Saraki pari ija laarin Adeleke ati Ogunbiyi

Spread the love

Pẹlu bo ṣe ku ọjọ mẹtala pere ti idibo gomina yoo waye nipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Bukọla Saraki ti pari aawọ to wa laarin oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ati ẹni ti wọn jọ koju ara wọn ninu idibo abẹle, Dokita Akin Ogunbiyi.

Lati ọjọ kọkanlelogun, oṣu keje, ọdun yii, ti gomina ipinlẹ Bayelsa, Seriake Dickson, ti waa ṣeto idibo abẹle ẹgbẹ PDP niluu Oṣogbo ni wahala ti bẹrẹ laarin Adeleke ati Ogunbiyi.

Ohun to si da wahala silẹ ko sẹyin bi Ogunbiyi atawọn alatilẹyin rẹ ṣe sọ pe ọrọ idibo abẹle naa ni ọwọ kan eru ninu. Lọjọ naa, ẹẹmeji ni wọn tun ibo Ogunbiyi ka, awọn alatilẹyin Ogunbiyi ni ki wọn tun ibo ti Adeleke naa, ka ṣugbọn awọn ti wọn ṣeto idibo naa ko ṣe bẹẹ.

Loootọ ni ẹgbẹ PDP fi orukọ Adeleke silẹ fun ajọ eleto idibo gẹgẹ bii oludije funpo gomina, oniruuru iwe ipẹjọ lo dide fun bii oṣu kan gbako, eleyii to mu ki ọpọ eeyan maa ro pe alawada lasan lẹgbẹ naa ti wọn ba n sọ pe awọn yoo gbajọba lọwọ Arẹgbẹsọla pẹlu wahala to n ṣẹlẹ laarin wọn.

Bi awọn olupẹjọ kan ṣe n sọ pe Adeleke ko kunju oṣuwọn lati dije latari pe ko kawe pari nileewe, bẹẹ lawọn kan ni maaki to buru jai lo ni ninu iwe ẹri to fẹẹ fi dupo gomina.

Ṣugbọn idajọ ile-ẹjọ yii ẹjọ mejeeji danu. Adajọ ni ko si ofin to sọ pe dandan ni ki oludije funpo gomina pari ileewe girama tabi ko ni maaki kan pato, ohun ti ofin sọ ni pe ki ẹri wa pe o lọ sileewe girama, iwadii si fidi rẹ mulẹ pe Adeleke lọ sileewe Ẹdẹ Muslim Grammar School, niluu Ẹdẹ.

O to akooko kan ti alaga apapọ ẹgbẹ naa lorilẹ-ede yii, Uche Secondus, ba awọn abala mejeeji ṣepade alaafia niluu Abuja, ṣugbọn awọn abala ti Ogunbiyi sọ pe Adeleke ko tẹle gbogbo adehun ti wọn jọ ṣe niluu Abuja, paapaa, pẹlu bo ṣe kọ jalẹ pe Ọnọrebu Albert Adeogun lati Ila-Oorun Ọṣun loun yoo lo gẹgẹ bii igbakeji gomina.

Laipẹ yii ni olu ile ẹgbẹ naa l’Abuja kede awọn igbimọ  ẹlẹni mẹtalelaaadọrun-un ti wọn yoo ṣeto ipolongo idibo gomina, wọn si yan Sẹnetọ Bukọla Saraki to jẹ aarẹ ile igbimọ aṣofin agba lorilẹ-ede yii gẹgẹ bii alaga igbimọ naa.

Lọsẹ to kọja ni Saraki pe ipade alaafia mi-in laarin Adeleke ati Ogunbiyi siluu Abuja, onikaluku wọn si fọwọ wọnu, wọn gbagbe ikunsinu aarin wọn, bẹẹ ni Ogunbiyi jẹjẹẹ lati ṣiṣẹ papọ pẹlu Adeleke lati le jẹ ki ẹgbẹ naa ṣaseyọri ninu idibo naa.

Nigba to di ọjọ keje, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, Ogunbiyi pe gbogbo awọn alatilẹyin rẹ kaakiri ipinlẹ Ọṣun jọ fun ipade niluu rẹ ni Olupọnna lati le fun wọn labọ ipade alaafia to waye l’Abuja, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun wọn nigba tipade naa de aaarin, ti Senetọ Ademọla Adeleke ati ẹgbọn rẹ, Dokita Deji Adeleke pẹlu awọn eeyan ṣanko ṣanko ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ọṣun yọ si wọn.

Irin yii lo fopin si gbogbo awuyewuye to wa nilẹ, gbogbo awọn agbaagba ẹgbẹ ti wọn wa nibẹ bii Erelu Oluṣọla Ọbada, Dokita Peter Adebayọ Babalọla, Alhaji Akinlẹyẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ si sọ pe ami aṣeyọri nla ni ipejọpọ naa jẹ fun ẹgbẹ PDP.

Sẹnetọ Adeleke dupẹ lọwọ Dokita Ogunbiyi fun bo ṣe fi ifẹ gba a, o ni ọmọ ẹgbẹ tootọ ni Ogunbiyi. O si ṣeleri lati ṣiṣẹ tọ ifẹ ati iṣọkan to ti fẹsẹ mulẹ laarin wọn.

Bakan naa ni Ogunbiyi naa dupẹ fun abẹwo wọn, o ni gbogbo awọn alatilẹyin oun ni wọn ti ṣetan lati ṣiṣẹ pẹlu Adeleke nitori pe to ba ti ṣaṣeyọri si rere, ẹgbẹ oṣelu PDP lo ṣẹgun yẹn

(15)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.