Salami kọyawo ẹ ni Ṣaki, o lo ti le jowu ju

Spread the love

Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun

 

Ile-ẹjọ kọkọ-kọkọ to wa niluu Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ, ti tu igbeyawo ọdun mẹjọ kan ka, latari ẹsun owu jijẹ.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, ni Ọgbẹni Idowu Salami, ẹni ọdun mẹrinlelogoji to n ṣiṣẹ awakọ, mu ẹjọ iyawo rẹ, Abilekọ Latifat Mayeloye, wa sile-ẹjọ pe ki wọn tu igbeyawo awọn ka nitori pe ọrọ obinrin naa ti su oun, ibagbe awọn ko si le wọ mọ.

Salami to n gbe laduugbo Asunnara, niluu Ṣaki, ṣalaye pe gbogbo igba ni obinrin naa maa n ṣo oun lọwọ-lẹsẹ, paapaa to ba ti le kofiri oun pẹlu obinrin mi-in, o ni ija nla lo maa n gbe koun loju, ki i si i duro gbẹjọ. Igbesẹ yii lo sọ pe o n dojuti oun nibi gbogbo.

O ni ojowu obinrin ti ko ba pa ọkọ, yoo pa ara rẹ ni, idi si niyi toun fi mu ẹjọ rẹ wa, ko ma baa pa oun.

Nigba to n dahun ibeere adajọ boya o fara mọ ibeere ọkọ rẹ, kia ni Latifa fesi pe oun fara mọ ọn pe kile-ẹjọ tu igbeyawo wọn ka.

Oun naa ṣalaye pe irin ẹsẹ Salami ko mọ rara, ati pe irọ pipa ti jaraba ọkọ oun ju. O ni oniruuru iwa aiṣootọ lo kun ọwọ ẹ.

Abilekọ Latifa tun beere pe lẹyin ti ile-ẹjọ ba tu wọn ka tan, ki wọn ba oun gba ẹgbẹrun lọna aadọta Naira toun ya ọkọ oun nigba kan lati fi ṣiṣẹ, ṣugbọn to kọ lati da pada foun. Iyaafin Latifa ni koun too kuro, o di dandan koun gba owo naa lọwọ rẹ nitori ẹni ti oun ba a ya owo yii lọwọ rẹ ti n foun ni wahala.

O waa bẹbẹ pe ki kile-ẹjọ yọnda Alia, ọmọ ọdun mẹrin, tawọn bi  foun, ki oun le tọju rẹ daadaa.

Adajọ Muritala Oladipupọ sọ pe, lẹyin tawọn mejeeji ti gba lati kọ ara awọn silẹ, il-ẹjọ fontẹ lu u. Bẹẹ lo paṣẹ pe ki Abilekọ Latifa Mayẹloye ko gbogbo ẹru rẹ laarin ọjọ meji, nitori ibagbepọ wọn le la ẹmi lọ niwọn igba ti ko sifẹẹ mọ laarin wọn.

Oloye Ọladipupọ tun pa a laṣẹ fun Ọgbẹni Salami lati waa san ẹgbẹrun lọna aadọta Naira sile-ẹjọ, o pẹ tan, laarin ọsẹ kan.

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.