SARAKI KỌJU IJA SI BUHARI

Spread the love

“A oo jọ na an tan bii owo ni!”

Ohun meji ni Dokita Bukọla Saraki, olori ile igbimọ aṣofin agba, ṣe ti Aarẹ Muhammadu Buhari ati awọn ọmọlẹyin rẹ fi n binu si i. Ohun meji si ni Buhari paapaa ṣe ti inu fi n bi olori awọn aṣofin naa si i. Ija ti awọn mejeeji ti n ba ara wọn ja lati ọjọ yii wa lo jade si gbangba l’Ọjọru to kọja yii, nigba ti awọn tọọgi kan wọ ile igbimọ aṣofin naa, ti wọn si gbe Ọpa-aṣẹ, iyẹn ọpa agbara kuro nibẹ, loju gbogbo awọn aṣofin. Bi ile igbimọ aṣofin ti tobi to nni, bi wọn ba n sọrọ tabi ti wọn n paṣẹ kan, ti ko ba si Ọpa-aṣẹ yii niwaju wọn, bii ẹni to n sọrọ sofo lasan ni, Ọpa-aṣẹ yii ni ami pe agbara wa lọwọ wọn, bi ko ba si ti si lori ijokoo niwaju olori ile igbimọ yii, gbogbo ẹjọ ti wọn ba ro, gbogbo aṣẹ ti wọn ba ni awọn pa, otubantẹ lasan ni, ko sẹni ti yoo tẹle e. Awọn ti wọn ji kinni naa gbe mọ bẹẹ, ohun ti wọn ṣe waa gbe e naa niyẹn.
Ọjọ buruku lọjọ ọhun jare, lara ohun ti yoo si maa yaayan lẹnu titi fun ọpọlọpọ ọjọ ni bi awọn tọọgi mẹrin ṣe ya wọ ile igbimọ naa, ti wọn si gbe ọpa-aṣẹ yii, nibi ti awọn ọlọpaa ati agbofinro oriṣiiriṣii wa, ti ko si sẹni to le da wọn duro. Ati pẹlu, mọto awọn alagbara ilu lawọn tọọgi naa gbe wa, bi wọn si ti ji kinni naa gbe, ọna ti wọn tun gba sa lọ, ọna iyanu ni. Wọn ko gba oju titi ti gbogbo eeyan n gba, geeti kan wa to jẹ aarẹ orilẹ-ede yii nikan lo maa n ba ibẹ wọle to ba fẹẹ wa si ọdọ awọn aṣofin yii, wọn ko si ni i ṣi geeti naa silẹ nigba kan, afi bi aarẹ ba wa nile, nitori oun nikan lo n gba ibẹ kọja. Ko ma di pe ẹni kan yoo gba ibẹ lojiji tabi pe wọn yoo kọlu geeti naa, tọsan-toru lawọn agbofinro DSS fi n ṣọ ọ. Amọ lọjọ ti iṣẹlẹ yii ṣẹ, geeti yii gan-an lawọn tọọgi naa ba kọja, bi wọn ṣe ṣe e ko ye ẹnikan.
Ohun ti Saraki ri ree to fi mọ pe ejo ọrọ naa lọwọ ninu. Ṣe inu n bi i si Buhari, oun naa si mọ pe Buhari naa n binu soun. Oun n binu si Buhari nitori o ni Buhari n wa iṣubu oun, o fẹ ki wọn yọ oun kuro nipo olori aṣofin, iyẹn lo ṣe gba awọn EFCC laaye ki wọn maa ba oun ṣẹjọ, ohun to si fẹ gan-an ni bi wọn yoo ṣe ti oun wọ ẹwọn nigbẹyin gbẹyin. Ati pẹlu, Saraki tun binu si Buhari, o lo ti sọ tẹlẹ pe saa kan loun yoo lo nile ijọba, oun si ti wa ninu awọn ti wọn fẹẹ du ipo naa bo ba ti gbe e silẹ, afi bo ṣe yipada biri to tun loun fẹẹ ṣe aarẹ. Ohun meji to n bi oun ninu ni tiẹ niyẹn. Buhari naa n binu. O ni Saraki fẹẹ ba toun jẹ, ko fẹ ki oun ṣejọba lẹẹkeji, iyẹn ni wọn ṣe fẹẹ ṣofin lati yi eto idibo pada, ki wọn le ri i pe oun ko wọle. Ẹṣẹ keji si ni pe Saraki ti n sọ fawọn eeyan pe oun naa fẹẹ du ipo aarẹ, boya ninu ẹgbẹ APC tabi ninu PDP.
