹ, bi ko ba si wọle, awọn yoo da a pada sile-igbimọ aṣofin!”

Ki Tinubu tilẹ too sọ ọrọ yii jade ni Saraki funra rẹ ti ni oun n ronu gan-an lati du ipo aarẹ Naijiria, nitori oun mọ arun to n ṣe awọn eeyan ibẹ, oun si mọ ọna ti oun fi le gba tan iṣoro wọn. Ọrọ to sọ yii lo tubọ jẹ ki awọn ọmọ Buhari koriira rẹ, Adams Oshiomhole ti i ṣe alaga APC si tun jade pe awọn yoo yọ ọ nipo to wa yii, bo fẹ bo kọ, awọn yoo fẹyin ẹ balẹ dandan ni. Ohun kan naa ni wọn n duro de, iyẹn ni ọjọ ti wọn yoo jokoo pade ni ile-igbimọ aṣofin, wọn ni lọjọ ti wọn ba ti jokoo yii, ọjọ naa ni wọn yoo yọ ọ kuro nipo. Ọkan Oshiomhole ti balẹ, ọkan awọn ti wọn si jẹ aṣofin ti wọn fẹ ti Buhari naa ko mi rara, wọn mọ pe lọjọ ti awọn ba ti le pade, awọn yoo yọ Saraki nipo olori, ko si ni i jẹ nnkan kan mọ. Eyi lawọn eeyan naa si ṣe n pariwo loju mejeeji pe ki awọn aṣofin tete pade kiakia.

Awọn aṣofin ti wa ninu isinmi o, bi ko si nidi, ko yẹ ki wọn ti tun sare waa pade bẹẹ, ṣugbọn awọn eeyan Buhari ni ki wọn maa bọ, iyẹn naa si ni awọn aṣaaju APC fọwọ si, wọn ni ki wọn waa sọrọ lori owo ti awọn INEC to fẹẹ ṣeto ibo lọdun to n bọ yoo na. Ọgbọn ni, ẹtan si ni, bi wọn ba ti debẹ ni wọn yoo yọ Saraki. Ohun ti ọkan awọn eeyan naa ṣe balẹ bẹẹ ni pe wọn ti ri awọn aṣofin ọmọ ẹgbẹ APC kan ti wọn ti fẹẹ tẹle Saraki lọ sinu PDP da pada, eyi si ti jẹ ki awọn aṣofin APC pọ ju ti PDP lọ. Bo tilẹ jẹ pe wọn ko pọ to iye ti ofin sọ lati le fi yọ olori wọn, sibẹ, pẹlu agbara ọlọpaa ati agbara Buhari atawọn DSS, wọn yoo fi tipatipa yọ ọkunrin naa danu, wọn yoo si fi ẹlomiiran ti wọn ba fẹ si i. Ohun ti wọn ṣe n sọ pe ki awọn aṣofin lọọ jokoo ipade niyẹn, ki wọn le yọ ọ lojiji ni.

Saraki naa gbọn, o mọ ohun ti wọn fẹẹ ṣe, oun ati awọn eeyan rẹ naa si n da ọgbọn tiwọn. Wọn mọ pe bi wọn ko ba lọọ jokoo sile-igbimọ lati lọọ ṣe apero lori owo ti INEC fẹẹ na yii, Buhari ati awọn eeyan rẹ yoo sọ awọn lẹnu loju gbogbo aye, awọn Oshiomhole yoo si lo agbara wọn lati ko awọn aṣofin APC jọ pe ki wọn waa jokoo, nnkan kan naa ni yoo si ja si, nitori wọn yoo yọ Saraki nibi ijokoo wọn. Ohun ti wọn ṣe ni pe wọn sare pe igbimọ to n ri si iru ọrọ inawo bẹẹ nile-igbimọ aṣofin, wọn ni ki wọn bẹrẹ iṣẹ kia, nitori bi wọn ba jokoo naa loootọ, igbimọ naa ni wọn yoo pada gbe iṣẹ yii fun, ọrọ ti igbimọ naa ba si sọ ni wọn yoo pada waa jiroro le lori ki wọn too fọwọ si owo ti awọn INEC ni awọn fẹẹ na naa. Saraki waa kede pe o digba ti igbimọ yii ba ṣiṣẹ wọn tan ki awọn too jokoo kankan.

