Sajẹnti ọlọpaa gun ọkọ rẹ pa l’Ekoo Lo ba sa lọ patapata

Spread the love

Lọwọlọwọ bayii, ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, ṣi n wa ọkan lara wọn, Sajẹnti Fọlakẹ Ogunbọdẹde, ẹni ti wọn lo sa lọ lẹyin to gun ọkọ rẹ, Taiwo Ogunbọdẹde, pa.

Alẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ niluu Ipaja. Fọlakẹ, ẹni to n ṣiṣẹ ni teṣan ọlọpaa to wa ni Ipaja, ni wọn ni oun pẹlu ọkọ rẹ jọ ja lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja. Nibi ti wọn ti n tahun sira wọn ni wọn ni obinrin ọlọpaa naa ti kilọ fun ọkọ rẹ pe ko ma pada waa sun nile lọjọ yii, nitori ohun ti oun yoo foju rẹ ri ko ni i daa.

Ṣugbọn Taiwo fi gbigbọ ṣe alaigbọ nipa ikilọ iyawo rẹ yii, nitori wọn lo sọ pe oun ko ni ibi ti oun le sun. Gẹgẹ bi awọn to ṣalaye nipa iṣẹlẹ yii ṣe sọ fun wa, wọn ni ero ọkan ọkunrin naa ni pe inu iyawo oun aa ti rọ diẹ ko too di alẹ.

Nigba ti ọkunrin naa wọle lalẹ ni wọn ni iyawo rẹ bẹrẹ si i gun un, koda, wọn ni ko si ẹmi kankan lara rẹ mọ lasiko ti awọn araadugbo naa yoo fi wọle tọ wọn lọ.

Lẹsẹkẹsẹ ni wọn ni obinrin naa ti sa lọ, ti awọn kan si ti gbe ọkọ rẹ lọ si ọsibitu kan, nibi to ti n gba itọju.

Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Chike Oti, loun ko ti i le fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun wa, ṣugbọn o ṣeleri lati kan si wa pada, eyi ti ko si ti i ṣe titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii.

(44)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.