Ṣe awọn oloṣelu ni wọn mọ ara wọn, wọn si maa n ri ara wọn tan. Loootọ, lati ibẹrẹ aye ijọba yii ni Buhari ko ti fẹ ti Saraki, ohun ti gbogbo eeyan si ro pe o fa a ni ọna ti Saraki fi di olori ile igbimọ aṣofin. Ṣugbọn iyẹn nikan kọ, Buhari atawọn eeyan ẹ mọ pe Saraki ko fi bẹẹ nifẹẹ olori Naijiria naa, bo ba ṣe pe ohun to fẹ ṣẹlẹ ni, Abubakar Atiku loun fẹ bii aarẹ, eyi lo ṣe jẹ bi ọrọ kan ba ti ṣe bii ọrọ, ọdọ Atiku lo n sare lọ; ibi ti wọn si di i si ko ye ẹnikan. Iyẹn ni wọn ṣe n le Saraki kiri lati ọjọ yii, nigba ti Ọlọrun yoo si mu iṣẹ wọn rọrun, ọwọ Saraki funra rẹ ko mọ, ko si ṣoro lati tu aṣiri awọn owo to ko jẹ sita. Ṣugbọn gbogbo bi wọn ti le ọkunrin naa to lati gba ibi ole to ja nile ijọba yii mu un, niṣe loun naa n yọ bọrọ mọ wọn lọwọ. Iyẹn ni wọn ṣe ro pe gbogbo anfaani to n jẹ ni pe o jẹ olori ile igbimọ, bi ipo naa ba bọ lọwọ rẹ, ọwọ yoo to o.
Amọ bi awọn ti n le e yii, bẹẹ loun naa n wa ọna ti nnkan yoo fi bọ lọwọ Buhari funra rẹ. Nigba ti Buhari ko tete sọ eyi to fẹẹ ṣe, Saraki jade sita, o si fi ọrọ naa si oniroyin kan lẹnu, niyẹn ba ju u sita pe Saraki ti n mura silẹ fun ibo aarẹ, to si sọ awọn iṣẹ rere rere ti ọkunrin ara Kwara naa ti ṣe. Bi iroyin naa ti jade ni jinnijinni da bo Buhari ati awọn eeyan rẹ, iyẹn lo si ṣe sare lọ si ibi ipade awọn apaṣẹ APC, to si kede pe oun fẹẹ du ipo aarẹ lọdun to n bọ, ko si iyẹn ninu ero rẹ rara. Nigba to ti jade bayii, Saraki ko tun le sare jade bẹẹ, n lo ba mura si ọna ti wọn n tọ tẹlẹ, pe ki wọn yi ofin idibo pada. Ofin eto idibo ti wọn fẹẹ yipada yii, bi wọn ba ri i ṣe, iṣoro ni yoo jẹ fun Buhari lati wọle, nitori bo ba wọle paapaa, ile-ẹjọ le fagi le e pe ko wọle, ti wọn yoo si gbejọba naa fun ẹlomiiran.
