SARAKI D’EEGUN ẸJA, O TI HA BUHARI LỌRUN Ko ṣee gbe mi, ko ṣee tu danu

Spread the love

Ohun tawọn oniroyin gbogbo gbe jade lọsẹ to kọja ni pe awọn ọlọpaa lọ si ile olori ile igbimọ aṣofin agba, Sẹnetọ Bukọla Saraki, ati igbakeji rẹ, Ike Ekweremadu, nitori ki wọn le di wọn lọwọ lati jade, ki wọn ma baa raaye gba alejo awọn aṣofin ọmọ ẹgbẹ APC ti wọn fẹẹ dọmọ ẹgbẹ PDP ni. Ṣugbọn Alaroye ti fidi ẹ mulẹ pe bẹẹ kọ lọrọ naa ri rara, ohun to ṣẹlẹ gan-an kọ niyẹn, o kan fara jọ ọ ni. Ohun to ṣẹlẹ lọjọ yii, Iditẹgbajọba ni wọn n pe e, iyẹn lawọn ṣọja n pe ni Kuu (Coup) laarin ara wọn. Ko yatọ sira wọn. Bawọn ṣọja ti n gbajọba lọwọ olori ti wọn fẹẹ le kuro lori oye naa ni wọn ṣe nijọ naa, boya nitori Aarẹ Muhammadu Buhari si jẹ ṣọja funra rẹ ni kinni ọhun ṣe lọ bo ṣe lọ. Bi ko si jẹ pe Ọlọrun ṣi wa lẹyin Saraki ati igbakeji rẹ, itimọle ni wọn iba wa titi di bi a ti n sọrọ yii.

Wọn ti pari eto naa. Ọrọ naa ni ọwọ awọn to sun mọ Buhari pẹkipẹki nile ijọba ninu, bẹẹ lo lọwọ olori awọn SSS ninu, olori EFCC wa wa nibẹ, ati ọga awọn ọlọpaa patapata pẹlu awọn sẹnetọ ti wọn jẹ APC, ti wọn si le ku nitori Buhari. Ọna mẹrin ọtọọtọ ni wọn pin ara wọn si, wọn si ti fun kaluku niṣẹ ti yoo ṣe. Awọn aṣofin APC yii yoo wa ni otẹẹli kan, wọn yoo ko ara wọn jọ sibẹ, wọn yoo si tibẹ gbera lọwọ kan lọ si ile-igbimọ aṣofin ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje, ọdun 2018. Ni kutukutu ọjọ naa gan-an, awọn ọlọpaa kan yoo lọ si ile olori igbimọ aṣofin agba, awọn SSS yoo tẹle wọn lọ, wọn yoo duro sẹnu ọna ile rẹ, wọn yoo ni ko le jade lọ sibikibi. Bawọn kan ti wa nile ẹ yii, bẹẹ lawọn mi-in yoo lọ sile igbakeji rẹ, awọn ọlọpaa EFCC ati SSS, wọn yoo ni oun naa ko le jade.

Awọn ti wọn wa ni ọna kẹrin ni awọn ọlọpaa mi-in, ile-igbimọ aṣofin ni awọn yoo wa, wọn yoo si pọ nibẹ rẹpẹtẹ, iṣẹ ti awọn naa fẹẹ ṣe ọtọ ni. Bi eto naa ṣe ri niyi. Ni ile-igbimọ aṣofin, awọn mẹta pere naa ni wọn le paṣẹ daadaa, ti wọn si le di ipo olori ile-igbimọ naa mu. Bi eeyan kan ba ti jokoo sori aga olori ile-igbimọ aṣofin, aṣẹ to ba pa naa ti di ofin, ko si sẹni to le yi i pada mọ. Ẹni akọkọ to jẹ ipo rẹ ni, to si le jokoo sibẹ ni olori ile-igbimọ aṣofin funra rẹ, iyẹn Bukọla Saraki. Ẹni keji to le gba ipo rẹ bi oun ko ba si nile naa ni igbakeji rẹ, iyẹn Ekweremadu. Bi awọn mejeeji yii ko ba fi waa si nile, tabi ohun kan ṣe wọn ti wọn ko fi ni i le si nile-igbimọ aṣofin, ẹni kẹta to tun le ṣe e ni olori ọmọ ẹgbẹ to pọ julọ nile-igbimọ naa, iyẹn ni wọn n pe ni mejọriti-lida (Majority Leader), Ahmed Lawan, ni.

