Saraki fun awọn araalu ti omiyale ba dukia wọn jẹ ni miliọnu mẹwaa Naira

Spread the love

O kere tan, awọn araalu to le ni ọgọfa ti wọn fara gba ninu iṣẹlẹ omiyale ni Ẹkun Aarin-Gbungbun ipinlẹ Kwara lo jẹ anfaani iranlọwọ owo oni milọnu mẹwaa Naira ti Olori ile igbimọ aṣofin agba, Dokita Bukọla Saraki, ṣe fun wọn.
Awọn araalu naa ti wọn jẹ aadọjọ niye tẹwọ gba owo ọhun lọfiisi ipolongo Saraki, niluu Ilọrin.
Ṣaaju ni aṣofin yii ti pese ibugbe fun awọn to lugbadi iṣẹlẹ omiyale naa, nibi to ti n fun wọn ni ounjẹ atawọn nnkan eelo mi-in.
Alhaji Musa Abdullahi to pin awọn ẹbun naa fun awọn to jẹ anfaani ẹ ṣalaye pe ọna kan ti Dokita Saraki fi ṣeranwọ fun awọn araalu ni eto naa. O ni ki i ṣe ẹgbẹ oṣelu ni wọn fi pin in. Abdullahi sọ pe:
‘Adari wa to tun jẹ aarẹ ile-igbimọ aṣofin agba, ri i pe ohun to bojumu ni lati ran awọn ti iṣẹlẹ omiyale sọ di alainile-lori lọwọ kaakiri Aarin-Gbungbun Kwara, lai ka ẹgbẹ oṣelu ti wọn n ba n ṣe si.’
Alhaji Yusuf Jimoh ati Alhaja Adijat Baki to gbẹnusọ fun awọn to jẹ anfaani ẹbun naa dupẹ lọwọ Saraki fun dide iranlọwọ fun wọn.
Awọn eeyan ọhun ni Saraki nikan ni oloṣelu to ṣeranwọ fun awọn lẹyin iṣẹlẹ omiyale naa ṣeleri lati ṣatilẹyin fun un ninu idibo ọdun to n bọ.
Abdullahi ke si awọn to jẹ anfaani naa lati tẹsiwaju nipa ṣiṣe atilẹyin fun Saraki, ki wọn si dibo fun ẹgbẹ oṣelu PDP ninu eto idibo aarẹ ati ti ipinlẹ.

(21)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.