Samuel Eto’o fẹyinti lẹyin ọdun mẹtadinlọgbọn

Spread the love

Ogbontarigi agbabọọlu ilẹ Cameroon nni, Samuel Eto’o Fils, ti fẹyinti lẹnu iṣẹ bọọlu gbigba lẹyin to lo apapọ ọdun mẹtadinlọgbọn.

Opin ọsẹ to kọja lẹni ọdun mejidinlogoji naa fi adagba eto rọ lati mu ileri to ṣe bii oṣu mẹta sẹyin ṣẹ.

Eto’o tawọn onimọ bọọlu gbagbọ pe o wa lara awọn agbabọọlu agbaye to ṣe bẹbẹ ju nidii iṣẹ naa kede ọrọ yii lori ẹka Instagram rẹ, o ni asiko ti to lati maa lọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ ọ: ‘Opin niyi. Mo n lọọ ṣakitiyan tuntun. Mo dupẹ lọwọ gbogbo yin, mo nifẹẹ yin pupọ.’

Ọdun mejilelogun ni Eto fi ṣe bẹbẹ nipele agba lẹyin to lo ọdun marun-un nipele ọjẹ-wẹwẹ. Laarin ọdun 1992 si 1997 lo fi gba bọọlu nipele ọjẹ-wẹwẹ nileewe ere idaraya Kadji Sports Academy, to wa nilẹ Cameroon, ati fun ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid, ilẹ Spain.

Real Madrid yii lo ti gba igbega ko too lọ sawọn kilọọbu mejila mi-in nilẹ Spain, Italy, Russia, England, Turkey ati Qatar.

Orukọ rẹ ko le parẹ ni Kilọọbu Barcelona, ilẹ Spain, rara pẹlu bo ṣe ran wọn lọwọ lati gba ife-ẹyẹ Champions League meji, La Liga mẹrin, Supercopa de Espana meji ati Copa del Rey kan.

Laarin ọdun marun-un to lo nibẹ, igba mejidinlaaadọfa (108) lo gba bọọlu wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹrinlelogoje (144).

Laarin ọdun 1997 si 2014 lo fi gba bọọlu fun Cameroon. Igba mẹrin lo lọ si idije agbaye fun ilẹ naa, ifẹsẹwọnsẹ mejidinlọgọfa (118) lo si ti kopa lapapọ, nibi to ti gba ayo mẹrindinlọgọta (56) wọle.

Oun ni agbabọọlu Cameroon to gba bọọlu sawọn ju, agbabọọlu to gba ayo wọle ju nibi idije Afrika, bẹẹ lo gba awọọdu agbabọọlu Afrika to dangajia ju nigba mẹrin. Agbabọọlu to ni iru akọsilẹ bii tirẹ yii ni Yaya Toure ilẹ Cote d’Ivoire.

Lapapọ, awọn ife-ẹyẹ, ami-ẹyẹ ati itan to fi balẹ le diẹ ni aadọta.

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.