Ahmed Lawan yii lo ṣaaju awọn aṣofin ọmọ ẹgbẹ APC ti wọn ko ara wọn jọ si otẹẹli kan, ohun ti wọn si n ro ni ki asiko lati wọle sile-igbimọ to, ki wọn si wọle. Bi wọn ba ti wolẹ ti wọn ko ri Saraki, ti wọn ko si ri Ekweremadu, kia ni Lawan yoo lọọ jokoo tepọn sori aga, bo ba si ti wọle to jokoo ti wọn ba sọrọ diẹ ni ẹni kan yoo dide pe oun fẹẹ da a labaa pe ki wọn yọ Saraki ati Ekweremadu, nitori pe awọn mejeeji lo ni ẹjọ buruku ti wọn n jẹ lọwọ, ẹjọ naa si tabuku fun awọn aṣofin. Wọn yoo ni wọn darukọ Saraki si ọrọ awọn adigunjale ti wọn mu l’Ọffa, bẹẹ ni awọn EFCC n ba Ekweremadu ṣe ẹjọ pe o ko owo jẹ, ati pe nitori ẹjọ ti wọn n ba wọn ṣe yii ni awọn mejeeji ko ṣe raaye de ile-igbimọ aṣofin. Bayii lawọn aṣofin to ku yoo dibo, wọn yoo si sọ pe awọn ti yọ Saraki ati igbakeji ẹ.

Nigba ti awọn ba yọ wọn yii, ti wọn si ti mu Lawan gẹgẹ bii olori ile-igbimọ aṣofin, nigba naa ni wọn yoo sọ awọn ọrọ mi-in, wọn yoo si ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ. Awọn ọlọpaa ti wọn wa nita yoo ri i pe ko si kinni kan to ṣẹlẹ nibẹ, bi ẹnikan ba fẹẹ fa wahala lori ọrọ naa, kia ni wọn yoo gbe e jade, iṣẹ ti awọn ọlọpaa ti wọn wa sile-igbimọ lọjọ naa waa ṣe niyẹn. Nigba ti ohun gbogbo ti lọ ti ko si wahala, nigba naa ni awọn ọlọpaa yoo wọle tọ Saraki, wọn yoo ni awọn mu un nitori ọrọ ẹjọ idigunjale to wa niwaju rẹ, pe ko waa lọọ ṣalaye awọn nnkan kan fawọn. Bo ba ti debẹ ni wọn yoo ti i mọle, wọn ko si ni i ṣi i silẹ lọjọ naa tabi lọsẹ naa, wọn yoo ni awọn n ṣe iwadii awọn lọwọ ni. Bẹẹ naa ni wọn yoo ṣe fun Ekweremadu, wọn yoo mu oun naa, awọn EFCC yoo si ni awọn ti i mọle fun iwadii awọn.

Bayii lawọn eeyan yii yoo ṣe lo ọsẹ kan tabi ju bẹẹ lọ ni itimọle, ki wọn si too fi wọn silẹ, ile-igbimọ aṣofin tuntun naa yoo ti fi ẹsẹ mulẹ, Lawan yoo ti di olori ile-igbimọ, wọn yoo si ti yan awọn alakooso tuntun ti wọn ko mọ Saraki ri rara, to jẹ wọn kan jọ wa nile-igbimọ ni, ti Buhari ni wọn n ṣe. Ile-igbimọ paapaa yoo ti ṣiṣẹ bii ọsẹ kan yii, wọn yoo si ti sun ijokoo wọn siwaju, wọn yoo si ti ko ẹru Saraki ati ti Ekweremadu lọ si ile wọn, nitori ẹlomi-in yoo ti maa lo ọfiisi wọn. Eto ti wọn ṣe niyi, wọn si ti pari gbogbo rẹ, wọn ti sọ fun Buhari paapaa pe ko fọkan balẹ, kinni naa ko ni i yingin, ọwọ ti ba Saraki, nibi ti awọn ti fẹẹ mu un yii, ko ni i ribi bọ. Ṣugbọn Saraki fi ayo elegee ta wọn yọ, o jẹwọ fun wọn pe oun ti pẹ nidii oṣelu yii ju Buhari ati ọpọlọpọ awọn ti wọn n tẹle e lẹyin lọ.