Ọrọ naa jo awọn ti wọn n wa a lara, wọn ni ko buru, ko maa dọgbọn, ogun ọdun kuku n bọ waa kọla. Igbimọ to n ṣiṣẹ naa ko tete yanju ọrọ yii, kaka bẹẹ, wọn ri owo rẹpẹtẹ ti awọn to n ṣeto ibo naa fẹẹ na ni inakunaa, wọn si gbegi di i, ọrọ naa si di ariwo laarin awọn ati ijọba Buhari. Ki i ṣe pe iṣẹ naa ti pari, ṣugbọn Saraki ti kede pe bi wọn ba pari iṣẹ wọn, ko le ya kiakia, ile-igbimọ aṣofin agba ati ile-igbimọ aṣofin kekere ni yoo jọ jokoo lẹẹkan naa lati jiroro lori ọrọ yii, ko ma di pe o n ni wahala kankan ninu, tabi awọn tun n fa ọrọ naa lọ fa a bọ. Bo ba jẹ tẹlẹ ni, ọtọ ni igbimọ aṣofin kekere yoo ṣe iṣẹ tiwọn, ọtọ lawọn aṣofin agba yoo ṣe tiwọn, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ lasiko yii, wọn ni awọn yoo jọ ṣe kinni naa pọ ni. Ọrọ yii dun awọn ọmọọṣẹ Buhari, nitori wọn mọ pe Saraki ti sa lọ mọ awọn lọwọ ni.

Ootọ si ni, Saraki ti sa mọ wọn lọwọ, nitori bi awọn aṣofin ba ti jọ jokoo pọ lati jiroro lori owo INEC, ko si ile-igbimọ kan to le sọ pe oun yoo yọ olori wọn niru ipade bẹẹ, ọrọ owo yii nikan ni wọn yoo sọ. Bi wọn ba ti sọ ọ tan ni wọn yoo tuka, o si di ipari oṣu kẹsan-an ki wọn too tun jokoo. Lasiko naa, ọpọ ibo abẹle ni wọn yoo ti di, awọn oloṣelu to ba fẹẹ wọ inu ẹgbẹ oṣelu mi-in yoo ti wọ ọ, yoo si ṣoro lati yi ohunkohun pada mọ, ko tilẹ ni i si akoko fun wọn lati ṣe bẹẹ, nitori ibo-didi yoo ti ku bii oṣu mẹta. Awọn aṣofin APC fẹrẹ le maa sunkun nigba ti wọn ri ọgbọn ti Saraki ati awọn eeyan rẹ gbe yọ, wọn mọ pe kinni naa ti bọ, ọna mi-in lo ku ti wọn n wa. Iyẹn ni Sẹnetọ Adamu Abdullahi ṣe sọ pe ki awọn EFCC dide, ki wọn waa yẹ bi Saraki ṣe nawo awọn ile-igbimọ wo, o daju pe wọn yoo ri i pe o kowo jẹ.

Ki aṣofin Abdullahi si too sọ eyi ni awọn EFCC ti bẹrẹ iṣẹ mi-in, wọn ni owo kan wa ti awọn kan ko jẹ nile-igbimọ aṣofin lasiko ti Buhari fi fun awọn gomina lowo kan bayii ti wọn da pada fun wọn lati ilu oyinbo, wọn ni awọn ọmọọṣẹ Saraki kan ti wọn ti ba a ṣiṣẹ ni banki baba rẹ (SGN), to tun gba wọn siṣẹ nile-igbimọ yii bayii, ni wọn ṣeto bi wọn ti ṣe ji owo naa ko. Awọn EFCC ti n kewi kiri bayii, wọn si ni wọn yoo mu wọn. Ohun ti wọn fẹ ni ki awọn yẹn jẹwọ pe Saraki lo ko owo fun awọn, tabi pe Saraki lo ni ki awọn ji owo ko, bi wọn ba ti le sọ bẹẹ, wọn yoo fi wọn silẹ, wọn yoo si gbe Saraki janto. Ija naa de ilu Ilọrin paapaa, nitori lasiko ti Saraki lọ sile ọdun, tawọn PDP ti duro de e ni papa-ọkọ-ofurufu Ilọrin lati fi ijo pade ẹ, awọn APC naa ko awọn eeyan tiwọn wa, lọrọ ba dija nibẹ.

Ko si tabi-ṣugbọn kan nibẹ, aarin ọta ni Saraki wa, nitori awọn ọmọ Buhari ko pada lẹyin rẹ. Loootọ lo ti ri ibi sa lọ lasiko yii na, ṣugbọn ibi ti yoo sa de ti wọn ko ni i pada mu un lẹnikan ko mọ, bi yoo ti ṣe e ku sọwọ oun ati awọn ti wọn n le e kiri.

 

(69)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.