Saraki, ki lo buru ninu iyẹn jare

Spread the love

Aṣiwaju Bọla Tinubu kọ lẹta kan si Oloye Bukọla Saraki, Olori ile-igbimọ aṣofin, o ni nitoripe ọkunrin naafẹẹdu ipo aarẹ, o si ti mọ pe ko le si aaye bẹẹ foun ninu APC loṣe sa kuro ninu ẹgbẹ, o ni nitori ibẹru Buhari lo ṣe lọ. Saraki naa mọpe ootọleleyii, ko ṣa siawo kan ninu awo ẹwa mọ, awọn ti wọn sun mọọn ti sọ peo fẹẹdu ipo aarẹ, oun naati sọ pe oun n ro ọrọ naa daadaa gan-an, oun fẹẹ jade lati du ipo aarẹ. Bi oun funra rẹ ba ti le sọ bẹẹ, ki lo waa tun ku. Oun naakuku mọpe oun ko le gbe inu APC ki oun jadelati tako Buhari, ọrọ oṣelu Naijiriako gbabẹẹ, ohun ti ko ro ni yoo ba pade. Oun naamọ bẹẹ, iyẹn ni ko si ṣe sẹni to le mu oun si i pe o ṣefi ẹgbẹ silẹ, bẹẹni ko si ba ẹnikẹni labo pe o fẹẹ du ipo aarẹ lo ṣe lọ, tabi pe o bẹru Buharini. Ṣugbọn Saraki fesi pada funTinubu, esi rẹ si ni pe inu kan n bi Tinubu soun ni. O nigbogboohun ti Tinubu ba ṣe, nitori to fẹ ki oun di aarẹ Naijiria lọdun 2023, o fẹ ki wọn gbe ipo aarẹ naapada si ilẹ Yoruba ni. Biko ṣesi ohun to buru ninu peki Saraki fi APC silẹ ko lọ si PDP nitori lati du ipo aarẹ, bẹẹ naani ko ṣe si nnkan ti ko dara ninu ki Tinubu jade pe oun yoo du ipo aarẹNaijiria ni 2023, tabi pe ki wọn da kinni naapada si ilẹ Yoruba. Ṣe ti pe Yoruba ko ni imọ lati ṣejọba ni tabi pe wọn ko kun oju oṣuwọn. Ati pe ewo niSaraki funra rẹ n ṣe, ṣe ọmọ Yoruba loun ni abi ọmọ Hausa, abi Fulani ni. Lara ohun to maan fa wahala fun wọn naaree, nitori lara ohun to fa wahala fun baba tirẹ niyẹn, iyẹn Oloye Oluṣọla Saraki. Nigba to fẹẹ du ipo aarẹ nigba aye rẹ, yoo ni oun Abubakar Saraki fawọn ara ilẹ Hausa, yoo ni oun Oluṣọla Saraki fun awọn ara ilẹ Yoruba ati Ibo, ko si pẹ ti awọn eeyan fi mọ pe adan ti ko ṣeku ti ko ṣẹyẹ ni. Bi Saraki ba gbọn, yoo fi ti baba rẹṣe arikọgbọn ni. Bo ba jẹ Fulani ni, ko tete sọ fawọn eeyan rẹ pe Fulani loun, ko si maa ba awọn Fulani ṣe, bo ba si jẹ Yoruba naa ni, ko rin mọ wa nisalẹ, ko si jẹ ka mọ petiwa lounn ṣe. Bi a ba fẹẹjẹọṣaka ki a jẹọṣaka, bi a ba si fẹẹ jẹ oṣoko, ki a jẹ oṣoko, ọṣakaṣoko ni ko yẹọmọ eniyan. Ko sohun to buru ninu eyi ti Tinubu wi bo ba jẹ loootọ lo loun yoo gba ipo aarẹ fun Yoruba ni 2023, Saraki ni ko mọ eyi toun funra ẹ ba fẹẹṣe.

 

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.