Saidi lo pe awọn ole waa ja nileese to ti n ṣọdẹ n’Ikẹja

Spread the love
Sọdiq ati Saidu pẹlu awọn brain box ti wọn ji

Adefunkẹ Adebiyi

Nigba ti ọwọ awọn ọlọpaa RRS ba ọmọkunrin kan, Sọdiq Musa, ọmọ ọdun mejidinlọgbọn to maa n tu kinni kan ti wọn n pe ni Brain box ninu mọto onimọto, ọwọ kan naa lo jẹwọ pe oun ko deede waa jale nileeeṣẹ ti wọn ti mu oun yii, o ni ọdẹ ti wọn gba sibẹ,  Saidu Atiku, lo n ṣagbodegba fawọn.

O ni Saidu lo ni koun ati Ridwan Adamu to ti sa lọ bayii waa tu nnkan pataki lara awọn mọto to wa  ninu ọgba ileeṣẹ naa, tọwọ fi ba oun, ti Ridwan Adamu si sa lọ.

Opin ọsẹ to kọja yii ni ikọ ọlọpaa ayaraṣaṣa RRS, mu Sọdiq nileeṣe kan to wa ni Awolowo Road, n’Ikẹja. Ileeṣẹ nla naa ni Saidu, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ti n ṣe ọdẹ alẹ, ṣugbọn awọn to gba a siṣẹ ko mọ pe ọdalẹ ni. Afi nigba to pe Ridwan ati Sọdiq pe ki wọn maa bọ waa tu irinṣẹ pataki to jẹ pe mọto ko le ṣisẹ bi ko ba si lara ọkọ. O ni awọn ọkọ ti ***Brain box wọn maa n ya kiakia lọja bii Toyota Hiace ati Hilux pọ nita awọn to jẹ tileeṣẹ naa, ki wọn waa pitu ọwọ wọn.

Iṣẹ naa ni Sọdiq ati Ridwan lọọ ṣẹ tọwọ fi ba Sọdiq nikan, ọga ẹ to n jẹ Ridwan rọna sa lọ  ni tiẹ. Aago kan oru ni Sọdiq  ṣalaye pe awọn de ileeṣẹ awọn Saidu, o ni ki i pẹ rara tawọn fi maa n tu kinni ọhun tan, nitori awọn ni ọna kan tawọn maa n gba a tu u to jẹ laarin iṣeju meji pere, awọn yoo ti fọ gilaasi ọkọ lai si ariwo rara, awọn yoo ti so kinni kan ti wọn n pe ni pulọọgi (plug) mọ nnkan mi-in, ko si ni i pẹ rara ti Brain box yoo fi dawati ninu ọkọ tawọn ba ṣiju le.

Bẹẹ naa lo sọ pe o ri lọjọ yii, nitori wọn ti tu Brain box Toyota mẹrin, awọn ọlọpaa ba mẹta lọwọ Sọdiq, Ridwan to sa lọ si gbe ẹlẹkẹẹrin lọ.

Nigba ti wọn mu eyi tọwọ tẹ yii de olu ileeṣẹ wọn ni Alausa, Sọdiq salaye fawọn RRS pe Saidu Atiku lo ni kawọn waa jale, niṣe lo si ṣe bii pe oun sun lọ fọnfọn nigba tawọn n tu nnkan lara awọn mọto to wa nibẹ. Ọlọdẹ mi-in to wa nitosi toun ki i ṣe ara wọn lo kegbajare, to fi di pe ọwọ palaba Sọdiq nikan segi.

Bo tilẹ jẹ pe o loun kawe gboye ninu imọ nipa oṣelu ni yunifasiti kan, Sọdiq loun ko fi ṣiṣẹ. Iṣẹ awọn to n ta asun lotẹẹli atawọn ibi ti wọn ba ti n ṣe faaji lo ni oun n ṣe tẹlẹ, ko too di pe oun pade Ridwan, ọga to kọ oun bi wọn ṣe n tu nnkan ta lara mọto. Ridwan lo maa n lọọ ta a fawọn onibaara lọja irin gẹgẹ bo ṣe wi, o ni ẹgbẹrun lọna ogoji lawọn maa n ta Brain box bọọsi Toyota Hiace, bo ba si jẹ ti Toyoya Hilux ni, ẹgbẹrun lọna ogun Naira ni, ẹsẹkẹsẹ lawọn yoo si gbowo ẹ, ko si lọọ kabọ nibẹ rara.

‘Ida ogoji (40%) ni Ridwan maa n fun mi ninu iye ta a ba ta awọn Brain box yii, ko si ki i sọ ibi tiṣẹ ba wa fun un ka too lọ, igba to ba ya lo maa ṣẹṣẹ sọ fun mi, oun lọgaa mi to kọ mi niṣẹ yii. Awọn ibi tawọn eeyan ba ti n ṣe faaji bii kilọọbu, ile ọti, ile igbafẹ atawọn mi-in la ti maa n lọọ tu nnkan lara mọto wọn.

‘Aago kan oru si meji la maa n tu awọn nnkan yii, nitori asiko yẹn ni faaji aa ti wọ awọn eeyan lara gan-an, wọn ko ni i bikita nipa mọto wọn ti wọn paaki kaakiri mọ.’

Bẹẹ ni Sọdiq to loun ti tu nnkan lara mọto ni Lekki, Ogunlana Drive ati Allen, n’Ikẹja wi.

Oun ati Saidu to ṣagbodegba fun un yoo de kootu laipẹ rara, bẹẹ ni awọn ọlọpaa ṣi n wa Ridwan to sa lọ. Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ yii, Zubairu Muazu, kilọ fawọn ọmọ jayejaye onifaaji pe ki wọn maa fi òye si i bi wọn ba n ṣe faaji lọwọ, paapaa nigba ti wọn ba paaki ọkọ wọn sibi ti ko fi bẹẹ ni aabo to peye.

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.