Igba ti awọn Buhari ti ri i bayii lawọn naa fi sare gbe ẹni kan dide nile igbimọ nibẹ, Ovie Omo-Agege ni. Latijọ ti awọn aṣofin ti bẹrẹ eto naa ni Omo-Agege ti pe awọn oniroyin jọ, o bu Saraki, o bu gbogbo awọn alaṣẹ ile igbimọ yii, o ni ko si awo kan ninu awo-ẹ̀wà mọ, aṣiiri wọn ti tu, nitori Buhari ni wọn ṣe fẹẹ yi eto idibo naa pada. Eleyii lo bi awọn aṣofin ninu, nigba ti wọn si jokoo ipade, wọn da sẹria fun Omo-Agege, wọn ni fun oṣu mẹfa gbako, wọn ko gbọdọ ri i nile igbimọ aṣofin mọ. Nigba naa ni Omo-Agege ati awọn Sẹnetọ mi-in nile igbimọ nibẹ ṣepade, wọn si pinnu pe awọn yoo mọ bi awọn yoo ṣe yọ Saraki, agaga nigba ti ko ba si nile. Lọjọ Mọnde ọsẹ to kọja ni Saraki lọ si Amẹrika fun ipade awọn olori aṣofin agbaye, bo si ti jade niluu ni Omo-Agege ko tọọgi wa si ile igbimọ naa, ni wọn ba ji ọpa-aṣẹ gbe.
Ohun to jẹ kawọn eeyan mọ pe oun ni ni pe awọn tọọgi naa ni wọn sin in wọ ile igbimọ, bi wọn si ti wọle ni wọn da wahala silẹ, lọrọ ba di bo-o-lọ-o-yago. Awọn ọlọpaa ni awọn ko mọ pe wọn n lọọ fajangbọn ni, nitori Omo-Agege ni wọn tẹle wọle. Ṣugbọn igbakeji olori ile igbimọ aṣofin to dari ipade ọjọ naa sọ pe awọn agbofinro ko lẹnu lati sọ pe awọn ko mọ ohun to ṣẹlẹ, bi wọn ba lawọn ko mọ, a jẹ pe ko yẹ ka pe wọn ni agbofinro. Ṣebi gbangba lawọn tọọgi yii paaki ọkọ ti wọn fi waa ṣe ijamba si, bẹẹ lawọn agbofinro si ri wọn nigba ti wọn n gbe ọpa aṣẹ naa lọ. Ṣe wọn ko da a mọ ni. Eyi to si mu ọrọ naa fidii mulẹ ni pe ọna ile aarẹ lawọn tọọgi naa ba lọ. Awọn ọlọpaa ti wa lọjọ keji o, wọn ni awọn ti ri ọpa-aṣẹ naa nibi tawọn tọọgi sọ ọ si, gbogbo araalu n pariwo ni pe afi ki wọn wa awọn tọọgi naa jade.
Aṣofin kan sọ fun Alaroye pe awọn tọọgi yii fẹẹ waa da wahala silẹ nile igbimọ ni, wọn ti ro pe aṣofin bii Dino Melaye yoo wa nibẹ, oun pẹlu awọn onijangbọn mi-in, bi awọn tọọgi naa ba si fẹẹ gbe ọpa-aṣẹ lọ bẹẹ, wọn yoo doju ija kọ wọn, yoo si di ki wọn maa fi aga fọ ara wọn lori, ti ohun gbogbo yoo si daru. Nigba naa ni awọn ọlọpaa yoo ya wọle pẹlu tiagaasi, wọn yoo si le awọn aṣofin gbogbo lọ, ijọba yoo si ti ile igbimọ aṣofin naa pa fun oṣu pipẹ, wọn yoo ni rogbodiyan to n ṣẹlẹ nibẹ lawọn ṣe ti i pa. “Wọn fẹẹ waa da ile igbimọ aṣofin ru ki wọn le ti i pa ni!” Ohun ti ọkan ninu awọn aṣofin naa sọ fun wa niyẹn.
Saraki funra ẹ ti sọrọ nibi to wa lọhun-un, o ni awọn ti wọn ṣe bẹẹ yẹn ko lohun meji ti wọn fẹẹ ṣe, wọn fẹẹ le awọn ti awọn jẹ olori ile igbimọ naa kuro, ki wọn fi awọn eeyan tiwọn si i ni, ṣugbọn apa wọn ko ka a, nitori wọn ko lero lẹyin, wọn kan n lọ bóóbóò lasan ni. Buhari wa ni London nigba tọrọ yii ṣẹlẹ, Saraki naa si wa l’Amẹrika. Awọn mejeeji ti de bayii o, Alaroye si gbọ pe niṣe ni wọn n leri sira wọn pe ọrọ to wa nilẹ yii, awọn yoo jọ na an tan bii owo ni!

(122)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.