Titi di asiko yii, ko sẹni to le sọ pe oun mọ bo ti ṣe e. Awọn kan sọ pe laarin oru lo ti jade kuro nile, ṣugbọn awọn kan sọ pe ile-igbimọ aṣofin yii gan-an lo sun, awọn eeyan naa ko kan mọ ni, nitori nigba ti awọn aṣofin yoo fi wọle, nibẹ ni wọn ba a. Asiko ti oun fi wa nile-igbimọ yii, awọn ọlọpaa ti di ile rẹ bamubamu, wọn n reti ko jade, nigba ti mọto kan si jade bii mọto rẹ ti wọn lero pe oun lo wa ninu rẹ, wọn bẹrẹ si i fi ibọn halẹ, wọn ni dẹrẹba naa ko le jade, afi ko pada sinu ile. Itiju buruku lo waa jẹ fun ọga ọlọpaa ati awọn ọmọ rẹ nibẹ nigba ti wọn gbọ pe Saraki ti wa nile-igbimọ aṣofin. Awọn aṣofin APC ti wọn ti ko ara wọn jọ si otẹẹli sare balabala o dọhun-un, bi wọn si ti n wọle ni wọn ba awọn aṣofin APC kan ti wọn ti mura lati di ọmọ PDP, Saraki n ka lẹta ti wọn kọ lọwọ ni, lọrọ ba pesi jẹ.

Titi ti a fi n ko iroyin yii jọ, Buhari ati awọn eeyan rẹ ṣi n wa gbogbo ọna lati yọ Saraki. Nigba ti awọn ọlọpaa halẹ mọ ọn ti wọn ko ri i mu bayii, wọn ni dandan ni ko maa bọ lọdọ awọn, awọn fẹẹ ri i ni. Saraki ko da wọn lohun, o loun ko lọ. Awọn ọlọpaa ti lọ si ọfiisi rẹ, wọn beere ẹjọ lọwọ rẹ, ṣugbọn Saraki ti ṣa awọn agba lọọya kan jọ bayii pe ki wọn pe Ọga ọlọpaa pata naa, Abubakar Idris, pe ko yee yọ oun lẹnu. Awọn aṣofin APC to ku lọ sọdọ Buhari, wọn jọ jẹun, ṣugbọn iye awọn ti wọn wa nibẹ ko to lati yọ Saraki nipo rẹ, wọn n wa awọn mi-in si i. Alaga APC tuntun, Adams Oshiomhole, n fẹsẹ halẹ pẹlu ibinu bayii, bo ti n kuru lo n ga, nigba to si jẹ eeyan kukuru lọkunrin naa tẹlẹ, niṣe lo n tiro bayii, o ni bi oun ko ba yọ Saraki, oun ko ni i sinmi.

Iṣoro ibẹ bayii ni pe ko si ọna ti wọn yoo gba yọ Saraki, o ti sun ijokoo ile igbimọ aṣofin siwaju di ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹsan-an, ko si si bi awọn ọmọ ẹgbẹ APC ṣe le ṣa ara wọn jọ ti wọn yoo ni mejọriti ti wọn yoo fi le lọ si ile-igbimọ naa lẹyin Saraki, ko ṣee ṣe. Awọn ti wọn mọ nipa oṣelu ti kilọ fun Buhari pe ko fi Saraki silẹ ko maa ba tirẹ lọ, wọn ni ọkunrin naa ti di eegun ẹja, o si ti ha a lọrun, ko ṣee jẹ, ko ṣee pọ silẹ, bo ba si sọ pe oun yoo fi tipatipa yọ ọ, afaimọ ki eegun naa ma bẹ ẹ lọna ọfun. Niṣe ni wọn ni Buhari paapaa n fọwọluwọ, ‘Iru ki leleyii Olodumare!’ ni wọn ni baba arugbo naa n sọ lẹnu!

 

(35)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.