Salaudeen atawọn ẹgbẹ rẹ pa ọmọ oniwara, wọn tun yọ ọkan rẹ lọ niluu Malete

Spread the love

Salaudeen Azeez, ọmọ ọdun mẹjidinlogun, toun pẹlu awọn ẹgbẹ rẹ pa ọmọ ọdun mejila kan to n kiri wara, Habu Adamu,niluu Malete, nipinlẹ Kwara, nile-ẹjọ ti paṣẹ lọsẹ to kọja ki wọn wa lahaamọ ọgba-ẹwọn. 

Azeez atawọn akẹgbẹ rẹ; Ismail Salimon, Abdulrauf Anafi atawọn mi-in ti wọn ti sa lọ ni wọn jọ gbimọpọ lati pa ọmọbinrin Fulani naa lati fi ṣe oogun owo.

Akọsilẹ ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn fi wọ awọn afurasi naa lọ sile-ẹjọ ṣalaye pe baba ọmọ naa, Adamu Abdullahi, lo fi to ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Malete leti pe Habu ti dawati.

O sọ fawọn ọlọpaa pe abule Baala ni ọmọ naa kiri wara lọ,ṣugbọn ti ko pada sile mọ.

Nigba tawọn to n wa ọmọ naa yoo pada ri i, oku rẹ ni wọn nibi tawọn afurasi naa ri i mọ ninu igbo kan to wa nitosi abule Paboo.

Wọn ṣakiyesi pe wọn ti la apa osi aya ọmọ naa, wọn si ti yọ awọn ẹya ara kan lọ lara rẹ.

Iwadii ẹka CIID fi han pe Salaudeen Azeez, Ismail Salimon ati Ibrahim ti gbogbo wọn n gbe abule Baala ni wọn gbimọpọ lati pa ọmọbinrin naa.

Bakan naa niwadii ileeṣẹ ọlọpaa fidi ẹ mulẹ pe lẹyin ti wọn yọ ọkan ọmọ naa, wọn gbe e fun Abdulrauf Anafi to n gbe ni Isalẹ Baani, lagbegbe Abayawo, niluu Ilọrin, lati fi ṣe oogun owo.

Anafi jẹwọ pe loootọ loun ran Akeem Fatai lati ba oun wa ọkan eeyan koun fi soogun owo. O ni Saliman naa wa nibẹ nigba naa.

Nigba to di ọjọ kẹrinla, oṣu keji, ọdun 2019, ni Saliman ti Anafi pada gbe iṣẹ yẹn fun pe Anafi lati waa gba ọkan eeyan to bẹ oun lati wa.

Lẹyin ti wọn ni Anafi gba ọkan ọmọ naa lo gbe e fun ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Isiaka, tiyẹn si gbe kinni ọhun sa lọ lati fi soogun owo.

Iwadii fi han pe ọjọ kẹrinla, oṣu keji, ọdun 2019 yii gan-an lawọn afurasi naa lọ dena de ọmọbinrin naa, ti wọn si yọ ọkan rẹ lẹyin ti wọn pa a.

Adajọ Awolọla Abioye tile-ẹjọ Magisreeti to n gbọ ẹjọ naa ni ile-ẹjọ ọhun ko laṣẹ labẹ ofin lati gbọ ẹjọ ọhun, o waa sun ẹjọ naa si ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 2019.

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.